Ó nira láti darí iléesẹ́ Twitter, kò sì rọrùn láti lé òṣìṣẹ́ 8000 – Elon Musk, Elon Musk: Mo ṣetán láti ta Twitter, tí mo bá rí ẹni tó tọ́ láti tà á fún

Adari ileeṣẹ Twitter, Elon Musk ti ni kii ṣe ohun to rọrun fun oun lati jẹ adari ileeṣẹ Twitter.
Musk sọ eyi lasiko to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu BBC ni olu ileeṣẹ Twitter lorilẹede Amerika.
Ninu ifọrọwerọ naa lo ti sọrọ nipa bi oun ṣe le ọgọọrọ oṣiṣẹ kuro ni ileesẹ naa, awọn iroyin ofege ati bi o ṣe n ṣiṣe gẹgẹ bi adari.
Elon Musk to jẹ adari ileeṣẹ to n ṣe ọkọ ayọkẹlẹ Tesla ati ileeṣẹ to n pese rọkẹẹti, SpaceX, lo ra Twitter fun biliọnu mẹrinlelogoji dọla ni Oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja.
‘’kò rọrùn láti jẹ́ adarí iléesẹ́ Twitter’’

Lasiko ifọrọwerọ naa ni Musk gbiyanju lati jẹ pe oun lo n beere ibere lọwọ akọroyin to n ba sọrọ.
O ni oun ṣiṣẹ takun takun lati mu ki ileeṣẹ naa gberi soke ti oun ko si banujẹ lori bi oun ṣe ra ileeṣẹ naa.
Lori ibeere pe sẹ inu rẹ dun si bi oun ṣe ra ileeṣẹ Twitter, o ni kii ṣe ohun to rọrun ni lati jẹ adari ileeṣẹ Twitter, paapaa lile awọn oṣiṣẹ ba oun ninu jẹ lọpọlọp̣ọ.
Amọ o fikun un pe oun fẹran iṣẹ ti oun ṣe, kii ṣe oun to niran fun oun.
O ni lọpọ igba ni oun ma n sun si ileeṣẹ oun nitori ọpọ iṣẹ ti oun ni lati pari.
‘’Mo ni ibusun kan ni oke to rọrun lati sun si, mo si ma n lọ sibẹ lọ sun ti iṣẹ ba lera diẹ.’’
‘’Lori awọn ọrọ to ma n kọ si ori Twitter, o ni lootọ ni oun gba pe oun ma n ṣi sọ lori Twitter, ti ko si yẹ ki oun maa lo Twitter lẹyin aago mẹta oru.’’
‘’Ti moba tilẹ fẹ fi ọrọ to wọ si oju opo Twitter mi, o yẹ ki n kọ, ki n lọ sun, ki n wo ni ọjọ keji ki n to fi si ori Twitter mi.’’
‘’A o tun kọ lori Twitter pe ijọba kọ lo n ṣagbatẹru BBC , awọn araalu ni’’
Bakan naa ni Elon Musk ni awọn yoo ṣe atunse akọle ti awọn fun ileeṣẹ iroyin BBC lori Twitter.
O ni oun yoo yi pada kuro ni ileeṣẹ ti ijọba n ṣagbatẹru fun ti awọn kọ tẹlẹ si ileeṣẹ ti awọn araalu n ṣe agbatẹru fun.
Eyi ko ṣẹyin bi BBC se fi aidunnu rẹ han si BBC ṣe tun akọle ileeṣẹ naa kọ ni Twitter.








