Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ti dibo

    Ibikunle Amosun n ṣatilẹyin fun Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu APM dipo APC ti oun ba jade

    idibo
    Àkọlé àwòrán, APC lo gbe Amosun wọle gẹgẹ bii aṣojuṣofin fun Abeokuta
    idibo
    Àkọlé àwòrán, APC lo gbe Amosun wọle gẹgẹ bii aṣojuṣofin fun Abeokuta
  2. Adebayọ Adelabu dìbò ní Ibadan

      • Author, Adedayo Okedare
      • Role, BBC Yoruba
    Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ APC, Adebayọ Adelabu
    Àkọlé àwòrán, Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ APC, Adebayọ Adelabu ti dibo ni wọọdu Kẹsan, agọ idibo kẹwa, nijọba ibilẹ Ibadan South East.
    Adebayọ Adelabu
  3. Sharafadeen Alli tó tò sẹyin oludije ẹgbẹ PDP ti dibo

    Oludije ZLP tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Sharafadeen Alli ti dibo bayii.

    idibo
    Àkọlé àwòrán, Oludije ZLP tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Sharafadeen Alli ti dibo bayii.
    idibo
    Àkọlé àwòrán, Oludije ZLP tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Sharafadeen Alli ti dibo bayii.
  4. Olóṣèlú tó n pín owó gbá akọ̀ròyìn BBC létí nípínlẹ̀ Eko

    Ṣegun Adewale ti Aeroland gbá akọroyin BBC léti nitoripe o n ká fidio bi o ṣe n pín ẹgbẹrun kan naira fun awọn oludibo ni Pleasure bus stop nipinlẹ Eko.

    Àkọlé fídíò, Segun Adewale to dije dupo gomina labẹ oselu ADP ni ipinlẹ Ekiti gba eti Akọroyin BBC.
  5. Faṣọla dibo nilu Eko

    Babatunde Raji Fasọla,
    Àkọlé àwòrán, Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Eko, Babatunde Raji Fasọla, to tun jẹ minisita fun isẹ ode bayii, naa ti dibo ni ilu Eko
  6. Arugbo ti ọmọ rẹ pọn sẹyin lọ dibo

    Iya arugbo to dibo
    Àkọlé àwòrán, Iya rugbo ti ko le rin dada mọ̀ nitori ojo ori ni ilu Bayelsa, ri daju pe oun na lọ dibo. Ọmọ rẹ ọkunrin lo gbe sẹyin lọ si agọ idibo.
  7. Adegbenga Kaka dibo ni woodu Kashamu

      • Author, Yetunde Olugbenga
    Adegbenga Kaka
    Àkọlé àwòrán, Shefiu Adegbenga Kaka ni sẹnatọ tẹlẹ fun ẹgbẹ oselu APC ni ijọ̀ba ibilẹ ila oorun Ogun, to si tun ti jẹ igbakeji gomina tẹlẹ.
    Adegbenga Kaka
  8. Adeleke ni sọ fun BBC pé o da oun loju pe oun a bori nile ẹjọ

    Ademola Adeleke to dije dupo gomina nipinlẹ Osun ni oun yoo bori nile ẹjọ laipẹ

    Àkọlé fídíò, Adeleke: Mo mọ̀ pé n ó jáwé olúborí ní tribunal
  9. Ibudo idibo Akeredolu ni ipinlẹ Ondo ni yii ti o da

    Awọn eniyan ibudo idibo wọọdu yii ko pọ to

    idibo
    Àkọlé àwòrán, Iwọnba ero perete lo jade dibo nibudo idibo yii
  10. Ọwọ́ EFCC tún tẹ apò owó 'fún ìbó rírá' ní Benue

    Ajọ EFCC, sọ pe niṣe ni awọn janduku kọlu awọn oṣiṣẹ ajọ naa to n gbiyanju lati fi panpẹ mu ẹni to fẹ ẹ pin owo naa, ti wọn si tun ba ọkọ ajọ naa jẹ.

    Agbegbe North Bank nilu Makurdi ni ọwọ ti tẹ ẹ.

    Skip X post, 1
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post, 1

    Skip X post, 2

    End of X post, 2

  11. Ṣeyi Makinde, olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọyọ dìbò

    Ṣeyi Makinde, olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọyọ
    Àkọlé àwòrán, Ṣeyi Makinde, olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọyọ dìbò
    Ṣeyi Makinde, olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọyọ
  12. Gomina Ambode ti dibo ni wọọdu rẹ ni Ẹpẹ

    Gomina Ambode to jẹ ọkan lara awọn gomina ti ko ni pada wa fun saa keji ni o ti dibo bayii ni ilu epe ni ipinlẹ Eko

    Babajide Sanwo Olu lo n dije dupo gomina ipinle Eko lẹgbe oṣelu APC

    inec
    Àkọlé àwòrán, Babajide Sanwo Olu lo n dije dupo gomina ipinle Eko lẹgbe oṣelu APC
  13. Lai Mohammed dìbò ní ìlú Òró ní Kwara

    Minisita fún ètò ìròyìn àti Ásà, Alhaji Lai Muhammed dibò ní Polling unit 006, Oro ward 2, Irepodun LG, Kwara.

    Lai Mohammed
    Àkọlé àwòrán, Lai Mohammed dìbò ní ìlú Òró ní Kwara
    Lai Mohammed
    Àkọlé àwòrán, Lai Mohammed dìbò ní ìlú Òró ní Kwara
  14. Ọwọ́ tẹ ọkùnrin kan tó n pín owó níbùdò ìdìbò ní Kwara

    Ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, tẹ arakunrin kan Abdulkareem Abdulsalem, to n pin owo fun awọn oludibo nilu Ilọrin.

    Ninu iroyin kan ti ajọ naa fi sita loju opo Twitter rẹ, EFCC sọ pe ni ẹka ibudo idibo keje ni ileewe awọn olukọni, Kwara State College of Education, ni ọwọ ti tẹ ọkunrin naa

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  15. Alao Akala dìbò nílù Ogbomọṣọ

    Gomina nigba kan fun ipinlẹ Ọyọ, to tun jẹ oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, ko to o di pe o wọgile ipinnu rẹ naa tibo nilu Ogbomọṣọ pẹlu aya rẹ, Kẹmi Alao-Akala.

    Alao Akala
    Àkọlé àwòrán, Alao akala dibo ni Ogbomoso
    Alao Akala
    Àkọlé àwòrán, Alao akala dibo ni Ogbomoso
  16. Àwọn àkàndá ẹ̀dá náà jáde láti dìbò ní Ẹdẹ

    Rosiliu Tiamiyu
    Àkọlé àwòrán, Rosiliu Tiamiyu,tó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá, jade, to si dibo ni Woodu Keji, Ipin Keje, nilu Ẹdẹ, Ọṣun.
    Rosiliu Tiamiyu
  17. Kí ló fà á tí kọmísánà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo bínú lásìkò ìdìbò?

      • Author, Onyinye Chime
      • Role, BBC Pidgin, Lagos

    Iṣẹ igbọnsẹ, a kii fi ran ọmọ. Funra kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Edo, Danmallam Mohammed, lo bọ si oju ọna lati gbe nkan di ojupopo.

    Botilẹjẹ wi pe ko yẹ ko si igboke-gbodo kankan nitori idibo, niṣe ni awọn olugbe ilu Benin n ṣe ohun to kan kaluku wọn bi ẹni pe ko si idibo.

    Awọn ọlọkọ eero ati aladani n lọ, ti wọn si n bọ lojupopo. Eyi lo mu ki inu bi kọmisana ọlọpaa naa, to si bọ si oju ọna lati gbofinro funra rẹ.

    Kọmisana ọlọpa
    Àkọlé àwòrán, Awọn ọlọkọ eero ati aladani n lọ, ti wọn si n bọ lojupopo ni ipinlẹ Edo.
  18. Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ ní àgọ́ ìdìbò Ademọla Adeleke

    Àkọlé fídíò, Nigeria 2019 Election: Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn olùdìbò kan pé wọn ń fi ìbo wọn han ẹlòmíì
  19. ''L'ákọ ni mo sì wà fún ìdíje gómìnà''

    Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA, Uche Nwosu ti pariwo sita pe irọ ni irpyin kan to sọ pe oun ti yọwọ ninu idije fun ipo gomina ipinlẹ Imo.

    Nwosu to jẹ ọkọ ọmọ gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ, Rochas Okorocha, sọ pe awọn alatako oun lo wa nidi iroyin naa.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  20. Gómìnà Abdulfatai Ahmed dìbò ní Kwara

    Gómìnà Abdulfatah Ahmed
    Àkọlé àwòrán, Bí Gómìnà Abdulfatah Ahmed ti Ìpínlẹ̀ Kwara ń ṣe dibò ni ibùdó ìdìbò Adebiopon Compound, Agọ idibo kẹjọ̀, nijọba ibilẹ Ifelodun, Kwara
    Gómìnà Abdulfatah Ahmed