Bobby Brown child death: Ẹkún sọ nílée olórin Bobby Brown, Junior jáde láyé!

Published

Bobby Brown Jr., to jẹ ọmọkunrin olorin ilẹ Amẹrika Bobby Brown ti jade laye.

Ẹgbọn rẹ toun naa jẹ olorin ati olukọtan orin, Landon Brown fi aridaju ipapoda rẹ han loju opo instagram rẹ to ni akọle pe "mo nifẹẹ rẹ titi lai Ọba".

Awọn eeyan ti bẹrẹ si ni ba idile naa kẹdun ati daro oloogbe ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, ileeṣẹ iroyin TMZ jabọ pe wọn ri Brown Jr. to ku sinu ile wọn to wa ni agbegbe Los Angeles.

Bobby Brown Jr. toun ati baba rẹ jọ n jẹ orukọ jẹ ọkan lara ọmọ meje obi rẹ. Awọn to ku ni Bobbi Kristina to ku lẹni ọdun mejilelogun lọdun 2015, LaPrincia to jẹ ẹni ọgbọn ọdun bayii, Landon ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Cassius ọmọ ọdun mọkanla, Bodhi ọmọ ọdun marun ati Hendrix to jẹ ọmọ ọdun mẹrin.

Eyi ni ọmọ ikeji ti Bobby Brown yoo padanu ni ọdun kaarun lẹyin iku ọmọbinrin rẹ, Bobbi Kristina Brown to bi pẹlu iyawo rẹ tẹlẹ, Whitney Houston.

Ati iya, baba atawọn ọbakan rẹ lọkunrin lobinrin marun ni Bobby Brown Jr. fi silẹ lọ ko si bi ọmọ kankan ko ti dagbere faye.

Ohun to yẹ koo mọ nipa Bobby Brown Jr.

Bobby Brown jr. ni ọmọ to jade latara ere ifẹ laarin ọrẹbinrin atijọ Bobby Brown, Kim Ward. Eyi waye koun ati gbajugbaja olorin Whitney Houston to bẹrẹ si ni jọ jade ti wọn si pada fẹ ara wọn.

Oun ati Kim ni ọmọ meji papọ, obinrin kan LaPrincia lọdun 1989 ati Bobby Jr. lọdun 1991. Jr. ni ẹgbọn ati aburo mẹfa mii.

Olorin to ṣẹṣẹ n dide ni Bobby Brown Jr,. O nifẹ lati tẹle ipasẹ baba rẹ toun naa ni ẹbun orin ati ijo. Bobby Jr. ṣe agbejade orinkan, "say Something" ninu oṣu kẹsan 2020 pẹlu fidio ranpẹ kan loju opo Instagram rẹ.

O dun Bobby Brown Jr. kan egungun nigba ti aburo rẹ obinrin Bobbi Kristina ku. O kọ ọ si oju opo Twitter rẹ nigba naa pe "awọn eeyan ko fi bẹẹ naani rẹ ayafi bi o ba jẹ pataki, bẹẹ ni wọn o fẹran rẹ afigba too ba to lokiki tabi ku. Mi o fẹ iru atẹle yii.

Oloogbe Bobby Jr. sọ eyi lẹyin igba ti awọn bẹrẹ si ni tẹlee lori ayelujara lati mọ ẹkunrẹrẹ nipa aburo rẹ to ku. Ṣe lo pada fi kun un wipe "Oju bi aye ṣe ri gangan ree fun mi, igbe aye mi ree".

Bobby Brown sunmọ aburo rẹ, LaPrincia bii iṣan eti. Inu gbogbo fọto rẹ lo ti ma n han loju opo Instagram rẹ. Lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan ọdun 2018, Bobby Jr. pin fọto alawọfunfun ati dudu kan to jẹ ti aye atijọ loju opo Instagram eyi to jẹ tirẹ pẹlu LaPrincia nigbaa kekere wọn pẹlu iya wn, Kim to bẹẹ to kọ ọ sinu akọle rẹ pe "mo nifẹ̀ẹ́ fọto yii pupọ, kuu ọjọ ibi La!!! Mo nifẹ rẹ pupọ! Ati iwọ iyaa mi!.