Ìwà tí ọ̀pọ̀ ‘Marketer’ ń hù, kù díẹ̀ káà tó, àwọn òṣèré gbà pé wọ́n gbọdọ́ gbéra sílẹ̀ fún wọn láti dìde - Nike Peller
Gbajumọ osere tiata to tun jẹ agbaọjẹ ni Nike Peller, o si ti le ni ọgbọn ọdun to ti n mi ori afẹfẹ nilẹ Yoruba ati yika Naijiria.
Oniruuru ere tiata, itage ati sinima si ni Nike Peller ti kopa ninu rẹ eyi to sọ di igba oju mọ nilẹ Yoruba.
Yatọ si eyi, ọmọ gbajumọ ọlọwọ idan, Professor Peller to ti di oloogbe tun ni Nike Peller, eyi to mu ko wa laarin awọn osere tiata ti aye n yọnu si.
Amọ o ti to ọjọ mẹta kan ti gbajumọ osere naa ti kopa kẹyin ninu ere tiata, idi ree ti BBC News Yoruba fi wa mama naa kan, lati mọ idi ti wọn se da awọn ololufẹ wọn ni agara bẹẹ.

"Awọn eeyan maa n bẹru lati wa sile wa tabi gba adugbo kọja, wọn yoo ni Professor Peller maa sọ yin di eku, ẹyẹ, ẹja, ti ko si si nnkan ti wọn ko fi ile wa we tan"
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Nike Peller salaye igba kekere rẹ ati ibẹru ti ọpọ eeyan ni lati wọnu ile wọn wa tori pe baba rẹ jẹ Ọlọwọ Idan.
"Nigba ti mo wa ni kekere nile wa ni adugbo Onipaanu, awọn eeyan maa n bẹru lati wa sile wa tabi gba adugbo naa kọja.
Wọn a ni Professor Peller maa sọ yin di eku, ẹyẹ, ẹja, ti ko si si nnkan ti wọn ko fi ile wa we tan.
Ile wa dabi ile ẹru fun ọpọ eeyan nigba yẹn sugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oju ti la, awọn eeyan ti n ri idan pipa, bo se ri, ko si oogun ninu rẹ."
"Ere tiata to gbe orukọ mi sita ni akọle rẹ n jẹ Adun, idi ti n ko fi kopa pupọ ninu ere mọ ni pe wọn ko pe mi, ti wọn ba pe mi, maa yọju"
Nigba to n sọ nipa bo se de ẹnu isẹ tiata, Nike Peller ni ọdun 1985, eyiun ọdun mọkanlelogoji sẹyin ni oun de ẹnu isẹ tiata.
"Ere tiata to kọkọ gbe orukọ mi sita ni akọle rẹ n jẹ Adun, idi ti n ko fi kopa pupọ ninu ere mọ ni pe wọn ko pe mi, ti wọn ba pe mi, maa yọju.
Amọ awọn akoko kan wa to jẹ pe n ko fi bẹẹ si ni Naijiria, awọn isẹ kọọkan naa wa to jẹ pe mo n se, to fi dabi ẹni pe awọn eeyan ko fi ri mi."
Bakan naa, Nike Peller tun mu wa si iranti nipa ọpọ ipenija to n koju awọn obinrin lẹnu isẹ tiata.
"Nigba ti a kọkọ bẹrẹ, ti gbogbo rẹ si n se witiwiti, iwa ti ọpọlọpọ awọn onigbọwọ sinima, ti a n pe ni Marketer, ku diẹ kaa to.
Awọn osere tiata kan si wa to jẹ pe wọn gbagbọ pe tawọn ba fẹ dide, wọn gbọdọ gbe ara silẹ fun awọn Marketer naa.
To ba si jẹ pe nilu oyinbo ni, wọn maa n mọ riri awọn gbajumọ osere, wọn yoo tun fun wọn ni nnkan ni amọ nibi, ẹru maa n ba eeyan lati jade ni.
Se gbogbo wa si la maa gbe ọlọpaa abi awọn ẹsọ alaabo rin kaakiri ni? Rara, tori ti eeyan ba de ibikibi, wọn maa bo eeyan ni, pe awọn gbọdọ jẹ nibẹ.
Emi tiẹ daran tori ẹgbọn mi to wa nile asoju-sofin nigba kan, wọn ro pe gbogbo owo ti wọn n gba nibẹ, emi ni wọn n ko fun."

"Ife lasan ti wọn fi n pa idan, wọn le ra ni $20,000, ẹ wa wo bi owo awọn eroja lorisirisi ti wọn fi n se idan yoo ti pọ to"
Nigba to n se apejuwe iru eeyan ti baba rẹ, Professor Moshood Abiola Folorunso, ti ọpọ eeyan mọ si Professor Peller jẹ, gbajumọ osere naa ni alaanu ati alalubarika ni baba oun.
"Ti eeyan ba n gbadura fun baba Alaanu, alalubarika ati baba oloriire, Professor Peller ni ẹni akọkọ.
To ba jẹ pe wọn si wa nile aye, mo mọ ibi ti maa wa ni sinsin yii, yoo tun ti ju bayi lọ tori wọn kii fẹ ki iya, abuku ati ẹtẹ ta le ẹnikankan."
Nike Peller tẹsiwaju nipa ipo ti idan pipa wa lode oni, to si ni ninu idile awọn, ko si ẹnikankan ti ko mọ nipa isẹ pidanpidan.
"Idan pipa nii se pẹlu idanilaraya, amọ awọn eeyan maa n gbagbọ oogun ni, ti ko si si nnkan to jẹ mọ oogun sise ninu idan pipa.
Ko si pe boya a n lo Ifunpa tabi Igbadi, rara o, ẹnikẹni lo le kọ nipa idan pipa, sugbọn wahala kan soso to kan wa nibẹ ni pe owo ti wọn fi n ra eroja idan pipa ti wọn ju.
Ife lasan ti wọn fi n pa idan, wọn le ra ni ẹgbẹrun lọna ogun Dọla, ẹ wa wo bi owo awọn eroja lorisirisi ti wọn fi n se idan yoo ti pọ to.
Idi ree ti awọn eeyan ko fi le sọ pe awọn fẹ tori bọ idan pipa."






