Tinubu kò sọ̀rọ̀ lórí ohun tí à ń bèèrè, ìfẹ̀hónúhàn wa yóò tèsíwájú – Àwọn olùwọ́de

NI kete ti Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, pari ọrọ rẹ to ba awọn eeyan sọ laaarọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ 2024, awọn olufẹhonuhan kan ti jade lati tako o.
Awọn olufẹhonuhan ti wọn ko fi bẹẹ pọ niye naa kora jọ si agbegbe Gani Fawehinmi Park, l’Ọjota, ipinlẹ Eko.
Wọn n fi orin ati ariwo sọ pe ohun ti Aarẹ sọ ko yanju iṣoro Naijiria rara ni.
Bi wọn ṣe n kọrin ijangbara ni wọn n sọ ọ di mimọ pe gbogbo koko inira tawọn n tori rẹ ṣe iwọde ko han ninu ọrọ ti Tinubu sọ.
Wọn fi kun un pe awọn ọrọ to n gbe oriyin fun ijọba rẹ ni Aarẹ tẹnumọ ninu ohun to ba Naijiria sọ, bẹẹ, eyi ko yanju ohun ti awọn n wi.
Awọn agbofinro wa lagbegbe ti awọn afẹhonuhan yii ti n tako Aarẹ Tinubu, wọn tilẹ pọ ju awọn ọdọ naa lọ pẹlu.
Ikọ alaabo naa paṣẹ fawọn to n fi ẹhonu han naa lati ma ṣe kọja inu ọgba GaniFawehinmi, wọn si pada sibẹ, wọn n kọ orin atako wọn lọ.
Aarẹ Tinubu lo ti fi owurọ kutu ba araalu sọrọ lori ọrọ aje, owo iranwọ epo to yọ kuro, ẹyawo to ṣe fawọn akẹkọọ, ipese ohun amayedẹrun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
















































