You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ nípa ìrẹsì tó léwu fún ìlera rẹ tí àjọ NAFDAC ń kìlọ̀ rẹ̀
Ajọ to n ri si ohun jijẹ ati oogun lilo lorilẹede Naijiria (NAFDAC) ti kilọ fun araalu lati ṣọra fun oriṣi irẹsi kan ti ijọba ilẹ Olominira Niger ti fofin de, amọ ti wọn lo ṣee ṣe ko ti wọ awọn apa ilẹ Africa mi-in.
Awọn ohun to lewu gidi fun ara (metallic contamination) lo wa ninu irẹsi naa lẹyin tawọn oluwadii ṣiṣẹ lori rẹ bi NAFDAC ṣe sọ.
Ẹka to n ri si okoowo ni Niger lo ta wa lolobo nipa irẹsi Bulmex -NAFDAC
Ninu ikede kan ti ajọ NAFDAC fi lede ni wọn ti ṣalaye pe orukọ irẹsi to lewu fun jijẹ naa ni Bulmex.
Wọn fi kun un pe ajọ to n ri si okoowo lorilẹede Niger lo fi to NAFDAC leti pe awọn ti fofin de irẹsi to n wa lati India naa lọdọ awọn.
Gẹgẹ bi NAFDAC ṣe wi, ẹka ileeṣẹ kan; Agadez Regional Directorate of Commerce and Industry, lo ri awọn irin idọti ninu irẹsi naa, ti wọn si ri i pe o lewu fun eeyan lati jẹ.
"Iwadii naa fi han pe wọn ri awọn irin aloku ati idọti irin ninu irẹsi naa, eyi to mu ko lewu fun jijẹ.
"Lati dena wahala, kiko irẹsi naa wọle tabi pinpin kiri rẹ ti di eewọ."
Bẹẹ ni ajọ naa wi.
Awọn wo ni wọn n ta irẹsi Bulmex?
Gẹgẹ bi ajọ NAFDAC ṣe ṣalaye, wọn n ta irẹsi Bulmex gẹgẹ bii eya irẹsi to wa lati India, ati bii onigigun ṣọọrọ to n wa lati Pakistan.
Awọn alagbata rẹ gboogi bi wọn ṣe kede ni: Karam Food Grains Private Limited, Paragon Commodities Limited ati Imoro Brunya/Sulemana Imoro Distribution Company.
Ajọ NAFDAC sọ pe oun gbọ pe wọn ti n ko irẹsi naa wọle kaakiri Africa, paapaa ni Naijiria ati orilẹede Niger.
Amọ ajọ yii sọ pe oun ko ti I fidi rẹ mulẹ boya wọn ti n ta irẹsi naa kaakiri awọn ọja ni Naijiria.
"O ṣe pataki lati mọ pe a ko ti i le fidi ẹ mulẹ boya irẹsi Bulmex ti wa lọja Naijiria.
"NAFDAC n kede silẹ lati fimu finlẹ nipa rẹ, ka si ri i pe ko wọ awọn ọja Naijiria lati awọn ẹnu ibode kiri."
Bẹẹ ni ajọ NAFDAC kede.
"A ti da awọn oṣiṣẹ wa sita lati gbẹsẹ le irẹsi yii bi wọn ba ri i nibikibi ni Naijiria"
Lati dena irẹsi Bulmex ko ma wọ Naijiria, NAFDAC sọ pe oun ti paṣẹ fawọn adari kaakiri ipinlẹ lati fi kun bi wọn ṣe n tọpinpin awọn ọja.
O ni ki wọn gbẹsẹ le irẹsi Bulmex lẹsẹkẹsẹ nibikibi ti wọn ba ti kofiri rẹ ni Naijiria.
"A maa tẹsiwaju lati maa ṣewadii rẹ bo ṣe n lọ, bẹẹ la o si maa mu àbọ̀ wa lori rẹ."
NAFDAC wa rọ awọn alagbata irẹsi, awọn alaratunta atawọn to n ta a ni iwọn kereje pẹlu awọn to n ra a jẹ lati ṣọra.
Wọn ni ki wọn farabalẹ wo irẹsi ti wọn ba fẹ ra, ki wọn wo bo ṣe jẹ ojulowo si ati bo ṣe daa to loju ki wọn too ra a tabi pin in kiri.
Bi araalu ba wa ri irẹsi eyikeyi ti wọn fura si pe ko daa to tabi to jẹ ayederu, NAFDAC ni ki wọn fi to ẹka oun to ba wa nitosi leti.