Owó ìrànwọ́ iná mọ̀nàmọ́ná tí ìjọba fẹ́ẹ́ yọ kúró ní 2027, ohun tí a mọ̀ rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede ipinnu rẹ lati fopin si owo iranwọ ina mọnamọna, bẹrẹ lati ọdun 2027.

Minisita to n ri si ọrọ ina mọnamọna, Joseph Tegbe, lo kede bẹẹ lọjọ Ẹti.

Tegbe ṣalaye pe igbesẹ yii ṣe pataki lati ri i pe ina ọba duro deede fun araalu lati ri lo.

"Mo n ṣeleri fun yin, pe ti Oluwa ba fun wa ni ọdun to n bọ, a maa fopin si owo iranwọ lẹka ina mọnamọna."

Bẹẹ ni minisita fun ina ọba, Joseph Tegbe, wi.

Ṣe eyi tumọ si afikun owo ina ni?

Nigba to n dahun ibeere awọn akọroyin, pe ṣe owo iranwọ tijọba fẹ yọ yii yoo tumọ si alekun owo ina sisan fun araalu, Tegbe ṣalaye pe okunkun ni ijọba fẹ yọ kuro, ki i ṣe pe wọn fẹ mu inira ba awọn eeyan to n lo ina mọnamọna.

O ni ibuwọlu Aarẹ Tinubu lo ku lati san gbese N3.3 trillion lẹka ina ọba, ki wọn ṣi ṣe awọn eto ti ko ni i jẹ ki gbese maa wa lẹka naa lọjọ iwaju.

" Ko si eto ijọba yii kankan to fẹ fi kun owo ina sisan lasiko yii, bi ẹnikẹni ba n sọ fun yin pe a fẹ fi kun owo ina ni, ko ri bẹẹ rara.

"Ẹ sọ fawọn ọmọ Naijiria pe ko sohun to jọ bẹẹ lọwọlọwọ yii."

Minisita ina ọba lo fi kun alaye rẹ bẹẹ.

O ni ohun ti ijọba fẹ ṣe ni ki ina daa si I, ki araalu maa ri I lo deede, ki wọn si ma ṣe sanwo kọja iye ina ti wọn ba lo.

Tegbe ṣalaye pe awọn eeyan kan wa ti wọn ko le sanwo ina ti wọn n lo nitori ai ni, o ni awọn yoo bojuto ọrọ iru wọn.

O fi kun un pe obitibiti gbese to wa lẹka ina mọnamọna lo n fa a ti ina to peye ko ṣe si, to si n dena idasilẹ awọn okoowo.

Atunto to fẹ waye yii ni Tegbe sọ pe yoo ran ẹka ina ọba lọwọ, ti ko si ni i ṣe akoba tabi inira fawọn eeyan Naijiria.