Ojúbọ̀rọ̀ kò ṣe é gbọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́ nídìí ìdìbò - Tinubu figbe ta

Oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu ti rọ awọn alatilẹyin rẹ lati ri wi pe wọn jade lati dibo yan gẹgẹ bi aarẹ orilẹ-ede yii ninu eto idibo aarẹ to oun bo. Tinubu sọrọ naa nibi ẹtọ ipolongo aarẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ni gbagan Nelson Mandela freedom park niluu Osogbo olu ilu Ipinlẹ Osun. Tinubu nigba ti oun ba awọn alatilẹyin re sọrọ nii" ko si nnkan ti wọn le wi,wọn baa so owo di tọrọ wọn o ba so owo di kọbọ ibiti ati ma dibo ko jina si ile wa aa rin de bẹ,". O tun tẹsiwaju lati so wi pe"Oju boro ko ni aa n fi gbọmọ lọwọ ekuro.
Oludije ẹgbẹ oṣelu APC tun ṣe leri pe ti oun ba jawe olubori ninu eto idibo aarẹ, awọn ọdọ Naijiria yoo ri iṣẹ ṣe. Bakan naa lo tun ṣeleri pe awọn ile-ẹkọ giga ni orilẹ-ede yii ko ni wo se niran mo. O ṣeleri pe ni kete ti oun ba ti di Aare, idasesilẹ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ Academic Staff Union of Universities (ASUU) yoo di ohun atijo.























