Orí Facebook ni mo ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi orí èèyàn ṣoògùn owó – Afurasí tó ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ OAU

OAUTH

Oríṣun àwòrán, NPF Ogun State

Published

Afurasi ẹni ọdun marundinlogoji ti ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ lori ẹsun pe o ṣekupa akẹẹkọọ OAU kan, Quadri Salam, lati ta ẹya ara rẹ fun oogun owo ti sọ pe oju opo Facebook ni oun ti kọ lati maa fi ori eeyan joogun.

Afurasi naa, Akeem , lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Nigerian Tribune.

Ṣaaju ni ọwọ ọlọpaa ti kọkọ tẹ Akeem atawọn afurasi mii lori iku akẹkọọ naa to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun 2023 ni ọlọpaa ṣawari oku akẹkọọ naa nibi ti afurasi ọhun atawọn ẹmẹwa rẹ sin si lẹyin ti wọn ti kọkọ ge ẹya ara rẹ fun tita fun awọn ologun owo.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinle Ogun, SP Omolola Odutola sọ ninu atẹjade kan pe ẹrọ ibaraẹnisọrọ oloogbe naa to wa lọwọ afurasi ni wọn fi ṣawari rẹ.

Ori Facebook ni mo ti kọ nipa lilo ori eeyan fun oogun owo

Akeem, to jẹ ọkan pataki lara awọn afurasi sọ fun ọlọpaa ninu ifọrọwerọ pe, oun ti n ṣe iṣẹ balalwo tẹlẹ ṣaaju ki oun to di olugbe ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.

O ni “Ọdun 2018 ni mo ti bẹrẹ si n ṣe iṣẹ oniṣegun, lara awọn ti mo n tọju ni egbo adaajina, atude, aṣina, aṣiri bibo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

“Ori ere, ori ọka, ori okete ati ori aja ni mo maa n lọ pọ mọ ewe ati egbo lati fi ṣe oogun awure ati bẹẹ lọ.

“Nigba ti a n kọ iṣẹ oniṣegun, wọn ko kọ wa ki a maa lo ori eeyan, ori Facebook ni mo ti kọ nipa rẹ.

“Ninu awọn ikanni ti mo darapọ mọ lori Facebook ni wọn ti n kọ nipa awọn eroja ti eeyan le lo lati fi joogun, ibẹ ni mo ti maa n kọ awọn eroja naa silẹ fun lilo, iyẹn lọdun mẹta sẹyin.

Afurasi ọhun sọ pe ọwọ awọn oniṣegun ẹgbẹ oun loun ti kọkọ maa n gba ori eeyan ti oun maa n lo tẹlẹ, eyi ti oun maa n gun pọ mo ewe lati fi ṣe asejẹ.

N50,000 ni mo ra ori eeyan

Akeem tẹsiwaju pe ọrẹ oun kan, Ifayemi lo ta ori eeyan fun oun lẹnu ọjọ mẹta yii.

“Mo ra ori eeyan meji lọwọ Ifayemi, amọ o ti salọ bayii.

“Ki n to ra ori naa, oniṣegun mii, Ifaniyi sọ pe oun nilo rẹ, mo sọ fun Ifayemi, nigba ti o ri ori naa, o gbe wa fun mi, o si gba ẹgbẹrun lọna aadọta naira lọwọ mi.”