Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Tí kò bá sí màgò-mágó, èmi ni màá di gómìnà Eko

    Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Eko ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Jimi Agbaje ti sọ pe màgò-mágó nìkan lo le mu ki oun ma di gomina ipinlẹ Eko.

    O fi igbagbọ yii han lasiko to ba akọroyin BBC sọrọ nibi to ti dibo.

    Àkọlé fídíò, Ti ko ba si mago mago, emi ni yoo wọle gẹgẹbi gomina nipinlẹ Eko.
  2. Ibo didi ti pari, ibo kika ti bẹrẹ lawọn agọ idibo

    Ibo kika
    Àkọlé àwòrán, A ri awon egbe oselu APC to n pin akara oyinbo fun oludibo ni agọ idibo kọkanla, wọọdu kẹrin nilu Akurẹ.
    Awọn osisẹ INEC n ka ibo
    Àkọlé àwòrán, Ibo kika ti bẹrẹ ni Ikorodu, wọọdu kinni, agọ idibo kẹrinla ree
  3. Idarudapọ waye ni agọ idibo nilu Ire Ekiti

    Ile idibo to daru
    Àkọlé àwòrán, Ile idibo daru ni ilu Ire Ekiti. Agọ idibo kẹtala, wọọdu keji ree ni Ijisu, nilu Ire Ekiti nijọba ibilẹ Ọyẹ.
    Ile idibo to daru
  4. Aje ko bu igba jẹ fawọn oṣiṣẹ INEC yii ni Ekiti

    Osisẹ INEC to n sun
    Àkọlé àwòrán, Awọn agunbanirọ to n sisẹ ajọ INEC ree ti wọn sun. Idi ni pe awọn eeyan ko jade to bẹẹ lati dibo ni Ekiti
  5. Ọkùnrin yíì n laago fi pe àwọn èèyàn láti jáde dìbò

    Awọn araalu ko fi bẹ ẹ jade dibo ni adugbo Dọpẹmu l'Eko.

    Eyi lo mu ki Ọgbẹni Ọladele Iyẹwu fi ara a rẹ ji lati laago kiri adugbo naa pe ki awọn eniyan 'dakun' jade dibo.

  6. Yakubu Dogara
    Àkọlé àwòrán, Olori ile asoju sofin, Yakubu Dogara, ni kete lẹyin to dibo tan nilu rẹ Gwarangah, nijọba ibilẹ Bogoro, nipinlẹ Bauchi.
    Yakubu Dogara
  7. Fídíò bí wọ́n ṣe kátà-kárà ìbò ní Bayelsa

    Akọroyin BBC sẹ alabapade awọn to n ṣe kata-kara ibo ni ibudo idibo keji, wọọdu krin, ni abule Igbogbene nilu Yenogoa, ipinlẹ Bayelsa.

    Ibo ile aṣofin ipinlẹ nikan lo n waye nipinlẹ naa.

    Àkọlé fídíò, Awọn kan n ra, ti wọn si ra ibo nipinlẹ Bayelsa
  8. Awọn eeyan ko jade lati dibo nile aarẹ l‘Abuja

    Awọn oludibo ko jade lati dibo ni ibudo idibo tile aarẹ.

    Koda, ko si eeyan kankan lori ila to fẹ dibo titi aago mejila aabọ ọsan.

    Ṣe lawọn osisẹ eleto idibo kan n takurọsọ laarin ara wọn, ti wọn si n fi ẹrọ ibaraẹnisrọ wọn sere.

    Awọn miran ninu wọn tiẹ ti n toogbe tori airi nkan se.

    12:40pm Nigba ti akroyin BBC de ibudo idibo to wa ni ileewe alakọbẹrẹ St. Paul, Omu-Aran ni nkan bi aago kan ọsan ku ogun iṣẹju, oorun ni awọm oṣiṣẹ INEC n sun.

    Awọn osisẹ INEC ti ko ri nkan se n fi ẹrọ ibaraẹnisọrọ sere
    Awọn osisẹ Inec n toogbe
    Awọn osisẹ Inec ko ri oludibo, wọn n bara wọn sere.
    Awọn oṣiṣẹ to n sun
    Àkọlé àwòrán, Oorun ni awọn oṣiṣẹ INEC n sun ni ibudo idibo kan ni Omu-Aran
  9. Gomina Kayọde Fayẹmi ti Ekiti ti dibo

    Gomina Kayọde Fayẹmi ti Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Gomina Kayọde Fayẹmi ti Ekiti ti dibo ni ipinlẹ Ekiti
    Gomina Kayọde Fayẹmi ti Ekiti
  10. Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu dibo ni Ikoyi

    Babajide Sanwo-Olu
    Àkọlé àwòrán, Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti dibo ni agọ idibo rẹ ni Ikoyi.
    Babajide Sanwo-Olu
  11. Akinlade ni àwọn ologun n ṣiṣẹ fawọn oloṣelu kan

    Àkọlé fídíò, Awọn ologun sisẹ fun awọn oloselu ni ipinlẹ Ogun

    Oludije sipo gomina nipinle Ogun labẹ oselu APM, Adekunle Akinlade, ti fi esun kan awọn omoogun Naijiria wipe, wọn sise fun oludije kan nipinlẹ̀ Ogun.

    Akinlade fikun wi pe, awọn ti fi ọrọ naa to awọn adari awọn ologun leti, ti wọn si fi da won loju wi pe, awon yoo se iwadii lori ẹsun naa.

  12. Gómìnà Amosun ní ó dájú pé olùdíje òun ní yóò wọlé

      • Author, Abdulwasiu Hassan
      • Role, BBC Hausa, Abuja

    Botilẹjẹ wi pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Amosun, oludije ẹgbẹ oṣelu, APM, Adekunle Akinlade l'oun ṣatilẹyin fun ninu idibo gomina.

    .

    Àkọlé fídíò, 'APM ni yoo jawe olubori ni idibo gomina ni Ogun''
  13. Gboyega Oyetọla dibo nipinlẹ Ọsun

    Gomina ipinlẹ Ọsun, Gboyega Oyetọla
    Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Ọsun, Gboyega Oyetọla ti dibo tiẹ naa nilu rẹ nipinlẹ Ọsun. Bakan naa ni iyawo rẹ, kọwọrin pẹ́lu rẹ lati dibo.
    Aya gomina ipinlẹ Ọsun naa n dibo rẹ
  14. Olufẹmi Lanlẹyin, oludije ADC tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ dibo

    Olufẹmi Lanlẹyin, oludije ADC tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ
    Àkọlé àwòrán, Olufẹmi Lanlẹyin, oludije ADC tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ dibo ni ilu Ibadan
    Olufẹmi Lanlẹyin, oludije ADC tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ b
  15. Sẹ́nétọ̀ Ladọja àti aya rẹ nàá ti dìbò

    Ladoja ati aya rẹ
    Àkọlé àwòrán, Sẹnetọ ati aya rẹ, Yinka naa tibo nilu Ibadan
    Ladoja
  16. Bukọla Saraki dibo ni Ilọrin

    Bukọla Saraki dibo ni Ilọrin
    Àkọlé àwòrán, Aarẹ ile asofin agba, Dokita Bukọla Saraki naa ti dibo ni agọ idibo rẹ ni ilu Ilrin
  17. Tinubu dìbò nípínlẹ̀ Eko

      • Author, Olubunmi Okunnu
      • Role, BBC Pidgin, Lagos

    Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bọla Tinubu naa ti dibo ni nkan bi aago mejila ku iṣẹju maarun.

    Idibo ko tete bẹrẹ ni ibudo idibo rẹ, nitori pe awọn oṣiṣẹ INEC ko tete de.

    Nigba ti Tinubu de si ibi idibo, niṣe lo fi awọn to wa lori ìlà silẹ, to si lọ siwaju lati dibo lai to sori ìlà.

    Bola Tinubu
    Bola Tinubu
    Bola Tinubu
  18. Babatunde Gbadamọsi, oludije fun ẹgbẹ oselu ADP ti dibo

    Babatunde Gbadamọsi
    Àkọlé àwòrán, Babatunde Gbadamọsi, oludije fun ẹgbẹ oselu ADP ti dibo ni agọ idibo rẹ to wa nilu Ikorodu.
    Babatunde Gbadamọsi
  19. Buruji Kasahamu ti dibo

    Buruji Kashamu n dibo
    Àkọlé àwòrán, Oludije fun ẹgbẹ oselu PDP, Buruji Kashamu ti dibo ni agọ idibo r ni ilu Ṣagamu
  20. Wọ́n fi ǹkan fọ́ orí aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú yìí ní Kwara

    Iṣẹlẹ yii waye ni ibudo idibo keje, ni adugbo Oju-Ẹkun Zarumi nijọba ibilẹ Ilorin West.

    Bakan naa ni iroyin sọ pe awọn ọmọ ogun gbe arakunrin Yunus Ataragba, t'oun ti ẹjẹ lori, kuro nibudo idibo naa, nitori aṣẹ ti oloye ẹgbẹ oṣelu APC pa fun wọn.

    Ẹni ti wọn f lori
    Ẹni ti wọn fọ lori
    Àkọlé àwòrán, Wọn na asoju ẹgbẹ oselu kan ni agọ idibo keje, Oju-Ekun Zarumi, nijọba ibilẹ Ilorin West.
    Ẹni ti wọn fọ lori