You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
‘Ọkùnrin tó bẹ́ sódò Ọ̀ṣun ti gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ rí nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀'
Ọkunrin kan to gbiyanju lati gba ẹmi ara rẹ lọjọ Aje nilu Osogbo ni awọn agbofinro ti yọ oju ọrọ sita pe igba kẹta ree ti ọkunrin naa yoo gbiyanju ati gb’ẹmi ara rẹ ṣugbọn ti Ọlọrun ko fun un ṣe.
Arakunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Saheed Ọladeji, ti ọjọ ori rẹ ti dagba diẹ gbiyanju lati ko sinu odo Osun nibi afara to gba ori odo naa kọja ni Gbodofọn nilu Osogbo.
Arakunrin naa ti bẹ sinu odo naa tan ki awọn eeyan to wa nibẹ to ranṣẹ pe awon panapana lati wa doola ẹmi rẹ ki omi to gbe e lọ.
Awọn panapana to doola ẹmi arakunrin naa fidi ọrọ naa mulẹ f’awon akọroyin nilu Osogbo.
‘Mi o nilo owo, mi ẹnikẹni maṣe ko owo jọ fun mi’
Alukoro fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Ọṣun, Ibrahim Adekunle sọ fun awọn akọroyin pe igba kẹta niyi ti arakunrin naa gbiyanju lati gbẹmi ara rẹ ti awọn si ti doola ẹmi rẹ.
Ọkan lara awọn ti ọrọ naa ṣe oju wọn, ẹni to pe orukọ ara rẹ ni Sukura ṣalaye fawọn akọroyin pe : “Ọladeji bẹ si u odo lowurọ ọjọ Aje. Awọn aladugbo to pe panapana ti wọn si doola ẹmi rẹ. Ibiti wọn ri n fọ mọto lo ti n ṣiṣẹ."
Ninu ọrọ to sọ, Ọgbẹni Oladeji ṣalaye pe ọmọ bibi agboole Iwinjọbi nilu Osogbo loun. “Mo ni iyawo ati ọmọ nilu Eko. Mi o fẹ owo kankan lati ọdọ ẹnikẹni. Ko si nnkankan to ṣe mi “