Ìdí rèé tí ìgbéyàwó méjì tí mó ṣe fi foríṣánpọ́n àti bí mi ò ṣe tí ì fé ìyàwó míì- Mr Steeze

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agbaọjẹ oṣiṣẹ banki to di ilumọọka nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun Ojude Oba ni Ijebu Ode, Farooq Oreagba, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Steeze ti ṣalaye idi ti igbeyawo rẹ fi foriṣanpọn.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori eto Nibo Laye Kọju Si?, Oreagba tun ṣalaye idi ti ko ti i fii laya lọọdẹ titi di akoko yii.

Oreagba sọ pe ''ẹmeji ni mo ti fẹ iyawo, iyawo ti mo kọkọ fẹ si ni ọrẹ korikosun mi titi di oni.

Kii ṣe ija, kii ṣe wi pe mo ṣe nnkankan fun un ti o fi lọ, emi funra mi ni mo pinnu pe igbeyawo ko le rọrun fun mi pẹlu igbe aye ti mo n gbe.

Mi o fẹ ki obinrin kan maa reti mi nigba ti mo ba rinrin ajo tabi ki obinrin maa ṣọ mi.

Amọ, ti Ọlọrun ba dẹ ṣe e ti mo ba ri obinrin ti ọrọ mi ye, ko si iyọnu.''

Ọgbẹni Oreagba ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe oun naa ni toun lọwọ gẹgẹ bi eeyan, o ni ''oṣiṣẹ banki meloo ni ẹ mọ to ya tattoo sara?

Oṣiṣẹ banki meloo ni ẹ mọ to n wọ yẹti bi obinrin, ko si oṣiṣẹ banki kankan to n wọ yeti ni Naijiria.''

Mr Steeze sọ pe bi Ọlọrun ṣe da oun ko ṣee yi pada, Oreagba ni oun ko le yi iwa oun pada tori obinrin tori inu oun ko ni i dun mọ toun ba ṣe bẹẹ.

Ọgbẹni Oreagba ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe oun kii ba obinrin sun kiri, bo tilẹ jẹ pe oun ko ni iyawo nile.