You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìgbéyàwó àti Ọmọ bíbí kò dá ilé ẹ̀kọ́ mi dúró - Akẹ́kọ̀ọ́ tó yege jùlọ ní FUNAAB
Ṣise igbeyawo ati bibi ọmọ ko da Arabinrin Tijani Oluwatoyin duro lati yege gẹgẹ bi akẹkọọ to yeye julọ ni Fasiti to n kọ nipa Ọgbin niluu Abeokuta, FUNAAB.
Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣe abẹwo si Akẹkọọ naa, ọkọ rẹ ati ọga ile ẹkọ lati mọ nipa irinajo rẹ ati awọn oun to la kọja ninu irinajo rẹ.
Tijani ni oun ko ni lero pe oun le jẹ akẹkọọ to yege julọ ni Fasiti naa nitori oun kan n ṣe nnkan ti oun mọ ṣe ni.
“Ti wọn ba sọ pe ma le tete kilasi mi, ma ni rara nitori oun ko lero rẹ rara fun iṣeju kan pe emi .
“Titi mo fi pari idanwo, ko wa si mi lọọkan rara.
“Mo ṣe igbayawo ninu oṣu kejila ọdun 2020, mo dẹ bi ọmọ ni oṣu karun un 2021, igba yẹn ni ipele kẹta
'Asiko Covid 19 ṣe iranlọwọ fun mi lẹyin ti mo bimọ'
Tijani ni oun jẹ anfani igbagba ẹkọ lori ayelujara to gbode lasiko Covid 19 nitori ọpọ igba ni oun ko ki lọ si ile ẹko, ti oun yo si tun ma gba ẹkọ lọ.
“Ẹkọ ta gba ori ayelujara ni a ti ṣe, ṣugbọn mo wa ni agbegbe ile-ẹkọ, mo kuro ni ile mo wa si ile-ẹkọ, mo tun le so pe ninu oyun, bi awọn ẹkọ maa ṣe wa lori ayelujara, o tun jẹ ko rọ mi lọrun diẹ, ṣugbọn gbogbo kikawe ni, mi o tori pe mo wa ninu oyun kii n ma ṣe nnkan to yẹ ki n ṣe.”
Ẹni to ba fẹ akẹkọọ mọ pe oun gbọdọ ṣe suuru to to suuru- Ọkọ OluwaToyin
Oguntola Olanrewaju to jẹ ọkọ ati baba ọmọ fun Oluwatọyin ni inu oun dun si ilọsiwaju iyawo oun nitori lati ilẹ ni oun ti mọ pe ori iyawo oun ji pepe.
“Latilẹ ni mo ti mọ pe ọmọ ti ori rẹ ji pepe ni latilẹ, ṣugbọn debi pe, o di akẹkọ to yege julọ ninu fasiti, o jẹ nnkan iwuri pupọ fun mi,
“Nnkan to tun wa jẹ ko dun mọ mi ninu ju ni wi pe, o jẹ ẹni to ti ni ọkọ, kii n ṣe iyẹn nikan o, o si tun ti bimọ.”
Bakan naa lo ni oun ti gbaradi pe oun ni lati ṣe ọpọlọpọ suuru nitori akẹkọọ ni oun fẹ
“Mo ti mọ pe emi ti mo fẹ ẹni to wa mi ile-ẹkọ mo gbọdọ ni suuru to to suuru, nnkan yo ma fa ede ayede laaarin wa ni igba yẹn,
“Ti mo ba ṣi ranti ni pe; ti o ba wa ni ile ẹkọ bi oṣu kan, meji, mẹta, ka ma rira, ki n ma ri aye yọju si.”
O ni akitiyan, o ni afojusi, ni koko ko kii n fi ọrọ ẹkọ ṣere- AkỌwe Agba FUNAAB
Akọwe agba FUNNAB, Bola Adekola ni Tijani ko mọ pe oun lo oun yege ju nitori o kan gba maaki lọ lia mọ.
Adakola wa kan sara si Akẹkọọ bi ko ṣe jẹ ki igbeyawo ati bibi ọmọ ṣe ida duro fun un ninu irinajo ẹkọ rẹ.
“Oun kawe tiẹ lọ ni, o n gba marki tiẹ lọ ni, awa la ṣe sọ fun pe oun lo yanranti ju ni fasiti, kii n ṣe pe boya o n le pe k'oun yanranti ni fasiti, kii n ṣe ọmọ ile olowo, ẹ jẹ ki n kuku laamọlẹ bẹ pe kii ṣe ọmọ olowo, ta ma fi sọ wi pe, tori owo ti Baba ẹ ni, ohun lo jẹ ki oun le kawe, ko yanranti bẹẹ, ti ẹ ba gbọ apilẹsọ ọrọ to ao ni ijọ yẹn naa, Baba ẹ gan ti ku, ko to di pe o jade ile-ẹkọ yii.
“Lara awọn nnkan to mu ṣe daadaa, oni igba toun bimọ tan, toun wa ni ile-ẹkọ, iya oun wa joko t'ọmọ, la ti le ma ba oun tọ ọmọ yẹn koun le raaye gbajumọ ẹkọ oun daadaa, ko dẹ ṣe alaiṣetan ni igba ti awọn to ku ẹ ṣetan o.”