Olùkọ́ tó ní ìpèníjà ojú kàwé gboyè Ọ̀mọ̀wé ní fásitì, ó ní ó wu òun láti jẹ́ amòfin, máa jà fún ọmọnìyàn

Olùkọ́ tó ní ìpèníjà ojú kàwé gboyè Ọ̀mọ̀wé ní fásitì, ó ní ó wu òun láti jẹ́ amòfin, máa jà fún ọmọnìyàn
Published

Yoruba ni ọmọ ti yoo jẹ Asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samusamu.

Bakan naa ni wọn sọ pe ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiitin nitori ipenija ko ni ka ma de ibi giga.

Bi ọrọ se ri ree pẹlu olukọ fasiti kan, Emmanuel Modurotimi Olubodede, ẹni to kawe gboye ọmọwe, to si jẹ olukọ nile ẹkọ fasiti Adekunle Ajasin to wa nilu Akungba Akoko nipinlẹ Ondo.

Olukọ naa, to ti kawe kẹkọ gboye imọ ijinlẹ Ọmọwe lo ni ipenija oju amọ eyi ko se idiwọ lati kawe rẹpẹtẹ.

BBC News Yoruba fọrọ wa olukọ naa, Modurotimi Olubodede lẹnu wo lati mọ bi ipenija oju rẹ se waye ati awọn ipenija to koju titi to fi kawe gba oye Ọmọwe.

"Mo maa n riran kedere titi mo fi pe ọmọ ọdun mẹrin amọ nigba to ya, mo oju bẹrẹ si ni dun mi, titi ti n ko fi riran mọ"

Nigba to n ba BBC news Yoruba sọrọ, Ọmọwe Modurotimi Olubodede salaye pe kii se inu oyun ni ipenija oju naa ti bẹrẹ pẹlu oun.

O ni oun si riran kedere titi di igba ti oun pe ọmọ ọdun mẹrin, amọ nigba to ya, mo oju bẹrẹ si ni dun mi, titi ti n ko fi riran mọ.

"Ipenija oju naa ko jẹ ki n bẹrẹ ileẹkọ ni akoko to yẹ ki n bẹrẹ, mo to ọmọ ọdun mejila ki n to bẹrẹ ile ẹkọ.

Idi ni pe ile ẹkọ fawọn akanda ẹda ti wọn sẹsẹ da silẹ ni mo lọ, mo lo ọdun mẹfa nibẹ, ti mo si bẹrẹ ile ẹkọ giga lọmọ ọdun mejila.

Lẹyin ti mo pari eto ẹkọ girama, mo wa nile fun igba diẹ, ki n to wa lọ sile ẹkọ fasiti."

"Erongba mẹta ti mo ni nile ẹkọ giga ni lati jẹ amofin, Sọrọsọrọ ati Olukọ"

Ọmọwe Modurotimi Olubodede tẹsiwaju pe erongba mẹta ni oun ni fun igbe aye oun nigba ti oun wa nile ẹkọ girama.

"Erongba akọkọ ni lati jẹ Amofin tori mo nifẹ lati maa gbeja awọn eeyan, mo mọ pe ti mo ba jẹ amofin, maa le maa ja fun ẹtọ ọmọniyan.

Ikeji ni pe mo fẹ lati sisẹ lori redio, ki n le maa lo awọn eto ti mo ba n se lati maa nipa lori awọn eeyan.

Erongba kẹta ti mo ni ni pe o wu mi lati jẹ olukọni, ki n le lọ maa sisẹ olukọ nile ẹkọ awọn akanda ẹda ti mo ti jade, ki n le lọtun ibẹ se."

Nigba to n salaye bo se maa n pese ara rẹ silẹ lasiko to ba fẹ kọ awọn akẹkọọ rẹ, Ọmọwe Modurotimi Olubodede ni oun ti maa n pese awọn koko to se pataki silẹ fun imọ ẹkọ ti oun fẹ kọ.

" Fun ẹni to ni ipenija oju, o rọrun lati kọ awọn akẹkọ ile ẹkọ giga ju awọn akẹkọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ lọ.

Idi ni pe nile ẹkọ giga, awa atawọn akẹkọ maa sọrọ ni, kii se pe a sẹsẹ maa kọ nnkan soju patako.

Awọn akẹkọ mi maa n ro pe awọn le yọ wọ inu kilaasi mi tori n ko ni mọ amọ ti mo ba pe akiyesi wọn si, o maa n ya wọn lẹnu pupọ.

Gbogbo awọn ipenija yii maa n wa pupọ.

"O maa n nira lati tun ra awọn ohun elo to ba bajẹ, abi elo ni mo n gba ti maa ra ohun elo to to miliọnu mẹta Naira"

Ọmọwe Modurotimi Olubodede tun salaye pe ko tii si ọna abayọ tabi iwosan fun ipenija oju to ni lọwọlọwọ bayii.

"Wọn ko pese akanse ohun elo kankan fun emi ti mo ni ipenija oju, owo mi ni mo fi n ra gbogbo nnkan ti mo n lo.

Amọ o maa n nira lati tun ra awọn ohun elo to ba bajẹ, abi elo ni mo n gba ti maa maa ọ ra ohun elo to to miliọnu mẹta Naira.

Bi o tilẹ jẹ pe ti mo ba ra, yoo se iranwọ fun isẹ mi amọ owo osu wa kere pupọ."

Olubodede wa rọ awọn eeyan ti wọn jọ ni ipenija oju lati ni ipinnu ọkan pe awọn fẹ di ẹni nla laye tori eyi yoo mu wọn se aseyọri.

Bakan naa, awọn akanda ẹda ko gbọdọ ti ara wọn mọ inu ile, mo si tun n rọ awọn to ba ni awọn akanda ẹda sile lati ko wọn jade."

John-Mary Aladesuyi, to jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ to n gba idanilẹkọ lọdọ Ọmọwe Modurotimi Olubodede naa ba BBC News Yoruba sọrọ.