Ọmọ ọdún méjìlá àti ìyá rẹ dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú babaláwo ẹni ọdún 63

Tọkọtaya to n ṣe igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published

Awọn ọlọpaa ni orilẹede Ghana, ti bẹrẹ iwadii lori bi babalawo kàn ṣe fẹ ọmọ ọdun mejila niyawo.

Opin ọsẹ to kọja ni igbeyawo ibilẹ laarin ẹni ọdún mẹtalelọgọta ọhun, Gborbu Wulomo, Nuumo Borketey Laweh Tsuru XXXIII, ati ọmọdebinrin naa fa awuyewuye lori ayelujara.

Awọn eniyan bu ẹnu ẹtẹ lu iwa naa, ṣugbọn awọn alaṣẹ ibilẹ ni Nungua sọ pe ko si nnkan to buru nibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ghana sọ ninu atẹjade kan pe ọmọ ọdun mejila naa ati iya rẹ, ti wa ni akata wọn.

Wọn ni igbesẹ naa waye lẹyin ti iroyin igbeyawo naa gba ori ayelujara.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa sọ pe awọn n ṣisẹ pẹlu ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn ọmọde ati obinrin, lati le fun ọmọ naa ni iranlọwọ to ba nilo, bi iwadii ṣe n lọ.

Ọdun mejidinlogun ni ọjọ ori ti ofin faaye gba eeyan lati ṣe igbeyawo ni Ghana. Lootọ si ni igbeyawo pẹlu ọmọde ti dinku nibẹ, amọ awọn kan n ṣe e ni ikọkọ.

Fidio ayẹyẹ igbeyawo naa to wa lori ayelujara, ṣafihan bi awọn araalu naa ṣe peju sibi eto ọhun.

Bakan naa ni awọn obinrin tun n fi ede ilu naa sọ fun ọmọdebinrin naa pe ko ma a wọ awọn aṣọ to le fa oju ọkọ rẹ mọra.

Wọn tun gba a nimọran pe, ko mura silẹ fun awọn ojúṣe rẹ gẹgẹ bi iyawo, ko si ma a lo awọn ororo ikunra oloorun didun ti wọn fun, ko le ba ma a wu ọkọ rẹ lati ni ibalopọ pẹlu rẹ.

Awọn ọrọ yii lo bi awọn eeyan ninu, tí wọn fi mọ daju pe kii ṣe ere ni igbeyawo naa.

Awọn eeyan kan n fẹ ki ijọba tu igbeyawo naa ka, ko si tun wadii babalawo ọhun, Ọgbẹni Tsuru.

'Aṣa ati iṣe pọnbele ni igbeyawo naa '

Awọn olori ilu Nungua, nibi ti ọmọdebinrin naa ati babalawo ọhun ti wa sọ pe aimọkan lo n ṣe awọn to n bu ẹnu ẹtẹ lu igbeyawo wọn.

Nii Bortey Kofi Frankwa II, to jẹ olori niluu naa sọ pe, ojuṣe ọmọde naa gẹgẹ bi iyawo fun babalawo, jẹ àṣà wọn.

O ni ọdun mẹfa sẹyin ni ọmọbìnrin naa ti bẹrẹ awọn eto to yẹ ko ṣe lati di iyawo babalawo ọhun, ti ko si di ẹ̀kọ́ rẹ lọwọ.

"O ṣi ku ipele keji eto naa ti yoo la kọja,lati sọ ọ di mimọ fun ojúṣe rẹ gẹgẹ bi iyawo oluawo."

Taa ni babalawo, ẹni ọdun mẹtalelọgọta ọhun?

Tsuru ni Oluawo ilu Nungua, to wa ni Olu ilu orilẹede Ghana, Accra.

Oun lo ma n ṣe etutu ati ẹbọ fun ilu, gbadura fun aabo ilu, o si tun ma n ṣe amojuto àṣà ati iṣe wọn.

Lara ojúṣe rẹ tun ni iyansipo awọn oloye ilu.

Lootọ ni ofin Ghana fọwọ si igbeyawo ni ilana ibilẹ, ṣugbọn ko faaye gba a pẹlu ọmọde.

Ajọ kan to n ja fun ẹtọ awọn ọmọdebinrin, Girls Not Brides, sọ pe ida mọkandinlogun awọn ọmọbìnrin ni Ghana lo n ṣe igbeyawo, ki wọn o to pe ẹni ọdun mejidinlogun, ida marun-un ninu wọn si lo n lọ sile ọkọ ṣaaju ki wọn to ṣe ọjọ ibi ọdun mẹẹdogun.