Olujare Ọba Adebamigbe Oluwagbemigun ti wàjà

Olujare

Oríṣun àwòrán, theprecisionng

Àkọlé àwòrán, Olujare ati olori rẹ lọdun 2019
Published

Olujare ti ilu Ijare, Ọba Adebamigbe Oluwagbemigun, Kokotiri Keji, ti waja.

Oloye Sapetu ilu naa, Wemimo Adekayero lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Ọdun 1996 ni Ọba Oluwagbemigun gori itẹ awọn babanla rẹ ko to dagbere faye lẹni ọdun mẹtalelọgọrin.

Iṣẹ imọ ẹrọ ni oloogbe ọhun kọ ko to di Ọba ilu Ijare.

Ilu Ijare jẹ ọkan lara awọn ilu to wa ni ijọba ibilẹ Ifedore nipinle Ondo.

Àkọlé fídíò, Ohun ti Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sátánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́

Ilu naa ni ile ẹkọ giga meji, Anglican Grammar School ti wọn da silẹ lọdun 1972 ati ile ẹkọ giga ti CAC ti wọn ṣagbekalẹ rẹ lọdun 1969.

Ni bayii ti kabiesi ti waja, awọn eeyan ilu naa yoo maa reti ki wọn yan adele ti yoo di ipo naa mu titi ti ọba mii yoo fi gori oye, nitori wọn kii yan adele obinrin niluu Ijare.