Ọjà kún 'nítorí ìdìbò ààrẹ'

Ẹ kaabọ si oju opo BBC Yoruba, wọnyi ni ohun ti awọn akoroyin wa to ti kalẹ kaakiri Naijiria n jabọ nipa ipalẹmọ idibo Aarẹ Naijiria.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Ahmed Ambali and Busayo Akogun

  1. Fayose n ṣe ipolongo fun Atiku lado, Lọja Oba nilu Ado lakọroyin wa ti pade Gomina ana Ekiti to n polongo fun oludijẹ ipo Aarẹ ẹgbẹ PDP

      • Author, Foluke Ogunbayo
      • Role, Broadcast Journalist

    Gomina ana nipinlẹ Ekiti Ayodele Fayose kii ṣe ẹni ti akọroyin yoo pade ti ko ni fẹ gbọ ohun to ni ṣọ.

    Akọroyin wa nilu Ado ṣabapade rẹ ni Oja Oba nibi ti o ti n polongo fun oludije ipo Aarẹ ẹgbẹ rẹ Atiku Abubakar.

    A o ma mu ifọrọwero to ni pẹlu akọroyin wa wa seti igbọ yin.

    Ẹ tẹti leko loju opo www.bbc.com/yoruba

    Aworan Gomina ana ni ipinlẹ Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Gomina ana ni ipinlẹ Ekiti
  2. Aabo to peye wa fun awọn oludibo-Ọga ọlọpaa Kwara ati Ondo, Ninu ifọrọwanilẹnuwo, awọn ọga ọlọpaa mejeeji ni ko si ewu loko nipa idibo Aarẹ

      • Author, Yemisi Oyedepo
      • Role, Broadcast Journalist

    Ọga Ọlọpaa ipinlẹ Kwara wa lara awọn ọga ọlọpaa ti wọn ṣẹṣẹ gbe lo si ipinlẹ kaakiri Naijiria bi idibo ti ṣe sunmọ.

    Ẹ gbọ ohun ti Kayode Egbetokun sọ fun akọroyin wa ninu fọnran fidio yi.

    Àkọlé fídíò, Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Oga ọlọpaa ni Kwara ati Ondo nipa idibo Aarẹ
  3. Ohun elo idibo nipinlẹ Oyo ati Ondo naa ti balẹ, Igbaradi ni ipinlẹ Ondo ko yọ ẹni ibusun silẹ fun awọn oṣiṣẹ ajọ Inec

      • Author, Funmi Jokotade
      • Role, BBC Yoruba, Lagos

    Ajọ eleto idibo Inec ẹka ti ipinlẹ Oyo ti tẹwọgba awọn ohun elo fun idibo gbogbogbo ti yoo waye lọjọabamẹta bẹẹsini awọn ohun elo naa ti n jẹ pinpin kaakiri awọn ijọba ibilẹ to n bẹ ni ipinlẹ Oyo.

    Lara ohun elo idibo to ṣe pataki fun awọn oṣiṣẹ ajọ Inec ti ayaworan wa ri ni ẹni ti awọn oṣiṣẹ Inec yoo fi sun lagbegbe ibi ti wọn ba gbe wọn lọ lati lọ ṣiṣẹ

    Aworan ẹni ti wọn ko si ọkọ fun awọn oṣiṣẹ Inec
    Àkọlé àwòrán, Ajọ Inec nipinlẹ Ondo ko fi igbayegbadun awọn oṣiṣẹ́ wọn jafira pẹlu bi wọn ti ṣe pese ẹni ibusun fun wọn.
  4. Ohun elo idibo Kwara ko tete de, Ọtọ ni ọmọ sori ni ipinlẹ Kwara

    Awọn nnkan idibo ṣe bi ẹni pẹ de nipinlẹ Kwara ṣugbọn wọn pada de nirọwọrọsẹ.

    Inu ọgba ile ifowopamọ apapọ CBN ni wọn si wa nibi ti wọn yoo ti fi wọn ṣọwọ si olu ile iṣẹ ajọ Inec ni ipinlẹ Kwara.

    Akọroyin wa Yemisi Oyedepo lo jabọ fun wa.

    Aworan nnkan elo idibo ipinlẹ Kwara
    Àkọlé àwòrán, Aworan nnkan elo idibo ni Kwara to pẹ de diẹ
    Aworan awọn agbofinro to wa ni ṣepẹ ni Ilorin
    Àkọlé àwòrán, Awọn agbofinro naa wa ni ṣepẹ ni Ilorin
  5. INEC ní kò leè sí ààyè fún 'dìbò kóo sebẹ̀', Akọwe agba ajọ Inec ni awọn ati agbofinro n fori kori lori ọrọ abo.

    Ajọ INEC ni atunto ti de ba eto idibo eleyi ti yoo mu ki o ṣoro fun ẹnikẹni lati ra ibo lasiko eto idibo apapọ ọdun 2019.

    Akọwe agba fun ileeṣẹ ajọ INEC nipinlẹ Ekiti,Ọmọwe Muslim Ọmọlẹkẹ ṣalaye pe ajọ INEC ti gbe atunto ilana idibo kalẹ eleyi ti yoo mu iṣoro ba aṣa dibo koo sebẹ lasiko idibo apapọ 2019.

    Aworan awọn oṣiṣẹ Inec
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣise Inec n yẹ awọn ẹrọ kaadi idibo wo
  6. Bi ipalẹmọ́ idibo ti ṣe n lọ ni Kwara,Ogun, Osun ati Ekiti, Awọn akọroyin wa yoo ma jabọ bi nnkan se n lọ lẹsẹsẹ fun yin

      • Author, Ahmed Ambali
      • Role, BBC Yoruba, Lagos

    A ki yin kaabọ si oju opo BBC Yoruba nibi ti a ti n mu iṣẹlẹ ni waransesa wa fun yin nipa ipalẹmọ de idibo Aarẹ Naijiria ti yoo waye lọjọ ti.

    Orukọ mi ni Ahmed Ambali emi si ni wọn maa tukọ bi awọn iroyin naa yoo ṣe ma de si eti igbọ yin.

    Jakejado Naijiria ni awọn akọroyin wa ti wa lati ma mu bi nnkan ti ṣe n lọ wa si eti igbọ yin.

    Aworan akọroyin BBC
    Àkọlé àwòrán, Aworan awọn akọroyin BBC