Ẹ kaabọ si oju opo BBC Yoruba, wọnyi ni ohun ti awọn akoroyin wa to ti kalẹ kaakiri Naijiria n jabọ nipa ipalẹmọ idibo Aarẹ Naijiria.
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Ahmed Ambali and Busayo Akogun
Ọdaran 181 lọwọ wa ti tẹ nipalẹmọ de idibo
Oga Ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ti salye awọn igbesẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe lati le mu ki eto idibo lọ ni pẹlẹkutu nipinlẹ naa.
O tun fi asiko ifọrọwero naa parọwa si awọn ara ilu lati bọwọ fofin lasiko idibo aarẹ Naijiria.
Àkọlé fídíò, Oga olopaa ipinlẹ Ekiti sọrọ bi ipalẹmọ de ibo ṣe n lọ.
Ọgba Banki apapọ Naijiria ni INEC ti pin eroja idibo l'Ondo
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ INEC to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe awọn ko le pin awọn nkan idibo naa ni ọọfisi INEC nitoripe wọn pọ, idi eyi si ni wọn fi duro pin in fun gbogbo awọn ijọba ibilẹ ninu ọgba banki apapọ Naijiria fun eto aabo to peye.
Awọn eleto aabo duro lati daabo bo awọn eroja idibo ni banki apapọ Naijiria.
Àkọlé àwòrán, Awọn eleto aabo duro lati daabo bo awọn eroja idibo ni banki apapọ Naijiria.
Okun inu laa fi gbe tita!
Ajọ Inec ko fi ọrọ ounjẹ tawọn agbofinro yoo jẹ ṣere nipinlẹ Rivers.
Oun ti ẹyẹ ba jẹ ni yoo gbe fo ni wọn fi ọrọ naa ṣe.
Àkọlé àwòrán, Aworan ounje ti wọn pese fun awọn agbofinro
Kini ẹṣẹ wa ti INEC ko fi gba wa siṣẹ?
Awọn ọdọ kan ni ipinlẹ Kwara fi aidunnu wọn han si bi wọn ko ṣe ni le e kopa gẹgẹ bi oṣiṣẹ ajọ INEC lasiko idibo aarẹ.
Awọn ọdọ naa sọ fun BBC Yoruba pe lẹyin gbogbo igbiyanju awon lati rii pe awon sisẹ fun INEC ni asiko yii, sibe oruko awon ko jade lẹyin idanilẹkọ ti awọn lọ fun.
Àkọlé àwòrán, Ajọ INEC maa n gba ọpọlọpọ eniyan siṣẹ lati kun awọn oṣiṣẹ rẹ lọwọ lasiko eto idibo
Igbaradi ti n lọ ni ipinlẹ Adamawa
Ajọ eleto ti bẹrẹ si ni pin awọn eroja idibo ni ipinlẹ Adamawa. Awọn onwoye
idibo naa si darapọ mọ wọn lati mojuto bi wọn ṣe n pin.
Àkọlé àwòrán, Niṣe ni awọn oṣiṣẹ alaabo duro wamu-wamu lati pese aabo nibi ti wọn ti n pin awọn eroja idibo.
Àkọlé àwòrán, Awọn onwoye idibo lati ilẹ okeere naa darapọ mọ wọn nibi eto naa.
Atunde lojumọ toni
E kaabọ soju opo wa fun loni Ọjọ Ẹti.
Aku imurasilẹ fun eto idibo gbogboogbo Naijriia.
Ni wakata diẹ to ku ti idibo yoo bẹrẹ, a ṣetan lati ma mu bi gbogbo eto ṣe n lọ jakejado Naijira wa fun yin.
Àkọlé fídíò, #NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí
Ẹseun pupọ!, Nibi ni a o fi adagba eto rọ si laṣalẹ oni
Lorukọ gbogbo awọn akẹgbẹ mi ti ati jọ ṣe akojọpọ iroyin wọn yi fun yin, a n ki yin pe ẹseun fun aduroti wa.E kan si wa lawọn ojuopo wa www.bbc.com/yoruba fun ẹkunrẹrẹ iroyin miran
Kasunre .
Aworan bi ipalẹmọ ṣe n lọ ni ipinlẹ Ogun
Àkọlé àwòrán, Aworan ipalẹmọ nipinlẹ Ogun
Àkọlé àwòrán, Aworan ipalẹmọ nipinlẹ Ogun
Àkọlé àwòrán, Aworan ipalẹmọ nipinlẹ Ogun
O ṣeeṣe ki rogbodiyan waye lasiko ibo, Ajọ kan to n ṣe agbatẹru iwoye idibo ni ki ijọba mojuto awọn nnkan to le fa a
Kimpact Development Initiative nilu Osogbo pẹlu ajọsepọ Nigerian Election Violence Report ti sọ fun akọ́royin BBC pe awọn funra si pe rogbodiyan le waye ni ipinlẹ Oyo ati Eko .
Wọn ni ọna ati dẹkun iru iṣẹlẹ bẹẹ ni ki ijọba mojuto awọn nnkan to le fa rogbodiyan naa
Inec yoo pese awo oju fun awọn afin lasiko ibo aarẹ, Iroyin ayọ ni eleyi jẹ fun awọn afin lasiko ibo aarẹ Naijiria
Awọn afin ni ipinlẹ Cross River yoo laanfani lati dibo laisi idiwọ.
Eyi waye latari bi ajọ Inec yoo ti ṣe pese awo oju ti yoo jẹ ki wọn rina daada.
Ajọ Inec nipinlẹ naa salaye pe awọn ṣi n duro de iwe ti awọn afọju yoo lo lati le dibo.
Àkọlé àwòrán, Awo oju ti Inec pese fun awọn afin
Idagbere Ikẹyin ni Buhari n ṣe-Fayose, Gomina ana naa jẹ ojulowo alatako Aarẹ Buhari
Gomina ana nipinlẹ Ekiti Ayodele Fayose naa ti da si ọrọ Aarẹ Buhari to ba awọn ọmọ Naijiria sọ lori ẹrọ amohunmaworan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
End of X post
Kilo de ti Buhari n fi ikede rẹ ṣe ipolongo si wa?, Loju opo Twitter awọn ọmọ Naijiria ti n ṣe kayefi pẹlu ikede Aarẹ Buhari
Awọn ọmọ Naijiria ti n fesi si ikede Aarẹ Buhari eleyi ti o ti n ba awọn eeyan Naijiria sọrọ lori ẹrọ amounmaworan Naijiria NTA.
Pupọ lo n ṣe kayefi bi ikede naa ti ṣe gba ọna ipolongo lọ ti Buhari si n ka aseyọri ijọba rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
End of X post, 3
Aarẹ Buhari ti n ba ọmọ Naijiria sọrọ saaju idibo, Ikede to wa lati ileeṣẹ Aare ni ago meje alẹ ọjọbọ ni Aarẹ yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ
Aarẹ Buhari fi akoko yi sọ nipa aṣeyọri ijọba rẹ paapa julọ lẹka ọrọ aje nibi ti o ti ni awọn ti mu adinku ba ẹlewo ọja.
Ikede yi ni eleyi ti Buhari yoo se kẹyin saaju idibo.
Oríṣun àwòrán, NTA
Àkọlé àwòrán, Buhari n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ
Atiku Abubakar kadi eto ipolongo rẹ ni Yola, Atiku Abubakar dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ re ti o si gba wọn ni iyanju lati tuyaya wa dibo
Lọni tii ṣe ọjọ kẹrinla osu Keji ni ipolongo idibo de opin saaju idibo gbogbogbo Naijiria.
Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP to n lewaju ninu awọn to n koju Aarẹ Buhari kadi eto idibo rẹ nilu Yola lẹyin ti o ti saaju ṣe ipolongo ni ilu Abuja.
Wọn yi ni awọn aworantofi si oju opo rẹ lati ibi ipolongo naa.
Oríṣun àwòrán, @atiku
Àkọlé àwòrán, Atiku fi opin si ipolongo rẹ
Oríṣun àwòrán, @atiku
Oríṣun àwòrán, @atiku
Ko ni si irina ọkọ laarin ago mẹfa aarọ si ago mẹfa irọlẹ, Ọga ọlọpaa Naijiria lo kede eto irina yi lakoko idibo Aarẹ ti yoo waye lọjọ ẹti
Ọga ọlọpaa Naijiria ti kede eto irina eleyi ti wọn ni yoo jẹ́ ki eto idibo lọ ni irọwọrọsẹ.
Atẹjade kan lorukọ Ọga agba ọlọpaa ti Frank Mba fi sita ni ki awọn janduku yago fun dida wahala silẹ lasiko idibo naa.
Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Àkọlé àwòrán, Ko ni si aaye irina laarin ago mẹfa aarọ si ago mẹfa irọlẹ
Wọn ko ti pin nnkan elo idibo Ondo, Awọn nnkan idibo naa ṣi yi wa ni ile ifowopamọ apapọ l'Akure
Titi di bi akọrọyin wa ti ṣe fi iroyin ranṣẹ́ si wa,awọn nnkan idibo ti ajọ Inec yoo lo ni iluAkure ko ti bẹrẹ irinajo wọn lọ si ibi ti wọn yoo ti ma lo wọn.
Àkọlé àwòrán, Awọn nnkan idibo
Àkọlé àwòrán, Awọn nnkan idibo
Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ọlọpaa ni ile ifowopamọ agba ni Akure
Inec ipinlẹ Ekiti naa lodi si aṣa ibo rira, Aṣa ibo rira jẹ ohun ti o n kọ awọn eeyan lominu nipa ibo aare to n bọ lọna
Article Information
Author, Foluke Ogunbayo
Role, Broadcast Journalist
Ogbẹni Muslim Omoleke to jẹ agọ eleto idibo Inec nipinlẹ Ekiti naa sọ nipa rira ibo.
Ẹ gbọ ohun to sọ
Àkọlé fídíò, Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Oga Inec ni Ekiti nipa ipalẹmọ de idibo Aarẹ
Ẹyin naa le fi iroyin ṣọwọ si wa, BBC Yoruba ti fi nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti ẹ le fi aworan tabi iṣẹ ranṣẹ si yin
Gbogbo wa la o jọ kopa ninu idibo Aarẹ yi.
Ki ẹyin naa baa le ni anfaani,BBC Yoruba ti ṣe agbekalẹ nọmba ibaraẹnisọrọ ti ẹ le fi aworan yin tabi iwe atẹjisẹ ranṣẹ siwa loju opo Whatsapp.
Ẹ ma gbagbe hashtag wa #BBCNigeria2019
Ẹ yara kọ silẹ.
Àkọlé àwòrán, Ikede lati ọdọ BBC Yoruba
Oṣiṣẹ Inec to ba fayegba ibo rira yoo fojuwina, Alamojuto eto idibo Inec nipinlẹ Ondo ni ko si aye 'see and buy' ninu ibo Aarẹ
Article Information
Author, Funmi Jokotade
Role, BBC Yoruba, Lagos
Ọga ajọ eleto idbo nipinlẹ Ondo, Rufus Akẹju ti fi ikilọ sita fun awọn oṣiṣẹ Inec to ba n gbero lati fayegba ibo rira ninu idibo Aarẹ ọjọ ẹti.
O ni ẹni to ba dan wo yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
O salaye fun akọroyin wa Funmi Jokotade pe awọn ko ni gba ẹrọ ibanisọrọ nidi apoti ibo ki awọn oludibo bama fi lo lati ṣe 'see and buy'
O ni ipenija to n koju Inec nipinlẹ Ondo ni bi awọn oṣiṣẹ awọn yoo ti ṣe de awọn ilu to wa lori omi nipinlẹ naa lasiko.
Akeju ni awọn ti n ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹgbẹ awako ori omi lati de awọn ilu bẹẹ.
Àkọlé fídíò, Oga Inec nipinlẹ Ondo ni ko ni si aye fun 'see and buy'
Awọn ọmọ ẹgbẹ APC taku siwaju ileeṣẹ Inec ni Rivers, Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ni dandandan ki Inec fi orukọ oludije awọn sori iwe idibo
Iwọde awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Rivers lọjọbọ da lori pe awọn fẹ ki ajọ naa fi orukọ oludije awọn si ori iwe idibo saaju idibo ọjọ ẹri.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa Nnamdi Omoni fidi ọrọ naa mule ti o si ni awọn ọlọpaa yin afẹfẹ tajutaju lu awọn oluwọde naa nigba ti ipa ko fẹ ka wọn mọ. O ni ohun gbogbo ti bọ si ipo pada.