Àwọn olùwọ́de ti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de nílùú Ibadan
Agbegbe Iwo road lawọn Oluwọde naa ti gbera ki wọn to kọju si idi apẹ gba agbegbe Gate lọ.
Apa ariwa orilẹede Naijiria ni iwọde 'ebi n pa wa' ti fẹsẹ mulẹ julọ pẹlu bawọn ọdọ ti tu yaya jade lati fi ẹhonu han lori bi ilu ko ti fara rọ.
Agbegbe Iwo road lawọn Oluwọde naa ti gbera ki wọn to kọju si idi apẹ gba agbegbe Gate lọ.

Bí iwode ifehonu hàn ebi ń pá wá ti àwọn olufehonuhan olojo mewa ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ lónìí jakejado orile-ede Naijiria, àwọn eso alabo lorisirisi tí wá ní pápá ìṣeré MKO tí ó wà ní kuto abeokuta, olú ìlú ipinle ogún.
Akoroyin BBC news Yoruba ti o jáde kàkàkí igboro abeokuta lowuro kutu oni jẹ ki o di mimo pé gbogbo oju poopo tí ó wà ní abeokuta ni àwọn agbofinro, àwọn eso abo lára ìlú (NSDC), àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ àti àwọn eso alabo miran.
Ọkàn lára àwọn oga eso alabo náà tí kò fẹ́ dárúkọ rẹ ni ìjọba apapo lo pàṣẹ lati jẹ ki awon eso alabo wá ní ojufo fun iwode ifehonu hàn naa lati maa ba si wahala kankan.
Adajo ile ejo gíga Olugboyega ogunfowora( ti high court)tí ó fìdí kalẹ sì ilu abeokuta lọ́jọ́ru Wednesday gbé igbejo kalẹ fún àwọn olufehonuhan naa lati ṣe ifehonuhan wọn ní, paapaa isere MKO tí ó wà ní kuto abeokuta, ansarudeen grammar school ota, Dipo Dina stadium Ijebu ode ati remo divisional high school ti o wa ni sagamu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile-ẹjọ giga ilu Abuja ti paṣẹ fun awọn oluwọde ibẹ, pe iwọde ‘ebi n pa wa’ ti wọn fẹẹ bẹrẹ lonii,ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ ọdun 2024 ko gbọdọ kọja papa iṣere MKO Abiola.
Adajọ Sylvanus Orji, ti ile-ẹjọ giga ilu Abuja lo paṣẹ naa, lẹyin tiMinisita fun olu-ilu ilẹ wa, Nyesom Wike, pe ẹjọ tako awọn oluwọde naa.
Ninu igbẹjọ ọhun ni Amofin agba Ogwu Onoja, ti rọ kootu lati fi ofin de awọn olori marun-un ninu ẹgbẹ oluwọde yii lati ma ṣe rin kaakiri igboro Abuja.
O ni ki kootu ma ṣe jẹ ki wọn gba ọfiisi awọn eeyan tabi gbagede ijọba laarin ọjọ kin-in-ni si ikẹwaa ti wọn fẹẹ fi ṣe ifẹhonuhan naa.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba ko lodi si iwọde bi olupẹjọ ṣe wi, o fidi ẹ mulẹ pe iroyin to n tẹ oun lọwọ lati ọdọ awọn agbofinro fi han pe awọn kan n pete ati sọ iwọde naa di jagidijagan.
Nigba to n ṣafikun ọrọ rẹ, Nyesom Wike ṣafihan ẹri kan lati ọdọ ẹgbẹ ‘’Take it Back Movement’’, nibi ti wọn kọ ọ si pe awọn kan n gbero lati wọ ile agbara, Aso Rock pẹlu ipa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni awọn eeyan naa tun N dunkooko pe awọn yoo ja gbogbo waya ina to kọju si ile ijọba lulẹ lasiko iwọde naa.
Awọn oluwọde yii tun n beere fun ina mọnanọna ati ibi itura ti wọn ti le maa ṣegbọnsẹ ati itọ, lasiko iwọde bi Wike ṣe sọ.
Damilare Adenola ni Wike pe orukọ ẹni to buwọ lu iwe naa.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Sylvanus Orji, sọ pe ẹtọ ni fun awọn eeyan lati fi ẹhonu wọn han, ṣugbọn pẹlu awọn ẹ̀rù ti minisita yii fi han, o paṣẹ pe oju kan naa ni ki iwọde ọhun ti waye.
Adajọ Orji paṣẹ pe ki wọn fi ẹhonu wọn han ni papa iṣere MKO Abiola ti i ṣe ti ijọba apapọ, l’Abuja.
Diẹ lara awọn olujẹjọ naa ti kootu darukọ ni; Omoyele Sowore,Damilare Adenola , Adama Ukpabi ati Tosin Harsogba.

Oríṣun àwòrán, X/@_EL_AMEEN/via REUTERS
Yoruba bọ, wọn ni o n bọ, o n bọ, awọn la a dẹ ẹ de e; eyi gan an ni BBC Yoruba fi fẹ ki o mọ bi o ti le daabo bo ara rẹ lasiko ifẹhonuhan ‘ebi n pa wa’ ti yoo bẹrẹ kaakiri orilẹede Naijiria ni Ọjọbọ ti i ṣe ọjọ kinni oṣu Kẹjọ ọdun yii.
Bi ọjọ ṣe n sun mọ ọjọ kinni oṣu kẹjọ ti ifẹhonuhan yoo waye ni Aarẹ Bola Tinubu ti n ṣe oniruuru ipade pẹlu awọn gomina, ọba alaye, awọn olori ẹsin at'awọn mii tọrọ kan.