Meghan, Harry àti ìdílé ìjọba ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì: Níbo ni nkan ti wọ́ wá?

Oríṣun àwòrán, NEIL HALL/EPA
Ni opin ọsẹ to kọja ni Duke ati Duchess ti ilu Sussex pẹlu sọrọ sọrọ ori ẹrọ amohunmaworan, Oprah Winfrey sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo, ti wọn si sọ ẹkunrẹrẹ ohun to mu wọn kuro ninu ẹbi ọba ilẹ Gẹẹsi.
Nigba ti ọrọ ifẹ wọn bẹrẹ, ọpọ eeyan lo gbagbọ pe wọn o mu ọlaju wọ eto lọbalọba ilẹ naa, amọ iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti tọkọtaya naa kede pe awọn n fi ilu silẹ lati maa gbe ni ilẹ America.
Irinajo ifẹ to ṣoro lati gbagbọ

Oríṣun àwòrán, Dan Kitwood/Getty Images
Ọdun 2016 ni awuyewuye bẹrẹ si ni gbode kan pe Ọmọọba Harry n fẹ oṣerebinrin kan to jẹ ọmọ ilẹ America, Meghan Markle.
Ẹnikan to jẹ ọrẹ si awọn mejeeji lo mu wọn mọ ara wọn.
Oṣu mejidinlogun lẹyin ọjọ naa si ni wọn dajọ igbeyawo.
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo 'kopa' nibi ayẹyẹ igbeyawo wọn to waye ninu oṣu Karun-un, ọdun 2018.
Fun asiko diẹ, o dabi ẹ ni pe awọn ileeṣẹ iroyin nilẹ Gẹẹsi fẹran tọkọtaya naa.
Bawo ni wahala ṣe bẹrẹ?
Ọpọlọpọ eeyan lo ni ireti pe ibẹrẹ ọtun ni igbeyawo Harry ati Meghan yoo jẹ ni agboole Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi.
Gbajugbaja olootu iwe iroyin Crown Chronicles, Victoria Howard sọ pe igbagbọ wa pe agboole naa yoo di eyi to ko eeyan mọra, kii ṣe nitori pe Meghan jẹ abẹya meji, bi ko ṣe pe o jẹ ọmọ ilẹ America, o tun jẹ ẹni to ti kọ ọkọ ri.
Ṣugbọn, ki wọn o to da ọjọ igbeyawo ni ami ti n han sita pe awọn iwe iroyin ko ni jẹ ki Meghan 'o sinmi'.

Oríṣun àwòrán, Robert Alexander/Getty Images
Nigba ti Ọmọọba Harry kọkọ kede pe Meghan ni iyawo afẹsọna rẹ, oriṣiriṣi ọrọ ti ko dara nipa rẹ lo n jẹ jade.
Harry sọ nigba naa pe wọn n fi ọrẹbinrinrin oun ṣe ẹlẹya ninu awọn iwe iroyin.
Howard sọ pe iru awọn nkan bayii ko jẹ tuntun, lati ọdọ awọn iwe iroyin si awọn obinrin to ba n darapọ mọ agboole ọbabinrin.
O ni iru nkan bẹẹ jẹ pataki lara nkan to fa ipinya laarin Kate Middleton ati Ọmọọba William lọdun 2007.
"Awọn iwe iroyin maa n ṣe daadaa si awọn obinrin naa ti wọn ba ṣẹṣẹ darapọ mọ aafin, ṣugbọn ti yoo ba fi to ọdun kan, wọn yoo bẹrẹ si ni wadii lati ọdọ awọn ọrẹ, alajọṣiṣẹ pọ tẹlẹ, ati awọn ọna mii lati ri nkan ti ko dara nipa wọn kọ.
"O si han gbangba ninu ọrọ ti Harry sọ nigba naa pe, ko ni fi aaye gba iru ẹ ko ṣẹlẹ si Meghan."

Oríṣun àwòrán, Pool via Reuters
Nitori naa, nigba ti tọkọtaya yii kede ni ọdun 2020 pe awọn ko fẹ oye kankan tabi ojuṣe ninu idile ọba mọ, Harry sọ pe igbesẹ naa waye lati le daabo bo awọn mejeeji lọwọ ayika kikoro ti awọn ileeṣẹ iroyin ilẹ Gẹẹsi da silẹ.
Akọroyin to ma n kọ iroyin nipa irinajo idile ọba fun iwe iroyin Yahoo, Jessica Morgan, sọ pe "Harry ti ri bi awọn oniroyin ṣe ṣe si iya rẹ, ko si fẹ ki iru ẹ ṣẹlẹ si iyawo rẹ."
"Eeyan takuntakun ni diana, ti ko si gba ki wọn o pa oun lẹnu mọ - Maghan fi awọn nkankan jọ ọ, o si tun jẹ alawọ dudu."
Ṣe iru ohun to ṣẹlẹ si Diana lo tun n ṣẹlẹ bayii?

Oríṣun àwòrán, Tim Graham/Getty Images
Nigba ti Lady Diana Spencer darapọ mọ idile Ọba, awọn iwe iroyin n ṣe daadaa si, bi wọn ṣe ṣe si Meghan.
Howard sọ pe "wọn tẹwọgba Diana ni ibẹrẹ pẹpẹ. Ọmọbinrin to rẹwa ni, o ni igboya, o tun gbajumọ."
Ṣugbọn, ni kete ti igbeyawo oun ati ọkọ rẹ, Ọmọọba Charles tuka, gbogbo igba ni awọn akọroyin ma n lepa rẹ.
Iroyin sọ pe fọto oun ati ọkunrin tuntun to n fẹ nigba naa, Dodi Fayed, pa owo to ju miliọnu kan Dọla lọ.
Bi wọn ṣe n ṣọ kaakiri jẹ ara nkan to mu ki wọn o ma a sare le ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ni ilu Paris, eyi to pada yọri si ijamba to pa a .

Oríṣun àwòrán, Princess Diana Archive/Getty Images
Iku rẹ si lo jẹ ipilẹ ikorira to wa laarin awọn ọmọ rẹ, ati awọn oniroyin.

Oríṣun àwòrán, Stephen Pond/Getty Images
Ọpọlọpọ awọn eeyan si ti sọ lori ayelujara pe bakan naa kọ ni wọn ṣe n kọ iroyin nipa Kate, to jẹ iyawo ẹgbọn Harry, Ọmọọba William.
Ọpọ nkan ti wọn koro oju si lara Meghan, ni wọn ko ri aida ninu rẹ lara Kate.
Kilo wa ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Oprah?

Oríṣun àwòrán, Harpo Productions - Joe Pugliese
Nigba ti tọkọtaya kede ninu oṣu Kinni, ọdun 2020 pe awọn fẹ ẹ fi ojuṣe awọn ninu ile ọba silẹ, o jọ igbesẹ ti wọn ko fi lọ ẹnikẹni ni aafin, ki wọn to o kede rẹ.
Koda, awọn awọn alamojuto aafin sọ pe igbesẹ naa jẹ eyi to bani lọkan jẹ.
Howard gbagbọ pe ifọrọwanilẹnuwo naa yoo ni ipa lara idile ọba ilẹ Gẹẹsi fun igba pipẹ.
























