Isiaka ni pipada si ileewe ekose ọwọ yoo wulo pelu imọ ẹrọ pẹlu kikọ awon eeyan ni iwa Omoluwabi ati idapada aṣa yoo yanju wahala abo
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàrin àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Ogun #BBCGOVDEBATE
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bó ṣe ń lọ níbi ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Yetunde Olugbenga
Paseda ni ojutu ti oun ni lori abo ni pipada si ori ibi ti a ti bere. O ni pipada si eto abo civil defence bi o se n wa lati ipile ni ojuutu si isoro yii. O ni pipada si eto abo iṣedale ti awon eeyan mo ni ona abayo.
"Ani ka pada sibi ti a mọ eyi to jẹ ibẹrẹ eto abo - civil defence A ni awọn ẹgbẹ to wulo ti a n danu bii Fijiilante Ohun taa mọ ni ka mura le lori".
Akinlade ni ki ijoba to wa lode to de nnkan buru ju bayii lo ni ti abo. O ni ijoba to wa nikale bayii ti gbiyanju lori abo
Ìdáhùn àwọn olùdíje sí ìṣòro àbò
Lori ibeere abo. Ogunbanjo ni omo ti ko ba ko iwe ko yanju ko lee ri ise se. O ni aikiisole awon odo ipinle ogun lo mu won ya si yahoo yahoo. O ni nipa atunto eko awon omo yahoo yoo lee sise ni stock exhange
Gboyega Nasir Isiaka ti ADC a ni lati joko wo bi a ṣe le ṣe e
Lori oro Tasued ati Mapoly. Paseda ni oun yoo se eto eko.
O sàlàyé ni tire pe gbogbo awon oludije lo janfani eto eko ofe nitorinaa ko si idi fun won lati so pe ko lee si eto eko ofe. O ni iga meta ni ipinle ogun ni. Akoko ni eto eko. O ni eto eko ofe seese nitori opo owo lo n lo sawon ohun ti ko kan araalu bii kiko afara.
Ogunbanjo ni ohun to n fa wahala ileewe Tauseued ati mapoly ni ileri eto eko ofe f'araalu. O ni ko si eto eko ofe to lee jina denu.
Ogunbanjo ni ko si idi fun eto eko ofe. O ni oun ti eka eko nilo ni ipese amayederun si ileewe, ikoni fawon oluko. O ni wahala ti araalu n daale lori eto eko ofe lo poju.
"Iru ẹkọ wo gangan lawọn ọmọ wa n kọ jade? A ni lati ṣe eto ẹkọ to ja geere ti awọn ọmọ to kẹkọọ̀ jade yoo fi ri iṣẹgidi. Bi ijọba to wa lori alefa latẹyin wa ba ti ṣe e daadaa ni, ao ni ṣẹṣẹ maa sọrọ rẹ bayii".
Akinlade ni ijoba to wa lode n pese eto eko sugbon eto yoo tun te siwaju.
Akinlade ni eto eko ye fun ileewe alakobere ṣugbọn ti o ba ti n ju eyi lo ko si idi fun eko ofe mọ.
Lori ibeere pe se o yẹ ka sanwo fun eto ẹkọ? Bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ?
Akinlade ni alakọbẹrẹ, bẹẹ ni ṣugbọn to ba ti n goke o y ka fi diẹ kun un.
Ìbéèrè àwọn èèyàn nípa MaPoly
Isiaka ni oun yoo seto apero ati eko lati jiroro lori idagbasoke eto eko.
Isiaka ni ki a lo bere model school, yoo ku die kaato. O ni aisi igbesoke awon olukọ ati aisan owo osu n sakoba fun eto eko atipe ipo kokandinlogun ti ipinle ogun n se ninu waec ko dara to
Rotimi Paṣeda - SDP
Owe ni Paṣeda fi pa, "bi iwaju o ba ṣe e lọ, ẹyin a ṣee pada si. Orisa ti a ba n sin ti ko ba gbe ni, o yẹ ka pada lẹyin rẹ".
Ademọla Ogunbanjo - ANN
"Emi o ṣe oṣelu ri. Ki wa nidi ti ẹ fi maa dibo yan mi. A o kii da ẹmu tuntun sinu igo to ti dagba.
Mo ni ibẹru Ọlọrun"
Gboyega Nasir Isiaka - ADC
"Ti a ba n sọ̀rọ̀ ootọ ati ifọkansin, emi ni mo mọ ọ ju awọn to ku lọ".
Àwọn kókó ọ̀rọ̀ gbòógì látẹnu àwọn olùdíje
Akinlade Adekunle - APN
"Bi a ṣe maa wa ohun taa nilo ti a maa ri i, mo mọ ọ"
Rotimi Paṣeda to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu SDP naa ti wa lori itage.

Àkọlé àwòrán, Rotimi Paṣeda - SDP Ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu
Gbọ̀ngàn ìpàdé ti kún fọ̀fọ̀

Àkọlé àwòrán, Gbọ̀ngàn ìpàdé ti kún fọ̀fọ̀ Gboyega Nasir Isiaka ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu ADC ni ipinlẹ Ogun.

Àkọlé àwòrán, Gboyega Nasir Isiaka ADC oludije ẹgbẹ oṣelu APN, Akinlade Adekunle ninu ifọrọwanilẹnu wo pẹlu akọroyin BBC Yoruba ni "Tẹẹ ba ti dibo yin kẹẹ duro ki wọn ka a"

Àkọlé àwòrán, Akinlade Adekunle - APN Àwọn olùdíje tó ti dé
Oludije fun ẹgbẹ oṣelu ANN lo kọkọ de ibi ipade ifọrọwerọ

Àkọlé àwòrán, Ademọla Ogunbanjo - ANN ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Abẹokuta
Ẹ ku ojumọ ẹ si ku alejo BBC Yoruba lori bo ṣe nlọ lonii lati ilu Abeokuta ni ipinlẹ Ogun. Yetunde Olugbenga lo n jábọ̀.
Awọn oludije sipo gomina ni ipinlẹ Abeokuta ti n de sibi ipade ifọrọwerọ laarin ara wọn eyi ti BBC Yoruba ṣe agbekalẹ rẹ. Ẹ maa ba wa kalọ
