Fásitì Ibadan mú àdínkù bá àkókò tí àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa fi lọ ibi iṣẹ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi èrò wọn hàn

BBC Yoruba kan si awọn akẹkọọ fasiti ilẹ Ibadan l'ọjọ Iṣẹgun lati gbọ ariwisi wọn lori ikede ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ṣe wi pe ọjọ mẹta pere ni awọn olukọ yoo fi maa ni anfani lati wọ iyara ikẹkọọ bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ kẹrinla ọdun yii, nitori ipenija to rọ mọ iyọkuro owo iranwọ epo bẹntiro.
Awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ giga naa ti iṣẹ wọn pọn dandan nikan ni ayipada ko ni ba bi wọn ṣe n ṣiṣẹ wọn laarin ọsẹ.
Botilẹ jẹ wi pe pupọ ninu awọn akẹkọọ fasiti naa lo ti pada sile wọn fun isinmi lẹnu ẹkọ, lara awọn to n kẹkọọ gboye ikeji to ba akọroyin wa sọrọ fi iyalẹnu han wi pe iroyin naa ko tii fi bẹẹ tan kaakiri ọgba ile ẹkọ naa.
Ọkan ninu awọn akẹkọọ naa ṣe alaye wi pe, "Ko si nnkan ko buru ti wọn ba din ọjọ ti awọn olukọ fin ṣiṣẹ si ọjọ mẹta laarin ọsẹ, ṣugbọn ko ni boju mu ti ko ba si ọna mii ti wọn fẹ gba lati jẹ ki awọn akẹkọọ kọ gbogbo nnkan to yẹ ki wọn mọ ki o to di opin saa eto ẹkọ."


Akẹkọọ mi ti o tun ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe alekun yoo ni lati ba akoko ti awọn akẹkọọ fi n da ka iwe laye ara wọn.
O ni ohun ti awọn olukọ yoo kan maa ṣe ni lati tọka awọn ibi ti akẹkọọ yoo maa ka saaju idanilẹkọ ni iyara ikẹkọọ, ki wọn le ni anfani lati beere awọn nnkan ti o ba ruju lọwọ awọn olukọ wọn laarin ọjọ mẹta ti wọn yoo fi pade laarin ọsẹ.
A kan si awọn aṣoju ẹgbẹ oluko, ASUU ẹka ti fasiti ilẹ Ibadan ati awọn alakoso ile ẹkọ giga naa ki a le gbọ alaye sii lori igbesẹ naa, ṣugbọn wọn ko fesi titi di asiko ti a gbe iroyin yii jade.
Lati igba ti aarẹ tuntun lorilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti kede iyọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiro ni awọn ijọba ipinlẹ ti n ṣe agbekale ọkanojokan eto ti yoo mu ara dẹ araalu.
Ipa idẹrun yii naa ni fasiti ilẹ Ibadan tọ pẹlu ikede ti wọn ṣe lati din iye ọjọ ti awọn olukọ fi n ṣiṣẹ ku.


























