"Abuja ni ọmọ mi ní òun ti ń ṣiṣẹ́, kìí ṣe oníjọ̀ngbọ̀n, àhésọ̀ ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kò yé mi tí ọlọ́pàá ṣe ba irin ara ògiri àti ìlẹ̀kùn ilé jẹ́ láti fi tipá wọlé"

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 14

Ni ọjọ Isẹgun ni iroyin gbalẹ kan pe ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa ti lọ gbe Baba Adeniyi Adeyemi, ti ileesẹ aarẹ fẹsun kan pe o da ayederu ileesẹ silẹ eyi to so mọ ileesẹ aarẹ.

Iroyin naa ni lẹyin ti Adeniyi Adeyemi di awati, ni ileeṣẹ ọlọpaa nawọ gan baba rẹ, alagba Adetunji Adeniyi.

Ọjọ Aje ni iroyin naa sọ pe awọn ọlọpaa gbe baba naa nile rẹ nilu Ogbomoso.

Idi ree ti BBC News Yoruba fi morile ilu Ogbomoso lati mọ bi wọn se mu baba naa, ka si bawọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn sọrọ.

Amọ iyalẹnu lo jẹ fun wa pe awọn ọlọpaa ti fi baba naa silẹ lẹyin wakati diẹ ti wọn gbe e, to si ti wa ninu ile rẹ nilu Ogbomoso.

Alagba Adetunji Adeniyi wa ba BBC News Yoruba sọrọ nipa ohun to la kọja lọwọ ọlọpaa ati ohun to mọ nipa ọmọ rẹ.

"Gbogbo irin babu waya ti a fi yi ogiri ile po ati ilẹkun ọna mi ni wọn bajẹ, ti wọn si gba fẹnsi wọle"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, alagba Adetunji Adeyemi ni ogiri fẹnsi ile oun ni awọn ọlọpaa gba wọle sinu ile naa.

Adetunji Adeniyi ni "Gbogbo irin babu waya ti a fi yi ogiri ile po ati ilẹkun ọna mi ni wọn bajẹ, ti wọn fi gba fẹnsi wọle.

Wọn bẹrẹ sii gba gbogbo ilẹkun ni gba gba gba.

Mo beere wi pe lati ibo ni wọn ti wa, wọn si sọ pe ẹṣọ alaabo ni awọn jẹ.

Mo sọ pe n ko ni sikiọriti nile, ṣugbọn wọn sọ pe sikiọriti ijọba ni awọn, eyi lo jẹ ki n ṣilẹkun fun wọn."

Alagba Adetunji tẹsiwaju pe bi oun ṣe ṣilẹkun fun wọn tan, loju ẹsẹ ni gbogbo wọn ti da wọle.

O ni gbogbo inu ile oun ni wọn yẹwo, titi kan gbogbo inu ibi ti oun n ko aṣọ si ati ile idana ni wọn yẹwo.

Adeniyi fikun pe nigba to ya ni wọn lọ, iyẹn ni nnkan bi agogo kan ọsan.

Sugbọn nigba to tun di bi agogo meji aabọ, wọn tun pada wa, wọn si ko foonu wa, ko to di pe wọn tun lọ.

"Nigba to di nnkan bi agogo mọkanla aabọ ni aarọ, bi wọn tun ṣe de niyẹn.

Koda bi eeyan ba gbe ṣigidi min, bawo ni ọkan ko ṣe ni mi soke, wi pe ewo tun leleyi, iwọ Ọlọrun mi.

Ẹhn, ṣe wahala ni wọn ni ki n ba ku ni?"

"N ko mọ ohun ti ọmọ mi ṣe, wọn ko ṣalaye kankan fun mi, wọn kan sọ pe ijọba n wa naa ni, n ko si mọ"

Ninu ifọrọwerọ pẹlu baba Adeniyi, BBC News Yoruba beere lọwọ rẹ nipa ọmọ rẹ, Adeniyi Adeyemi ati isẹ to n se.

Baba naa fesi pe awọn ọlọpaa naa beere ibeere ọhun lọwọ ohun, gẹgẹ bi awa naa ti beere.

"Ọdọ ijọba lo ti sọ pe oun n ṣiṣẹ l'Abuja, ko ju bẹẹ lọ.

Wọn beere pe nibo lo ti n ṣiṣẹ, mo sọ pe n ko mọ, ṣugbọn abẹ ijọba lo loun wa.

Ọmọ mi kii ṣe ẹni to laapọn, bẹẹ si ni kii ṣe onijọgbọn eeyan, ṣugbọn mo mọ pe o n ṣiṣẹ l'Abuja, labẹ ijọba si lo sọ pe oun ti n ṣiṣẹ.

Kii ṣe onijọgbọn, kii ba eeyan jẹ lati kekere rẹ, titi to fi de ibi to de lonii.

Ara mi ko da, gbogbo ohun ti mo n gbọ pẹlu rumọọsi ti wọn wa n fun mi, ko dun mọ mi ninu.

Ọmọ kii ṣe onijọgbọn to maa le debi pe a n wa kaakiri.

O jọ mi loju, ko si ye mi di akoko yii gan-an, bi mo ba sọ pe o ye mi, irọ ni mo pa.

"O wa sile ni bi ijẹjọ, ọjọ keji lo si sọ pe oun ti n pada lọ si Abuja"

Adetunji Adeniyi tun si asọ loju rẹ fun BBC News Yoruba pe ọmọ oun wa sile ni ọjọ Isẹgun ọsẹ to kọja, to si pada silu Abuja ni ọjọ keji.

"Nigba to di ni ana, wọn bẹrẹ sii beere lọwọ mi pe bawo ni emi ko ṣe mọ ibi ti ọmọ mi n gbe.

N ko sọ pe mi o mọ ibi to n gbe, Abuja lo n gbe.

Nigba to loun n lọ si ibi iṣẹ, ṣe maa wa sọ pe ko gbọdọ lọ sẹnu iṣẹ rẹ ni?

Oriṣiriṣi ibeere ni wọn beere lọwọ mi, ṣugbọn mo sọ fun wọn pe ohun ti mo mọ ni mo sọ fun un yin yii.

Wọn ni ohun ti awọn ba wa ni pe ọdọ ijọba lawọn ti wa, mo sọ pe n ko sọ pe ọdọ Yoruba ni wọn ti wa, n ko si sọ pe ọdọ ijọba kọ."

Alagba Adeniyi ni ọrọ naa ko ju bẹẹ lọ, tawọn ọlọpaa si ni agọ ọlọpaa ya niyẹn, ti wọn si gbe oun lọ.

Wo kókó ohun méje tí Tinubu sọ, bó ṣe pàṣẹ kí ICPC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí Adeniyi Adeyemi àti ìdásílẹ̀ ayédèrú iléeṣẹ́ ìjọba

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti paṣẹ fun ajọ Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission, ICPC, lati bẹrẹ lori iwadii ayederu ileeṣẹ ijọba Presidential Foreign Intervention Promotion Council atawọn ọrọ mii to rọ mọ ileeṣẹ naa laarin ọgbọn ọjọ pere.

Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga, sọ ninu atẹjade kan pe Aarẹ ni oun gbọdọ gba esi abajade iwadii naa laarin ọgbọn ọjọ ọhun.

Onanuga sọ pe aṣẹ yii waye lẹyin ti aṣiri tu nipa ileeṣẹ ọhun ti Aarẹ sọ pe oun ko mọ nipa rẹ tabi buwọlu lati maa ṣiṣẹ lorukọ oun.

Koko awọn ohun ti ijọba fẹ ṣe iwadii rẹ

  • Atẹjade naa sọ pe Tinubu paṣẹ ki wọn ṣe iwadii iwe igbanisiṣẹ ti adari ajọ ofege naa, Adeniyi Adeyemi Mathew, n lo.
  • Iwadii naa yoo tun tu pẹrẹpẹrẹ bi ọgbẹni Adeniyi Adeyemi Mathew ṣe ri iwe igbanisiṣẹ lati ọọfisi Aarẹ titi to fi di ẹni to n ṣoju ijọba Naijiria niwaju awọn aṣoju ijọba ilẹ okere mii.
  • Ijọba yoo tun ṣewadii bo ṣe n gba fisa lorukọ rẹ, bo ṣe ṣi oniruru apo iṣuna lawọn ile ifowopamọ atawọn nnkan mii.
  • Onanuga tun tẹsiwaju pe Aarẹ fẹ mọ ohun to fun afurasi naa ni igboya atawọn nnkan mii to rọ mọ bo ṣe ri iwe igbanisiṣẹ ijọba apapọ gba lorukọ ijọba.
  • Atẹjade naa sọ pe "Iwadii naa yoo tu aṣiri bo ṣe ri ati bo ṣe n lo ayederu iwe lati ṣoju ijọba; bo ṣe ṣi awọn apo iṣuna ni oniruru ile ifowopamọ, bi owo ṣe n wọ inu awọn apọ iṣuna naa ati ibi ti owo ọhun ti wa, awọn banki to n lo atawọn to jẹ ki iṣẹ rẹ ṣeeṣe."
  • Aarẹ tun paṣẹ ki ICPC ṣewadii awọn kudiẹ-kudiẹ to wa nileeṣe ijọba ti afurasi naa gba wọle ati ọna ti yoo fi di awọn kudiẹ-kudiẹ naa ki irufẹ iṣẹlẹ bẹe ma baa waye mọ lọjọ iwaju.
  • Gẹgẹ bo ṣe sọ, Aarẹ paṣẹ fun gbogbo ileeṣẹ ijọba ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ICPC ninu iwadii naa ki wọn si fun ajọ naa ni ohun to ba bere fun iwadii rẹ.

Ileeṣẹ Aarẹ ni ọrọ naa jẹ eyii to buru jai to si lagbara lati dojuti Aarẹ ati ijọba Naijiria lagbaye.

Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe Onanuga sọ fun akọroyin oun pe iwadii ti wọn ṣe ti fi han pe ayederu ni ibuwọlu olori oṣiṣẹ Aarẹ, Femi Gbajabiamila to wa lori iwe igbnisiṣẹ afurasi to n tukọ ayederu ileeṣẹ ọhun.

Idi ti awọn aṣofin ko fi le da si ọrọ naa

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii lo yẹ ki ile igbimọ aṣofin Naijiria jiroro lori ọrọ ọkunrin naa ati ayederu ileeṣẹ ti wọn ni o da silẹ.

Amọ ijiroro naa ko le waye lẹyin ti wọn ni ẹnikẹni ko kọ iwe ẹbẹ si awọn lori ọrọ ọhun, ati pe ọrọ naa ti wa nile ẹjọ.

Sẹnetọ Yemi Adaramodu to ba awọn akọroyin sọrọ lori ọrọ naa ni lootọ ni ijọba ya owo sọtọ fun ayederu ileeṣẹ naa ninu eto iṣuna ọdun 2026 yii.

Adaramodu sọ pe ọrọ naa ti di ọrọ ti gbogbo araalu n jẹ lẹnu, ẹnikẹni ko si fi ọrọ naa lọ awọn nipa iwe kikọ, o tun ti wa nile ẹjọ, nitori naa ni awọn ko ṣe ni le sọrọ tabi jiroro lori rẹ.

Ọlọ́pàá gbé Baba Adeniyi Adeyemi tíjọba fẹ̀sùn ìdásílẹ̀ ayédèrú iléeṣẹ́ àti àjẹbánu kàn, Gbajabiamila ní òun yóò pe Afurasí náà lẹ́jọ́ N10bn fẹ́sùn ìbanilórúkọ jẹ́

Ọrọ ba ibomi-in yọ fun Ọmọọba Adeniyi Adeyemi, ẹni ti ijọba apapọ Naijiria n fẹsun idasilẹ ayederu ileeṣẹ ati ajebanu kan, pẹlu bi wọn ṣe tun lọ fi ọlọpaa gbe baba rẹ niluu Ogbomoso, lọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Keje ọdun 2026 yii.

Ẹ o ranti pe owo to to N1.3bn ni wọn ni igbimọ Presidential Foreign Intervention Promotion Council ni lati ṣalaye, eyi ti Ọmọọba Adeyemi sọ pe oun ni ọga agba ibẹ.

Adeyemi lo ni oun gbe ileeṣẹ naa kalẹ nilana to gba ọfiisi aarẹ kọja, amọ ti ijọba Naijiria ni awọn ko mọ nipa rẹ.

Ọrọ naa ti de ile ẹjọ giga ilu Abuja, awọn ẹsun bi igbimọpọ huwa to lodi sofin, iwe yiyi ati pipe ara ẹni ni oun ti a ko jẹ ni ijọba apapọ si fi n kan Adeyemi, ti Femi Gbajabiamiala atawọn mẹwaa kan si jẹ ẹlẹrii ijọba ninu ẹjọ naa.

Alaye ree lori bi wọn ṣe mu Baba Adeyemi ati alejo to wa ki i

Nipa bo ṣe di pe ọlọpaa wọle mu Baba Adeyemi laaarọ ọjọ Aje naa, o ṣoju mi koro kan ṣalaye pe:

"Mọto mẹrin ni awọn ọlọpaa gbe wa, wọn wọle awọn obi Ọmọọba Adeyemi Adeniyi to wa lagbegbe Road Safety, niluu Ogbomoso, wọn si gbe baba rẹ ati alejo to wa ki i lọ.

Ẹni naa to jẹ ọkan lara awọn alajọgbele fun Baba Adeyemi, sọ pe awọn ọlọpaa tilẹ halẹ mọ awọn baba yii ki wọn to gbe wọn lọ. O ni wọn ko ṣe wọn jẹjẹ rara.

Bẹẹ lo ni wọn ko gba awọn araale laye lati da si ọrọ naa ti wọn fi gbe awọn baba meji naa lọ.

Bakan naa ni ẹnikan toun naa ko darukọ rẹ, amọ ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, sọ pe:

"Wọn gbe Baba lọ si agọ ọlọpaa Agbomire, pẹlu ẹnikan to wa ki wọn laaarọ.

"Wọn ko gbe Mama Adeniyi lọ ni tiwọn, amọ iṣẹlẹ naa ṣoju mama, o si ti mu jinni-jinni ba wọn bayii."

Ile awọn Baba Adeniyi naa ni iroyin sọ pe o wa ni ojule kẹta , Adeniyi Dynasty, lẹyin ile ẹkọ ẹkọṣẹ ọwọ, loju ọna Road Safety, Ogbomoso niluu Oyo.

Ṣe ofin Naijiria fi aaye gba ki wọn gbe ẹbi ẹni ti wọn fẹsun kan?

Latigba ti iroyin ti jade pe wọn ti fọlọpaa gbe Baba Adeyemi ni ọpọ eeyan ti n beere pe ṣe ofin fi aaye silẹ fun ninawọ gan baba, iya, iyawo, ọmọ tabi ẹbi rẹ kankan ni?

Ọpọ eeyan lo n sọ pe to ba jẹ lori ẹsun ti Adeniyi funra rẹ ti ni oun gba lati jẹjọ ni wọn tun gbe baba rẹ si, pe eyi ko tọna labẹ ofin.

Ninu alaye rẹ to ṣe fun iwe iroyin Punch lori ọrọ yii, Amofin agba lorilẹede Naijiria, Femi Falana (SAN), sọ pe ko si aaye fun ofin lati mu ẹlomiran fun ẹsun ẹnikẹni.

Falana sọ pe: " Wọn ti mu baba naa. Ko si idi kankan labẹ ofin lati mu ẹnikan fun ẹnikeji. Ọkunrin naa ti ṣeleri lati farahan ni kootu, ki ni wọn tun mu baba rẹ fun?"

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn agbẹjọro nilẹẹ Naijiria (NBA) naa koro oju si mimu ti wọn mu Baba Adeyemi.

Aarẹ NBA, Mazi Afam Osigwe (SAN) pẹlu awọn agbejọrọ agba miin nilẹ Naijiria, kilọ pe ofin Naijiria ko faaye gba mimu ẹbi eeyan ki ẹni ti wọn fẹ ba rojọ gan-an le yọju si wọn.

Ohun kan ṣoṣo ti wọn ni ofin fi le fi aaye silẹ lati mu Baba Adeyemi ni ti baba funra rẹ ba jẹ afurasi, tabi ẹni to ni nnkan kan pẹlu ẹsun to wa nilẹ naa.

O fi kun un pe o ye ki kaluku fi idi ododo ọrọ yii mulẹ, ki wọn si mọ idi ti ọlọpaa ṣe gbe baba ti ọmọ rẹ lẹjọ lọdọ ijọba.

Ijọba naa lo si wa nipo alaye bo ṣe wi, lati ṣe fun araalu lori ọrọ yii.

Ikọ ọlọpaa, lati ẹka FCID ni iroyin sọ pe wọn gbe Baba Adeyemi lọ, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i sọ nnkan kan lori rẹ lasiko ti a pari iroyin yii.

Gbajabiamila ni oun le pe Adeyemi lẹjọ koun si beere N10bn fun ẹsun ipaniyan, abẹtẹlẹ

Olori oṣiṣẹ lọfiisi Aarẹ, Femi Gbajabiamila ti ni o ṣee sẹ ki oun gbe igbesẹ ipẹjọ ti yoo la biliọnu mẹwaa naira lọ fun Ọmọọba Adeniyi Adeyemi, nipa bo ṣe ni oun mọ nipa ipaniyan, owo ẹyin atawọn ẹsun iwa ọdaran mi-in.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch to fi iroyin naa lede ṣe wi, lẹta kan ni wọn ni Gbajabiamila kọ lọjọ kẹfa , oṣu Keje ọdun 2026 yii, eyi ti 'Kemi Pinheiro, (SAN), buwọ lu fun olori oṣiṣẹ lọdọ ijọba apapọ naa.

Femi Gbajabiamila kọ lẹta igbẹsẹ naa lẹyin ipade oniroyin kan ti wọn ni Adeyemi pe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa ọdun 2026.

Nibi ipade naa ni iroyin ti sọ pe Adeyemi ni Gbajabiamila beere ipin tirẹ ninu owo ileeṣẹ PFIPC to di ẹjọ bayii.

Ileeṣẹ yii ni ijọba apapọ ni oun ko mọ nipa rẹ, amọ ti Adeyemi sọ pe o ba ofin mu, to si gba ilana to yẹ lọdọ ijọba apapọ kọja.

Nibi ipade oniroyin naa ni iroyin sọ pe Adeyemi ti ni Gbaja gba lara owo to di ẹjọ bo tilẹ jẹ pe oun funra rẹ kọ lo tẹwọ gba a, ṣiṣe aṣilo ọfiisi rẹ ati ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iroyin sọ pe Adeyemi tun ṣapejuwe Gbajabiamila bii apaayan nibi ipade naa.

Ki lo de ti Gbajabiamila fẹ gbe igbesẹ yii?

Awọn ọrọ yii ni Gbajabiamila ni ki Adeyemi ko jẹ, titi kan awọn fidio tabi ohùn ẹnu ti wọn ka silẹ to n ba Gbajabiamila lorukọ jẹ.

Wọn ni ko tọrọ aforiji ninu iwe iroyin marun-un, o kere tan, ko si ṣe bẹẹ lori awọn ẹka ayelujara ti wọn ti pin fọnran ipade oniroyin naa.

Bakan naa ni olori oṣiṣẹ lofiisi Aarẹ n beere pe ki Adeyemi kọwe adehun pe oun ko ni i kọ nnkan kan mọ nipa Gbajabiamila.

Lẹta naa ka ẹsun mẹsan-an to ni Adeyemi fi kan Gbaja, lara eyi ti I ṣe pe Gbajabiamila beere ida mejidinlaadọta (48%)ninu owo ileeṣẹ tijọba apapọ pe ni ayederu yii, to to N12.5bn

Ati pe o tun gba N400m latọwọdọwọ ninu ileeṣẹ naa.

Agbejọrọ fun Gbajabiamila ṣapejuwe awọn ẹsun ti Adeyemi fi kan onibaara rẹ bii irọ gbuu ati ibanilorukọjẹ.

Gbajabiamila funra sọ ninu lẹta naa pe oun ko foju kan Adeyemi ri, debi toun yoo ba a ṣe gbogbo ohun to ka si oun lẹsẹ.

"A fun ọ ni wakati mejilelaadọrin lati ṣe ohun to yẹ bi o ba ti gba lẹta yii

Gẹgẹ bi lẹta naa ṣe wi, wakati mejilelaadọrin ti i ṣe ọjọ mẹta ni Gbajabiamila fun Adeyemi lati ko gbogbo ohun to sọ naa jẹ, ai jẹ bẹẹ, yoo foju ba kootu.

O gbọdọ tọrọ aforiji loju iwe iroyin marun-un ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Owo to to N10bn ni Gbaja yoo beere fun bi wọn ṣe wi,bi Adeyemi ba kuna lati ṣe ohun ti wọn fẹ laaarin ọjọ mẹta.

Bẹẹ ni Adeyemi yoo tun jẹjọ ibanilorukojẹ pẹlu bi wọn ṣe sọ.