Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ láàrin àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Ogun #BBCGOVDEBATE

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bó ṣe ń lọ níbi ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Àwọn obìnrin kò lè máa bèrè fún ìlera ọ̀fẹ́ kí wọ́n tún máa jà fún ìbádọ́gba

    Ogunbanjo ni oun ko nigbagbo ninu re sugbon oun yoo se e tori araalu. O ni eto adojutofo ilera ko ni pataki bikose ipese awon ohun to ye nileewosan.

    O ni omode ati arugbo nikan ni isejoba oun yoo fun ni ilera ofe pe "obinrin ko le maa bere fun ilera ọfẹ ki wọn tun maa ja fun idọgba.

  2. Isiaka ni eto ilera ko si ni ipo to joju. O ni akọkọ iṣẹ oun ni lati se koriya fawon oṣiṣẹ eto ilera. Ṣiṣi awon ileewosan alabode ti o wa ni titipa. O ni oun gbo nipa eto adojutofo ilera sugbon oun ko tii ri i nitorinaa oun yoo se ise lori re. O fi kun un pe eto ilera ofe fawon arugbo, ọmọ wẹwẹ, ati aboyun ni koko fun ohun.

  3. Ni ti Akinlade, o ni ijoba amosun ti fowo si iwe adojutofo ilera fun ipinle Ogun, isejoba oun yoo si tun tẹsiwaju lori rẹ.

  4. Ohun tí àwọn olùdíje yóò ṣe lórí ètò ìlera

    Paseda ni eto ilera alabode ko si ni ipo to dara. Isejoba oun yoo si lo awon agunbaniro atawon akeko to ni imo isegun lati maa sise lawon ile iwosan alabode.

  5. Ogunbanjo naa ni ko si nkan to se baba isale. O ni oun meta loloselu nilo,

    ogbon

    owo

    si ni awon baba isalẹ ati iya isalẹ

  6. 'Gbogbo olùdíje ló gbọ́dọ̀ lókùn nídìí' - Akinlade

    Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APN ni ko sohun tao buru ninu keeyan ni baba isalẹ gẹgẹ bii oloṣelu.

  7. Ibeere fun akinlade

    Pe se kii se saa keta enikan ni yoo lo?

    Akinlade ni oun ti lo kaakiri oun si ti mo aini gbogbo igun ipinle ogun. Gbogbo won ni yoo gba ifowokan isejoba oun.

    Akinlade
    Àkọlé àwòrán, Akinlade
  8. Ibeere fun ogunbanjo.

    O ni ko ni iriri oselu ogun. Bawo lo se fe see ti ikan ko fi ni ju ikan lo?

    Ogunbanjo ni iriri ninu oselu ko ni nnkan se pelu ibi ti oro de duro bayii. O ni aisi idagbasoke ti ko jukan lọ lo n fa ipe elekunjekun

    Ogunbanjọ
    Àkọlé àwòrán, Ogunbanjọ
  9. Bi ifọrọwerọ ṣe n lọ awọn akopa n fi idunu ati iwuri han si bi awọn oludije ṣe n fọrọwerọ ti wọn si n tako ara wọn lori awọn ọ̀rọ̀ mii

    Awo akopa
    Àkọlé àwòrán, Awo akopa
  10. Ibeere fun paseda.

    Kini nnkan ti e ti se fun orisun yin?

    Paseda ni oun ni ajo fun iranlọwọ awon akeko, onisowo kereje. 'mo ti se iwonba ti mo lee se'

    Paṣeda
    Àkọlé àwòrán, Paṣeda
  11. Isaiaka dahun pe oun yoo wole lote yii. O ni oun ko mo baba ota ti won nso. Sugbon lati okan oun ni oun dìde láti wa dije.

  12. Ìb'éèrè láti orí ayélujára

    Fun Isiaka

    Se ti ko ba wole se yoo dije leemii. Se kii se baba isale ni yoo dari ogun?

    Isiaka ati Ogunbanjo lori itage
    Àkọlé àwòrán, Isiaka ati Ogunbanjo lori itage
  13. Lori oro ekun to ye ki ipo gomina kan paseda ati akinlade n tako ara won

  14. Akinlade ni eto idanileko fun araalu se pataki

  15. Isiaka ni ona meji ni oro naa. Akoko ni olaju. O ni olaju maa n fa omiyale sugbon ijoba gbodo mura si i. O ni idasile eka ileese lati maa mojuto oro omiyale yoo wa. O ni eto idagbasoke naa n faa

  16. Ogunbanjo ni aisi aato ilu n ko ba oro omiyale. O ni bi a se n gbe ise agbase sita naa n faa

  17. Lórí ọ̀rọ̀ omiyalé tó wọ́pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun

    Paseda ni fifi oju isaju gbe ise agbase fun kongila lo n fa omiyale. O ni eni to ba gba ise akanse ibi ti omi ba ti yale yoo foju wina ofin to nii ṣe pẹlu omi

  18. Akinlade lori itage
    Àkọlé àwòrán, Akinlade lori itage
  19. Awọn oludije lori itage
    Àkọlé àwòrán, Awọn oludije lori itage
  20. Ọtunba Rotimi Paṣeda ni apc, apm ati pdp iru kankan naa ni won o si daa bi won se n ba ara won ja