Kóòtù ju Òjó tó bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lò pọ̀ lẹ́ẹ̀ẹmẹ̀ta sẹ̀wọ̀n gbére

Oríṣun àwòrán, getty
Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko ti ju ọkunrin kan, Ojo Ọladeji, si ẹwọn gbere lori ẹsun biba ọmọ ọdun mọkanla lo pọ lẹẹẹmẹta ọtọọtọ.
Ogunjọ oṣu kẹta 2024 yii ni idajọ naa waye lati ẹnu Adajọ Rahman Oshodi.
Ṣaaju ni Agbefọba Babajide Boye ti ṣalaye, pe logunjọ, oṣu keje ọdun 2021, olujẹjọ ba ọmọbinrin naa lo pọ ninu ile akọku kan laduugbo Agberuba, Mẹiran, nipinlẹ Eko.
O ni o ti kọkọ fọgbọn tan an nigba meji to si ba a lo pọ, ọkan ninu awọn asiko naa lo fun ọmọ ọhun lọti mu.
Ọmọde naa loun fẹẹ fẹ Ojo lẹyin iwe mẹfa ni aṣiri fi tu
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Rahman ṣalaye pe ọmọdebinrin naa fi aimọkan sọ fun iya rẹ pe oun nifẹẹ Ojo, oun si fẹẹ fẹ ẹ lẹyin toun ba pari iwe mẹfa.
Eyi lo mu iya rẹ fọrọ wa a lẹnu wo titi tọmọ fi jẹwọ, pe Ojo maa n ba oun lo pọ, o si ti ṣe bẹẹ lẹẹẹmẹta.
‘’ Ipa ti iya ọmọ naa ko ninu ọrọ yii, to fọgbọn tẹ ọmọ rẹ ninu lati mọ pe iwọ Ojo lo n ba ọmọde ṣe aṣepọ, bi wọn ṣe lọ sileewosan lati fidi ibalopọ naa mulẹ ati bi wọn ṣe fi to ọlọpaa leti, kopa pataki ninu ẹsun yii.
‘’Ati paapaa, bi iwọ Ojo ṣe funra rẹ jẹwọ pe o jẹbi, bo tilẹ jẹ pe niṣe lo n purọ tẹlẹ nibẹrẹ ẹjọ yii.
‘’Bo o ṣe fun ọmọde yii lọti mu naa lodi labẹ ofin, ẹwọn gbere si ni ijiya ibalopọ to o ni pẹlu rẹ.
‘’Ọgbẹ buruku to le ṣakoba fọmọ kekere yii fun ọpọlọpọ ọdun lo da si i lọkan pẹlu ibalopọ ti ko yẹ.
Fun idi eyi, idajọ ẹwon gbere to wa fun ẹṣẹ rẹ naa ni mo da fun ọ’’
Bẹẹ ni Adajọ Rahman Oshodi paṣẹ.


























