"Àgọ́ NYSC ni mo ti ń bọ̀, tí mo fi kò ìjàmbá, n kò le dá jókòó, rìn, sùn, yàgbẹ́ tàbí tọ̀, tí mo bá tún ayé wa, n kò ní sìnrú ìlú mọ́"
Erongba gbogbo eeyan, paapaa lati kekere ni lati kẹkọọ jade ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama, titi to fi de ile-ẹkọ giga fasiti tabi gbogboniṣe.
Eyi to tun ṣe pataki ni lati lọ sinru ilu ti wọn n pe ni agunbanirọ, nitori awọn iriri, ẹkọ ati irin ajo afẹ to wa nibẹ.
Bayii gẹgẹ lo ri fun ọmọbinrin Eniola Amusan, ẹni to jade ile-ẹkọ giga, to si lọ ṣe agunbanirọ rẹ.
Ṣugbọn si iyalẹnu, lasiko to n dunnu pe erongba oun ti n wa si imuṣẹ, ni ọrọ yiwọ lojiji, to si ṣe bẹẹ di ẹni to n jokoo lori aga, ti wọn n gbe e kaakiri.
Eniola ko le da rin, ko le da jokoo, ko le da sun, ko le da yagbẹ, bẹẹ tun ni ko le da tọ funra rẹ.
Awọn nnkan wọnyi lo si maa n ko ironu ba a lojoojumọ, paapaa nigba to ba n ranti awọn afojusun rẹ lati kekere.
Ṣugbọn ṣa o, Eniola Amusan si ni ireti ati igbagbọ wi pe, lọjọ kan, oun yoo dide rin, toun yoo si maa ṣe gbogbo nnkan ti abarapa n ṣe ni irọrun.

"A pọ ti ara wa ko ya, wọn ni ka pada sile wa, igba ti mo n lọ ni ijamba naa ṣẹlẹ, gbogbo eeyan to wa ninu ọkọ lo ku, emi nikan ni mo ye"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ laipẹ yii, Eniola jẹ ko di mimọ pe toun ba tun ile aye wa, tabi bi wọn ba beere pe ṣe oun yoo tun agunbanirọ ọhun ṣe, o ni ala ti ko le ṣẹ mọ ni, nitori pe oun ko tun le yan agunbanirọ mọ.
Eniola sọ pe abamọ kan ṣoṣo toun maa n ko bayii ni eto agunbanirọ toun lọ ṣe, nitori toun ko mọ pe ibi ti yoo pada yọri ree.
"Ni bi ọdun marun-un sẹyin, nigba ti mo n bọ lati ipagọ agunbanirọ, mo ni ijamba ọkọ.
Gbogbo eeyan to wa ninu ọkọ lo ku, emi nikan ni mo ye ninu ijamba ọkọ ọhun. Latigba naa ni mo ti wa bayii, ti mi o ti le rin," Eniọla sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.
O sọ pe "Idi ti mo fi kuro ni ipagọ agunbanirọ, ti mo fi n bọ wa sile ni pe, ni bi ọsẹ meji ta a debẹ, mo bẹrẹ sii ṣe aisan, mo dẹ lọ si ile-itọju kekere ti wọn ṣe fun wa.
"Wọn gun mi ni abẹrẹ, lẹyin igba ti mo gba abẹrẹ yẹn tan, inu bẹrẹ sii lọ mi. Ooyi bẹrẹ sii kọ mi, mo n bi, ara mi n gbona. Mo pada lọ sibẹ.
"Ni ọjọ yẹn, a pọ ti ara wa ko ya. Igba ti a ti pọ yẹn, ko si aaye to to, ko si bẹẹdi fun wa lati sun.
Wọn wa sọ pe gbogbo awa ti ara wa ko ya, pe ka maa pada lọ sibi ti a ti wa, ka maa pada lọ sile. Nitori ẹ ni mo ṣe lọ."
O sọ siwaju pe oju ọna loun wa, ninu ọkọ bọọsi toun lọ wọ, ti ijamba fi ṣẹlẹ. "Igba ti mo n lọ ni ijamba naa ṣẹlẹ."

"Ori ibusun ni UCH ni mo wa fun oṣu mẹta, ijamba naa ti ko ba ọpa ẹyin mi, lati oke ikun mi wa silẹ, n ko ni imọlara rẹ, ti wọn ba fọwọ gba mi, mi o le mọ"
Eniola sọ pe "Oju mi ri mẹwaa, koda to ju mẹwaa lọ."
O sọ pe awọn mẹwaa ni wọn ye, bo tilẹ jẹ pe awọn farapa yannayanna, ṣugbọn to ni awọn mẹta pada ku nile iwosan ti wọn gbe awọn lọ.
"Nigba ti ijamba naa kọkọ ṣẹlẹ ni Ijebu-Ode, awa mẹrin ti a kọkọ ye ninu ijamba naa, wọn gbe wa lọ si ile iwosan ijọba ni Ijebu-Ode.
"Awọn mẹta padanu ẹmi wọn sibẹ, wọn wa ni ki wọn maa gbe emi lọ si ilu Ibadan pada ni UCH."
Bakan naa lo sọ pe odindi oṣu mẹta gbako loun fi wa lori bẹẹdi ile iwosan UCH niluu Ibadan, ko to di pe wọn sọ pe koun maa lọ.
Eniola sọ pe ori bẹẹdi naa loun wa, ti wọn ti ṣalaye oriṣiriṣi ọrọ foun wi pe oun ko nii le fi ẹsẹ mejeeji rin mọ, nitori pe ọpa ẹyin oun ti kan.
Iyẹn nikan kọ, ọmọbinrin naa to ni ọjọ iwaju rere ṣalayi pe eyi to n ba oun lọkan jẹ tun ni pe oun ko tun ni le da yagbe tabi da tọ mọ.
"Ibẹ ni mo wa fun bi oṣu mẹta, nibẹ ni wọn ti sọ ọpọlọpọ nnkan fun mi pe mo ti ni ijamba ọkọ yi o, o dẹ ti koba ọpa ẹyin mi, tori ẹ lo jẹ ki n wa bayii.
"Atigba yẹn lo jẹ pe lati oke ikun mi wa silẹ bayii, mi o ni imọlara ara mi, ti wọn ba fọwọ gba mi bayii, mi o le mọ.

"Mo ti lọ si ile-iwosan to pọ, wọn fẹ gba mi ni, wọn a dẹ tun da apa to pọ si eeyan lara, n ko le jokoo rara tẹlẹ, lẹyin ọsẹ mẹfa si mẹjọ, mo bẹrẹ si jokoo"
Eniola fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe latigba naa loun ko ti ni imọlara kankan mọ.
O ni oun kii mọ bi iyagbẹ tabi itọ ba n gbọn oun, bẹẹ lo fi kun un pe beeyan ba fọwọ kan oun lati iku si isalẹ, oun ko nii mọ.
"Mi o ni imọlara teeyan ba fọwọ kan mi.
Ti mo ba fẹẹ tọ naa, mi o ni imọlara, bi mo ba fẹẹ yagbẹ, mi o ni imọlara, tori ẹ ni mo ṣe n wọ kinni tawọn ọmọde maa n wo lati ma ba a yagbẹ tabi tọ sara.
Mo dẹ tun n lọ nnkan ti awọn oloyinbo n pe ni Catheter, ibẹ ni itọ mi maa n gba jade.
"Lẹyin igba ti wọn da mi silẹ ni UCH, mo ti lọ si awọn oriṣiriṣi ile-iwosan to pọ, to jẹ pe wọn maa parọ wi pe awọn mọ nipa eto ailera ọpa ẹyin, to dẹ jẹ pe irọ patapata ni, lẹyin wi pe wọn fẹẹ gba owo, wọn fẹẹ gba eeyan, wọn a dẹ tun da apa to pọ si eeyan lara.
"Ni akọkọ, nigba ti o bẹrẹ, wọn kọkọ sọ fun mi pe boya mi o tiẹ nile jokoo rara, ṣugbọn lẹyin ọsẹ bii mẹfa si mẹjọ, nnkan yatọ, mo dẹ bẹrẹ si ni jokoo nipa oore ofẹ Ọlọrun.
"Latigba yẹn naa ti mo tun ti kuro nibẹ, mo n ṣe ayẹwo ati idaraya, pẹlu igbagbọ, nnkan bẹrẹ sii yatọ fun mi."

"Mo ni ireti pe mo tun le pada fi ẹsẹ mejeeji mi rin, pẹlu bi mo ṣe pade ọkunrin kan to fun mi ni ireti ati rin"
Ọmọbinrin yii sọ pe oun tun ti ni ireti bayii wi pe o ṣee ṣe ki oun tun pada fi ẹsẹ mejeeji oun rin, pẹlu boun ṣe pade ọkunrin kan to fun oun ni ireti.
Eniola sọ pe laipẹ yii loun pade ẹnikan lori ayelujara, ẹni naa lo sọ pe awọn jọ ni ipenija kan naa, to si ni ọmọkunrin ọhun n gbiyanju lati lọ si ilẹ India fun iṣẹ abẹ ni tiẹ.
"Ni kopẹkopẹ yii, mo pade ọmọkunrin kan lori ikanni ayelujara, to jẹ pe bayii loun naa ṣe wa.
Oun naa n gbiyanju lati lọ si ilu India lati lọ ṣiṣẹ abẹ to maa jẹ ko rin," Agunbanirọ tẹlẹ sọ bẹẹ.
"Oun lo wa ṣe afihan mi fun awọn dokita to wa ni India.
Igba ti emi naa fi aworan mi ranṣẹ si wọn, wọn sọ fun mi pe mo le ṣe iṣẹ abẹ kan to maa jẹ ki n rin, ki nnkan tubọ dara fun mi daadaa, ṣugbọn ẹnikankan ko le sọ ibi ti yoo dara dẹ.
Emi nigbagbọ pe temi ba ṣe e, emi a rin."
"Ẹ̀ru aṣọ agùnbánirọ̀ máa n bà mí"
"Ti wọn ba ni ṣe maa tun tun agunbanirọ ṣe, mi o ni lọ fun agunbanirọ. Agunbanirọ jẹ nnkan to ba mi lọkan jẹ gidi.
"Fun bi ọdun meji lẹyin ti jamba yii ṣẹlẹ, ni mi o fi le wo agunbanirọ kankan. Ti mo ba ri aṣọ agunbanirọ, o maa n ba mi lọkan jẹ, nitori ti mo lero wi pe ti mi o ba lọ fun agunbanirọ, nnkan to ṣe mi yii, ko ba ma ṣe mi," Eniola sọ fun BBC Yoruba.

"Mo nílò ìrànlọ́wọ́"
Nigba to n sọrọ nipa bo ṣe wu oun lati tun fi ẹsẹ mejeeji rin pada, Eniola sọ pe iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu loun nilo bayii.
O ni oun mọ pe irin ajo iṣẹ abẹ lọ si ilu India yoo so eso rere boun ba ri iranlọwọ lati lọ ṣiṣẹ abẹ.
"Nnkan to wu mi ni ki n tun pada fi ẹsẹ mi mejeeji rin, ki aye mi si dara, ki aye mi kuro ninu ipo ti mo wa yii, ko bọ si ipo to dara, ki ohun gbogbo wa ni irọrun fun mi, ki n maa ṣe nnkan ninu irọrun, ko ma si inira fun mi mọ.
"Ni bayii, mo n gbiyanju lati wa owo fun iṣẹ abẹ ti mo fẹ lọ ṣe ni India. Mo nilo iranlọwọ owo, ati iranlọwọ yoowu ti gbogbo eeyan lero wi pe wọn le ṣe fun mi."






