Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa olùṣírò owó àgbà àkọ́kọ́ Nàìjíría Akintola Williams tó kú lẹ́ni ọdún 104

Aworan Pa Akintola Williams

Oríṣun àwòrán, The Guardian Life

Published

Awaye ma lọ kan o si, ọrun nikan lare ma bọ.

Ogbontarigi oluṣiro owo akọkọ iruẹ lorilẹede Naijiria, Pa Akintola Williams ti dagbere faye.

Akintola to gbajugbaja ninu iṣẹ iṣiro owo jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọrun un.

Pupọ ni yoo ranti Pa Akintola fun bo ṣe gbafẹ ati ifẹ ti baba ni si wiwọ aṣọ oyinbo taa mọ si suuti.

Ko fẹ si ibi ti eeyan yoo ti ri aworan Pa Akintola ti ogbontarigi oniṣiro yi ko ni mura dẹẹdẹ pẹlu suuti to gbafẹ.

Ọjọ Aje, ọjọ kọkànlá oṣu kẹsan an ọdun 2023 yìí ni a gbọ iroyin iku Pa Williams lati ile rẹ niluu Eko.

Koda, oṣu kẹjọ to lọ yìí ni oloogbe naa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹrinlelọgọrun rẹ.

Wọnyi ni awọn koko to yẹ kí o mọ nipa ilumọọka oluṣiro owo, Pa Akintola Williams ti di oloogbe.

Ọdun 1919 lẹyìn ti ogun agbaye alakọkọ pari ni a bi Pa Akintola Williams.

Oniṣowo pataki lati ilu Abeokuta ni baba to bi Pa Akintola iyẹn, Z.A Akintola ṣe nigba naa lọhun.

Baba tiẹ gangan si jẹ akọwe to ba awọn oyinbo ṣiṣẹ nigba ijọba amunisin ko to wa da ileeṣẹ agbẹjọro tiẹ silẹ lẹyin to kawe gboye ni ilẹ Gẹẹsi.

Aburo Pa Akintola Williams lo tọ oju ọna baba wọnlọ to si di gbajugbaja ilumọọka agbẹjọro F.R.A Williams.

Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Olowogbowo Methodist Primary School, to wa ni opopona Bankole ni Apongbon ni Pa Williams ti bẹrẹ eto ẹkọ rẹ.

Pa Williams lọ si ileẹkọ giga Yaba nibi to ti gboye dipiloma ninu ẹkọ idokowo.

Ẹkọ ọfẹ ti ileeṣẹ UAC ṣe onigbọwọ rẹ ni Pa Williams fi kawe nibẹ.

Lọdun 1944 ni o tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ lọ si fasiti ilu London nibi to ti kẹkọọ gboye ninu iṣiro owo.

Pa Akintola Williams ati Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ Akinwumi Ambode

Oríṣun àwòrán, Facebook/Akinwunmi.Ambode

Pa Akintola di oluṣiro owo agba lọdun 1949.

Pa Williams da ileeṣẹ iṣiro owo aladani, alakọkọ iruẹ nilẹ Afirika alawọdudu lọdun 1952.

Orukọ ileeṣẹ naa ni Akintola Williams & Co niluu Eko.

Gẹgẹ bii awọn iroyin ti a gbọ, Pa Williams ni oluṣiro owo agba akọkọ laarin awọn ọmọ ilẹ Afirika dudu.

O gboye yii lẹyìn ti o pegede ninu idanwo ajọ awọn oluṣiro owo agba ni ilẹ Gẹẹsi ati Wales lọdun 1949.

Pa Williams ko ipa ribiribi ninu idasilẹ àjọ awọn oluṣiro owo agba ni Naijiria lọdun 1960 ti ọpọ mọ sì ICAN lonii.

Pa Williams gan an ni aarẹ akọkọ ẹgbẹ ICAN.

Aworan Pa Akintola ati iyawo rẹ Efuntiloye Mabel Williams

Oríṣun àwòrán, The Guardian Life

Bakanna ni Pa Williams tun ko ipa gidi ninu idasilẹ ọja pasipaarọ Naijiria, NSE.

Ijọba apapọ fi oye OFR da Pa Williams lọla lọdun 1982.

Ko tan sibẹ o, Ọbabinrin ilẹ Gẹesi, Elizabeth naa tun fi oye CBE da a lọla lọdun 1997.

Pa Williams ṣiṣẹ pẹlu ajọ to n ri si pipawo wọle fun ijọba laarin ọdun 1950 sí 1952.

Akoko yii lo kuro lẹnu iṣẹ ijọba to sì da ileeṣẹ aladani ti ara rẹ silẹ.

Ileeṣẹ aladani iṣiro owo naa lo di Deloitte & Touche Nigeria lonii