EndSARS report: Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tó kéré jù lọ nílé asòfin sọ pé ìjọba àpapọ̀ ní ẹjọ́ láti jẹ lórí ìpànìyàn Lekki Tollgate

Published

Agbarijọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ́ oselu to kere julọ ni ile asoju-sofin Naijiria, sọ pe oun ti ṣe agbeyẹwo abajade iwadii ogbimọ ti ipinlẹ Eko gbe kalẹ lori ọrọ iwọde EndSARS.

Àwọn asofin naa sọ pe ijoba apapọ ni ẹkọ lati kọ.

Wọn sọ ninu atẹjade kan ti olori àwọn ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin naa, Ndudi Elumelu fi ọwọ si, ti wọn si fi sita lọjọ Ọjọbọ, pe abajade iwadii naa fihan pe lóòótọ́ ni ipaniyan waye ni Lekki Tollgate ni ogunjọ, oṣù Kẹwàá, ọdun 2020, botilẹ jẹ pe awọn kan sọ pe irọ ni.

"Lẹyin ti a fi ara balẹ ṣe agbeyẹwo abajade iwadii ogbimọ ti ijọba ipinlẹ Eko gbé kalẹ lori ọrọ EndSARS, a ri pe igbiyanju ijọba apapọ lábẹ́ ẹgbẹ́ oselu All Progressives Congress, APC, lati bo bi wọn ṣe pa awọn ọdọ Naijiria ni Lekki Tollgate, jẹ ẹri pe ijọba ṣe atilẹyin fun diditẹ mọ awọn ọmọ Naijiria.

"Bakan naa si ni ẹri to wa ninu abajade iwadii ọhun, to fihan pe awọn osisẹ alaabo to jẹ ti ìjọba, ko oku awọn ti wọn pa lọ, ti wọn si tun pa àwọn ẹri iṣẹlẹ naa rẹ, jẹ ẹrù wiwo lori ìjọba apapọ to ti kọkọ sọ pe ipaniyan naa ko waye.

"Yàtọ̀ si eyi, awọn asofin naa tun bu ẹnu ẹtẹ lu minisita eto iroyin ati àṣà, Lai Mohammed, fun bose sare sọ lori agbohunsafẹfẹ pe ipaniyan ko waye ni Lekki Tollgate, lai bikita fun awọn ẹlẹri iṣẹlẹ ibanujẹ naa.

Wọn ni o yẹ ki Lai Mohammed kọ̀wé fi ipo rẹ silẹ ni tabi ki Aarẹ Muhammadu Buhari daa duro, pẹlu ẹri tuntun to jade bayii.

Wọn tun rọ àwọn ìgbímọ to n ṣe iwadii ni awọn ipinle miran pe wọn ko gbọdọ bo iṣẹlẹ bẹẹ mọ́ra.

Ẹgbẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu to kere julọ nile aṣojusofin ni Naijiria sọ pe awọn ti ṣagbeyẹwo abajade iwadii lori endsars lEko tawọn ṣi ri pe ijọba apapọ ni ibeere lati dahun si.

Awọn aṣofin yi sọrọ naa ninu atẹjadekan ti olori ọmọ ẹgbẹ to kere julọ nile Ndudi Elumelu fi sita lỌjọbọ.

O ni esi yi fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni iapniyan waye nibi ikọlu Lekki TollGate logunjọ oṣu Kẹwa ọdun 2020 yatọ si bi ijọba ṣe n jiyan pe ko sohun to jọ ọ.

''Awa ọmọ ẹgbẹ to kere julọ nile lẹyin agbeyẹwo fiudi rẹ mulẹ pe igbiyanju ijba APC lati fọwọ bo ipaniyan awọn ọdọ Naijiria lati ọwọ awọn ọmọ ogun fi han pe ijọba lọwọ si idunkoko mọ araalu to waye yi''

O tẹsiwaju pe ''Bi igbimọ yi ṣe fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ipaniyan waye ni Lekki Toll Gate ti awọn agbofinro si gbe oku salọ kuro nibi iṣẹlẹ yi ti wa di ẹbi ru ijba apapọ to ti ṣaaju jiyan pe ipaniyan ko waye''

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn ọmọ ẹgbẹ to kere julọ yi tun bẹnu atẹ lu Minisita feto iroyin ati aṣa Lai Mohammed ''to sare sọ fawọn akọroyin ki igbimọ to gbe iwadii jade pe ko si ipaniyan to ṣẹlẹ ni Lekki toun ti pe ẹri to fi eleyi han pọ nilẹ''

Wọn ni o jẹ ohun iyalẹnu pe ijọba ti ẹ fẹ daṣọ bo nkan to ṣẹlẹ logunjọ oṣu Kẹwa ti wọn si ni dandan ki wọn ri pe idajọ ododo fidi mulẹ.

Wọn ba awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu yi kẹdun ti wọn si ni kawọn ọmọ Naijiria ma ṣe foya lasiko yi.

Ohun to wa nita bayi ni ẹda abajade igbimọ yi nitori ijọba kọ lofi sita, awọn kan lo tu abajde yi sita.

Ninu ilana to de gbigbe iru abajade yi kalẹ ni ki ihjọba kọkọ gba lọwọ igbimọ lẹyin igba naa ki wọn wa gbe iwe jade lori rẹ taa mọ si White Paper.

Eleyi ni ijọba ipinlẹ Eko ṣeleri lati ṣe nigba ti wọn gba abajade iwadii igbimọ lọwọ igbimọ naa lọsẹ yi.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko ti ni gbogbo araalu lawọn yoo jẹ ki o mọ nkan to wa ninu abajde igbimọ yi.