You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ nípa Olajide Esan olùdíje sípò Gómìnà fẹ́gbẹ́ òṣèlú AAC ní ìpínlẹ̀ Osun
Ilu Ejigbo, nipinlẹ Osun ni wọn ti bi Olajide Esan ni ọdun 1986.
O kẹkọọ gboye BSC ninu imọ nipa Geography and Resource Management nile ẹkọ giga UNIOSUN.
Bello Muideen Yekeen ni ẹni to yan lati ṣe Igbakeji ninu idije si ipo gomina ipinlẹ Osun to ti n kopa.
Oniṣowo ọkọ ayọkẹlẹ ni Olajide Esan.
Igba gbogbo lo maa n sọ pe oun kunju oṣuwọn ju awọn oludije yoku lọ, owo nikan ni oun ko ni lọwọ.
''Mi ò lówó tí màá fún àwọn èèyàn Osun láti dìbò fún mi''
Ṣaaju lori eto itakurọsọ ti BBC Yoruba ṣe fawọn oludije sipo gomina ipinlẹ Osun ni Esan ti fun ipo gomina ipinlẹ Osun ninu ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC); Olajide Esan, kede pe oun ko ni kọbọ toun yoo fun araalu ki wọn le dibo foun, bi ko ṣe pe igbagbọ wọn ninu ohun ti oun le ṣe fun Osun lo ṣe koko.''
Oludije yii sọ pe iṣẹ ilu ni Ọlọrun gbe le oun lọwọ, oun fẹ sin ipinlẹ Osun ni, ko ba owo de.
Olajide sọrọ yii lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun 2026 yii, nibi itakurọsọ ti ileeṣẹ BBC News Yoruba gbe kalẹ fawọn to fẹ di gomina ipinlẹ Osun ninu ibo to ku si dẹdẹ naa.
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu AAC ti Omoyele Sowore n dupo aarẹ Naijiria labẹ rẹ naa sọ pe:
" O di ọjọ ti araalu ba mọ pe wọn n jẹun ọmọ ninu oyun ni pẹlu owo ti wọn n gba lọwọ oṣelu, ko too ye wọn pe ohun to yẹ ki wọn jẹ́ ni wọn n jẹ.
"Emi o ni owo ti mo maa fun araalu lati dibo fun mi o, bi ẹ ba ri ẹlomi-in ti ẹ ro pe o tun kunju oṣuwọn ju mi lọ, to fẹẹ sinlu ju mi lọ, ẹ lọọ dibo fun un."
Mo ni eto ti a pe ni "Osun Residence Data Base" ti yoo jẹ ka mọye eeyan to wa l'Osun
Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Olajide Esan sọ pe ohun ti oun mu ni pataki ni gbigba ijọba fun araalu, nigba ti araalu ba ti le sọ ohun ti wọn fẹ.
O ni eto kan toun pe ni Osun Residence Data Base yoo jẹ koun mọ iye agba ati ọmọde to wa l'Osun ati ohun ti wọn n fẹ, ti ko fi ni fi sibi ikan ju ibi kan lọ.
Bakan naa lo ni oun tun ni eto mi-in ti yoo ri si iṣuna, o pe e ni Financial Dashboard.
"Eyi yoo jẹ kawọn ara ipinlẹ Osun mọ iye to n wọ apo ijọba, yoo jẹ ki wọn mọ iye ti ijọba n na lọwọ ati iye to ku lapo ijọba, to jẹ pe ti naira kan wọn ba sọnu, wọn yoo le beere pe, 'Gomina, naira kan wa da."
O ni awon ijọba kan ti jẹ gbese silẹ l'Osun de awọn ọmọ ipinlẹ yii, araalu kọọkan si ti jẹ gbese miliọnu kan naira, o si yẹ ki araalu maa beere bi wọn ṣe n nawo wọn
Bakan naa lo ni oun tun ni eto ti yoo ri si ẹtọ araalu, nibi ti wọn yoo ti maa gbọ ifisun awọn eeyan Osun, ti wọn yoo si maa dajọ are fun alare, da ti ẹbi fun ẹni to ba jẹbi.