Naira Marley: Ilé-ẹjọ́ gba ẹ̀rí síi lórí ẹ̀sùn jìbìtì tí wọ́n fi kan olọrí àwọn Marlians

Naira Marley: Ilé-ẹjọ́ gba ẹ̀rí síi lórí ẹ̀sùn jìbìtì tí wọ́n fi kan olọrí àwọn Marlians

Oríṣun àwòrán, EFCC

Published

Ileẹjọ giga ijọba apapọ ni Ikoyi niluu Eko tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ Olorin takasufe, Azeez Fashola ti ọpọ mọ sí Naira Marley.Ajọ EFCC fi ẹsun Onikoko mọkanla to da lori igbimọ pọ lu jubiti pẹlu Kaadi igbowo.Adajọ Nicholas Oweibo tun gba awọn ẹri mii l'Ọjọru lori ẹsun ti won fi kan Marley.

Àmọ́, Marley ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.Agbẹjọro Akinwale Kola-Taiwo to ṣoju Marley rọ ileẹjọ lati sun igbejọ ọhún siwaju.Alaye ti Kola-Taiwo ṣe fun ileẹjọ ni pe agbẹjọro agba, Olalekan Ọjọ(SAN) to jẹ olori awọn agbẹjọro Marley wa nipinlẹ Edo nibi to ti n ṣiṣẹ fun onibara rẹ mii.Lẹyin naa ni adajọ Oweibo sun igbejo ọhun siwaju di ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2021 yii.