Dominic Joshua Ngene: Ọmọ ọdún 21 kó sọ́wọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn jìbìtì N2bn fún ìdókòwò Bitcoin àti Forex

Dominic Joshua

Oríṣun àwòrán, Dominic Joshua

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu ọga agba ileeṣẹ Brisk Capital Limited, Dominic Joshua lori ẹsun jibiti owo to le ni biliọnu meji naira.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni lara ẹsun ti wọn fi kan Joshua ni pe o dari owo awọn oludokowo lọ si ibo miran.

Awọn ọlọpaa ni lẹyin ti ọpọ eeyan ti mu ẹjọ rẹ wa lawọn ṣe iwadii lori Joshua to jẹ ọmọ ọdun mọkalelogun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni lori ẹrọ ayelujara bii Facebook, Instagram ati Twitter ni Joshua ti maa n ri awọn ti wọn ba n da owo pọ.

Ohun ti wọn ni Joshua n sọ fawọn eeyan ni pe oun maa ba wọn dokowo lori Bitcoin, Forex, ile ati ilẹ tita to fi mọ owo epo rọbi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe Joshua tun maa n sọ fawọn eeyan ere gọbọi bii ida ọgọta ninu ọgorun ni wọn yoo maa ri lori okowo wọn.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Awọn ọlọpaa ni ẹẹdẹẹgbẹta eeyan lo lu ni jibiti owo to le ni biliọnu meji naira ri.

Ninu atẹjade ti kọmiṣọnna ọlọpaa to n ri si ẹsun jibiti lulu, Anderson Bankole fi sita, o kilọ fawọn eeyan lati kiye sara lori okowo ti wọn ba sọ fun wọn pe ere gọbọi lo wa nibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Joshua yoo foju ba ileẹjọ lẹyin tawọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ ba ti pari iyanṣẹlodi ti wọn gunle lọwọ yii.

Ta ni Dominic Joshua gan an?

Dominic Joshua jẹ ọga agba ileeṣẹ Brisk Capital Limited.

Ọmọbibi ipinlẹ Ebonyi niiṣe, amọ ipinlẹ Akwa Ibom lo fi ṣe ibujoko.

Joshua ninu ọrọ to fi sori ẹrọ ayelujara Linkedin pe oṣiṣẹ banki onimọ nipa okowo ni oun, bẹẹ ni oun si ti ṣiṣẹ naa fun ọdun mẹwaa.

A ko mọ nipa ile ẹkọ to lo, ṣugbọn o sọ pe oun kẹkẹ gboye ni fasiti UNICAL niluu Calabar, ipinlẹ Cross River.

Joshua ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ẹni to n bawọn eeyan dokowo pẹlu owo wọn.

Odu ni Joshua kii ṣe aimọ fun oloko awọn akọroyin, ṣugbọn oun ti ọpọ mọ nipa rẹ ni pe o maa n sọ pe oun maa n ṣe iranwọ fawọn eeyan.