You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Corornavirus:A o gbé pápákọ̀ ofurufu Eko ati Abuja ti laipẹ- Hadi Sirika
Mínísita fun ọ̀rọ̀ irinajo ofurufu Hadi Sirika, sọ pé ìjọba yóò gbé papakọ ofurufu meji to ṣe gbòógi ti pa laipẹ yìí ju bi awọn ṣe ro tẹ́lẹ̀ lọ.
Lasiko to n ba awọn akọròyìn, ilé ijọba sọ̀rọ̀, lẹ́yìn ìpàdé pẹlú ààrẹ Buhari, Sirika ni, àwọn yóò dẹkun itankalẹ ajakalẹ ààrun Coronavirus.
O ni àwọn ìgbìmọ amúṣẹ sẹ ijọba lori COVID-19 ni yóò kede igbésẹ ti àwọn yóò gbe nitori alaye ọlọdani ni oun ṣe fun àwọn oniroyin.
Sirika jẹ ọkan lara ọmo igbimọ amúṣẹsẹ lori COVID-19 nigba ti Boss Mustapha to jẹ akọwé ijoba apapọ jẹ́ alaga wọ́n.
Ẹ̀wẹ̀ ìjọba ti fi orilẹ̀-èdè Sweden àti Austgria si àra àwọn orilẹ̀-èdè ti wọ́n ti fi ofin de láti ma wọ Naijiria mọ.
Ní bayìí, orilẹ̀-èdè mẹẹdogun ni wọ́n ti fi ofin de láti ma wọ Naijira mọ