Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Níbo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Chibok 96 tó kú wà lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án?
"N kò ríran, mo ń lọ ẹ̀rọ ata, ro fùfú lórí ààrò, mó sì ń fi ìpèníjà ojú ṣe àwàdà lórí Tik-Tok"
Àwọn adigunjalè ṣọṣẹ́ ní ọjà fóònù l'Abeokuta, pa ọlọ́jà kan, jí fóònù tó tó N14m gbé lọ
Afipábánilòpọ̀ dáná sun ara rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó díbọ́n pé òun kú fún ọdún kan, àṣírí tú
Ọwọ́ ọlọ́pàá Kwara tẹ àwọn afurasí ajínigbé, ológùn owó

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti fojú àwọn afurasí ajínigbé kan hàn.
Àwọn afurasí náà ni wọ́n ní wọ́n wà lára àwọn ajínigbé tó jí adájọ́ Oladapo Jumoke Bamigboye, tó jẹ́ ìyàwó gómìnà ológun ìgbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Bauchi àti Osun, Colonel Theophilus Bamigboye.
Àwọn afurasí náà tí olórí ikọ̀ wọn jẹ́ Abubakar Shehu tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Dogo ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ nígbà tí wọ́n tún jí ẹlòmíràn gbé.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lásìkò tó ń fojú àwọn afurasí náà hàn, Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Paul Odama ní Dogo wà lára ikọ̀ ajínigbé ẹlẹ́ni márùn-ún tí àwọn fi páńpẹ́ òfin gbé ní oṣù tó kọjá pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn fijilanté.
Lára àwọn ikọ̀ afurasí ajínigbé náà tí ọwọ́ òfin tún bà ni Mohammed Aliyu, Yunusa Ahmadu, Malami Usman àti Dauda Amosa.
Odama ṣàlàyé pé Dogo àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ni wọ́n wà nídìí bí wọ́n ṣe jí Alhaji Madaki Shuaibu gbé ní agbo àwọn Fulani kan ní Ayegun nínú oṣù kìíní ọdún 2023 tí wọ́n sì pa ọmọ Alhaji náà.
Ó fi kun pé àwọn afurasí náà tún máa ń jí àwọn màlúù gbé àti pé ọkọ̀ kan tí wọ́n máa ń lò fún iṣẹ́ ibi tí wà ní ọwọ́ àwọn.
Ó ní kété tí ìwádìí bá ti parí ni àwọn máa gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni wọ́n tún fojú àwọn afurasí ológùn owó hàn.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá náà ní ilé ìtura kan tó wà ní ìlú Malete, ìjọba ìbílẹ̀ Moro ni ọwọ́ ti ba awon afurasí yìí.
Odama ní kànìnkànìn ìbílẹ̀, aṣọ oògùn àti fóònù wá lára àwọn nǹkan tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ wọn.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti fojú àwọn afurasí ajínigbé kan hàn.
Àwọn afurasí náà ni wọ́n ní wọ́n wà lára àwọn ajínigbé tó jí adájọ́ Oladapo Jumoke Bamigboye, tó jẹ́ ìyàwó gómìnà ológun ìgbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Bauchi àti Osun, Colonel Theophilus Bamigboye.
Àwọn afurasí náà tí olórí ikọ̀ wọn jẹ́ Abubakar Shehu tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Dogo ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ nígbà tí wọ́n tún jí ẹlòmíràn gbé.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lásìkò tó ń fojú àwọn afurasí náà hàn, Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Paul Odama ní Dogo wà lára ikọ̀ ajínigbé ẹlẹ́ni márùn-ún tí àwọn fi páńpẹ́ òfin gbé ní oṣù tó kọjá pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn fijilanté.
Lára àwọn ikọ̀ afurasí ajínigbé náà tí ọwọ́ òfin tún bà ni Mohammed Aliyu, Yunusa Ahmadu, Malami Usman àti Dauda Amosa.
Odama ṣàlàyé pé Dogo àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ni wọ́n wà nídìí bí wọ́n ṣe jí Alhaji Madaki Shuaibu gbé ní agbo àwọn Fulani kan ní Ayegun nínú oṣù kìíní ọdún 2023 tí wọ́n sì pa ọmọ Alhaji náà.
Ó fi kun pé àwọn afurasí náà tún máa ń jí àwọn màlúù gbé àti pé ọkọ̀ kan tí wọ́n máa ń lò fún iṣẹ́ ibi tí wà ní ọwọ́ àwọn.
Ó ní kété tí ìwádìí bá ti parí ni àwọn máa gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni wọ́n tún fojú àwọn afurasí ológùn owó hàn.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá náà ní ilé ìtura kan tó wà ní ìlú Malete, ìjọba ìbílẹ̀ Moro ni ọwọ́ ti ba awon afurasí yìí.
Odama ní kànìnkànìn ìbílẹ̀, aṣọ oògùn àti fóònù wá lára àwọn nǹkan tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ wọn.
Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá mẹ́ta fẹ́sùn pé wọ́n hùwà lòdì sí òfin

Oríṣun àwòrán, POLICE NGR
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mẹ́ta kan fẹ́sùn wí pé wọ́n lòdì sí òfin iṣẹ́ ọlọ́pàá.
Àwọn ọlọ́pàá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni Dahiru Shuaibu, Abdullahi Badamosi àti Isah Danladi.
Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, Olumuyiwa Adejobi fí léde ní ìlú Abuja ní àwọn ọlọ́pàá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà yìbọn lọ́nà àìtọ́ níbi ètò kan ní ìpínlẹ̀ Katsina lọ́jọ́ Ẹtì tó kọjá.
Àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún ló jẹ́ àwọn tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi tí olórin kan, Dauda Adamu Kahutu Rarara.
Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Keje oṣù Kẹrin ni ariwo sọ lórí ayélujára nígbà tí fídíò kan ṣàfihàn bí àwọn ọlọ́pàá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ṣe ń yìbọn sókè nígbà tí olórin tí wọ́n ń tẹ̀lé ń lọ sínú ọkọ̀ rẹ̀ láti òde kan ní ìpínlẹ̀ Katsina.
Nígbà tí fídíò náà gba orí ayélujára ni ilé ọlọ́pàá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fojú àwọn ọlọ́pàá tó wà nídìí rẹ̀ winá òfin.
Àtẹ̀jáde tí Agbẹnusọ ọlọ́pàá fi síta ní yàtọ̀ sí pé ìwà tí àwọn ọlọ́pàá yìí hù nípa yíyin ìbọn sókè níbi tí ọ̀pọ̀ èrò wà lòdì sí òfin àwọn, ó ní ìwà ọ̀daràn gbá à ló jẹ́.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ló wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, tí ìwà náà sì lè kó ẹrẹ̀ bá ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.
Bákan náà ló rọ àwọn ọlọ́pàá káàkiri Nàìjíríà láti máa tẹ̀lé òfin tó dé iṣẹ́ wọn kí àwọn náà má bà á lu idà òfin lójú.
Fijilańté yarí, kọlu ibùba ajínigbé tó jí èèyàn méjìlá, òkú sùn
Yóò nira láti rí ìwòsàn fún àìsàn jẹjẹrẹ lọ́jọ́ iwájú - Àwọn Olúwádìí

Oríṣun àwòrán, FRANCIS CRICK INSTITUTE
Iwadi awọn oluwadi kan ti fihan pe lati isin yii lọ ati ti ti ayeraye, aarun jẹjẹrẹ yoo maa tẹsiwaju lati se ijamba lago ara eeyan ati pe yoo nira pupọ lati iwosan fun aisan naa lọjọ waju..
Esi iwadi naa lọ jẹyọ lẹyin ti awọn onimọ isegun se ayẹwo lori ẹni to ni aarun naa fun ọdun mẹsan, ti esi iwadii naa si dẹruba wọn saaju isẹ to wa niwaju wọn.
Ni pari. wọn pinnu pe o se koko pe ki eeyan da bobo ara rẹ lọwọ aarun naa nitori yoo nira ri iwosan fun lọjọ iwaju
Igbimọ iwadi Cancer ni Ilẹ Gẹẹsi ni o se koko pe ki eeyan tete mọ pe oun ni aarun lara
Iwadi naa tun pese alaye lori bi aarun jẹjẹrẹ se bẹrẹ ati nnkan to fa.
Aarun jẹjẹrẹ maa yipa lorekore sugbọn ni ara ọtọ.
"Àwọn agbébọn ṣekúpa àbúrò mí obìnrin, yínbọ̀n fún bàbá mi lásìkò ìkọlù"
Èèyàn mẹ́je farapa níbi ilé alájà méje tó dàwó l‘Eko, òṣìṣẹ́ kan sọnù, kò sẹ́ni tó kú - Ìjọba Eko
Àwọn tó sun ọmọ mi níná ní ó wọ aṣọ olówó ńlá táwọn kò rí irú rẹ̀ wọ̀, ni wọn ṣe pa á - Ìyá Tope Olorunfemi
Ìtàn Ọba Yorùbá tí wọ́n yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
N kò lè jẹ́ ọmọ Nàíjíríà mọ́ níbi tí Bola Tinubu ti di ààrẹ - Igbákejì gómìnà àná l‘Eko
"Ó kù díẹ̀ kí ń kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní fásitì, ni mo gbà pé iṣẹ́ atọ́kọ̀ṣe ni màá fi jẹun"
Ìyá arúgbó ẹni ọdún 78 wọ gbaga fẹ́sùn ìdigunjalè
A ṣì ń wá ènìyàn kan nínú ilé tó dàwó l'Ekoo - LASEMA

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Kò dín ní ènìyàn méje tí wọ́n móríbọ́ nínú ilé tó dà wó lulẹ̀ lọ́jọ́rú ní agbègbè Banana Island, Ikoyi, ìpínlẹ̀ Eko.
Ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni ilé alájà méje tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ náà ṣàdédé dà wó lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́.
Ìròyìn ní pé àwọn òṣìṣẹ́ kan mórí ọ́ láì farapa, tí àwọn mìíràn sì farapa kékeré, tí àwọn mìíràn sì tún há sábẹ́ ilé náà.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASTMA ní àwọn ṣì ń wá ènìyàn kan tó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ó há sábẹ́ ilé náà.
Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní orí àjà kẹfà ilé náà ní àwọn ṣiṣẹ́ dé láti gbé àjà keje le lórí kí ilé náà tó dà wó lulẹ̀.
Àtẹ̀jáde kan tí ọ̀gá àgbà àjọ LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu fi léde ní ìwádìí fi hàn pé ọkọ̀ ńlá tó ń po sìmẹ́ǹtì ló ṣokùnfà bí ilé náà ṣe dàwó.
Oke-Osanyintolu ṣàlàyé pé nígbà tí ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ ààbò ilé náà, Anthony Onah ka àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó ku òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń wá tó sì ṣeéṣe kó ṣì wà lábẹ́ ilé ọ̀hún.
Ó ní iṣẹ́ ń lọ láti ṣàwárí ọkùnrin náà, àti pé gbogbo àwọn ohun èlò tí àwọn nílò láti fi ṣiṣẹ́ ló ti wà níbẹ̀.
Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Eko, Margaret Adeseye nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ní ènìyàn méje ni àwọn ti yọ tó sì jẹ́ wí pé wọ́n farapa.
Adeseye ní ènìyàn kan ló ṣì wà tó há sábẹ́ ilé náà tí iṣẹ́ kò sì dúró láti yọ ẹni náà.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Àkọlé àwòrán, Irinṣẹ́ láti fi dóòlà àwọn tó há sábẹ́ ilé Àgbàrá òjò pa ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ọ̀pọ̀ ènìyàn tún di àwátì l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Others
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìjàm̀bá omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ni agbègbè kan ní ìlú Sagamu, ìpínlẹ̀ Ogun.
Bákan náà ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tún di àwátì lásìkò tí ẹ̀kúnwọ́ omi ṣọṣẹ́ ní àwọn agbègbè bíi Ajaka, Express Junction, Ogunyanwo, Olayinka àti Isale-Ojumele ní ìlú Sagamu lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Ọmọ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ wọ aṣọ ilé ẹ̀kọ́ girama Agbele gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní orí ọ̀kadà tí ọmọ ọ̀hún wà ni ẹ̀kúnwọ́ omi ti wọ lọ.
Bákan náà ni ìròyìn tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ dúkìá ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ló tún sọnù sínú ìjàm̀bá náà ní agbègbè Makun tí ọ̀pọ̀ ará ìlú sì farapa.
Àwọn ará àdúgbò náà kọminú pé bí nǹkan ìní àwọn ṣe máa ń bàjẹ́ ní gbogbo àsìkò òjò nìyí nítorí kò sí kòtò ìdaminù tó já gaara ní agbègbè náà.
Lára àwọn ará àdúgbò náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wáyé lọ́dún to kọjá tí àwọn sì ké gbàjarè lọ sọ́dọ̀ ìjọba.
Wọ́n ní àìsí ibi tí omi máa gbà kọjá ló ń fà á tí omi fi ń ya wọ ilé àwọn tí àwọn sì rò pé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún to kọjá máa mú kí ìjọba tètè dìde sọ́rọ̀ àwọn.
Wọ́n ní ó ṣeni láàánú pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tún pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lórí ìjàm̀bá yìí kan náà.
Kọmíṣọ́nà fún ètò àyíká ìpínlẹ̀ Ogun, Ọla Oresanya nígbà tó ṣe àbẹ̀wò síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìwé ìlànà bí àwọn ṣe ń kọ́ ilé ti pọn dandan báyìí.
Oresanya ké sí ìjọba àpapọ̀ láti ran ìpínlẹ̀ Ogun lọ́wọ́ lórí àjálù ọ̀hún.
Ó ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun náà yóò gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ nípa kíkọ́ kòtò ìdaminù sí agbègbè náà láìpẹ́.
INEC fún Obi, Atiku lésì nílé ẹjọ́, Ó ní Tinubu ló borí ìbò ààrẹ
Ìdí tí ‘UK Immigration’ fi tàbùkù Peter Obi, kí wọn tó tìí mọ́lé fúngbà díẹ̀