Ẹ fààyè gbà kí Amotekun máa lo ohun ìjà alágbára – Akeredolu  

Ikọ Amotekun

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu

Published

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu, ti ke si ijọba apapọ lati gba ikọ alaabo Amotekun laaye, lati maa lo awọn ohun ija oloro fun idaabo araalu.

Akeredolu tun sọrọ lori iṣẹ abo ọpa epo ti ijọba apapọ gbe fun ileeṣẹ aladani kan.

O ni ti ijọba ba le gba awọn ileeṣẹ aladani laaye lati maa lo ohun ija oloro fun aabo ọpa epo, ko buru ti ijọba ka naa ba le gba Amotekun laaye lati maa lo ibọn fun abo araalu.

Akeredolu lo sọ ọrọ naa nibi to ti ṣi ọọfisi ajọ OSOPADEC tuntun, ni Oba Ile, niluu Akure.

‘N ko ni dẹkun lati maa gbena woju ijọba apapọ’

Nigba to n bu ẹnu atẹ lu ipo ti eto abo Naijiria wa, Akeredolu sọ pe oun ko ni dẹkun ati maa gbena woju ẹkun ijọba apapọ lori ọrọ naa.

O ni “Ọpọ araalu atawọn akẹgbẹ mi lo yẹ ko ye nipa ipo mi lori iṣẹ ti ijọba apapọ gbe fun ileeṣẹ aladani lori abo ọpa epo.

N ko lodi si ki ijọba gbe iṣẹ eto abo fun ẹnikẹni to ba wu wọn, owo wọn ni, wọn si le na bo ṣe wu wọn.”

Ni ipinlẹ wa nibi, Amotekun ni a n ko owo wa le lori.

Nnkan ti mo sọ ni pe o yẹ ki ijọba gba fun Amotekun lati gbe ohun ija alagbara gẹgẹ bo ṣe gba bẹẹ fun awọn alaabo to n ṣọ ọpa epo.”

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

“Ti ẹ ba le gba awọn aladani laaye lati gbe ibọn fun abo ọpa epo, kilode ti ẹ ko gba Amotekun laaye lati maa dabo bo awọn araalu?”

Gomina ọhun ni “ Ọpa epo rọbi ko ṣe pataki ju ẹmi eeyan lọ.”

O sọ siwaju si pe ọwọ ofin ti tẹ lara awọn afurasi to ji awọn arinrinajokan  gbe loju ọna Ifon lọsẹ to kọja, amọ ẹru n ba wọn ti eeyan wọn ji gbew lati wa tọka si awọn afurasi ọhun.”

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn ẹṣọ alaabo ipilẹ Ondo fun akitiyan wọn lati dabo bo awọn araalu, to fi mọ Amotekun fun bi wọn ṣe doola awọn ti wọn ji gbe.