Obìnrin 550 ti pé Uber lẹ́jọ́ tórí Ìfipàbanilópọ̀ inú ọkọ̀ àti ìjínigbé

Àwòrán ile ise Uber

Oríṣun àwòrán, others

Published

Ile isẹ Uber ti ko sọwọ ofin gẹgẹ bi awọn obinrin aadọtalelẹẹdẹgbẹta ti pe e lẹjọ latari bi wọn ṣe fi ẹsun ifipabanilopọ, ijinigbe ati awọn ẹsun ọdaran miiran kan awọn awakọ wọn lorilẹde Amẹrika.

Iwe ẹjọ naa lo kun fun ọpọlọpọ iriri awọn obinrin ti awọn awako ‘Uber’ ṣe ni ijamba bii ijinigbe, ifitipa banisun ati awọn iwa ọdaran.

Ile ẹjọ San Francisco County Superior Court ti tewọ gba iwe ẹjọ naa lọjọru ọse yii.

“Fifi ilọkulọ ibanilọpọ lọ ni jẹ ohun buruku ati ẹsun nla ti a si mu ni ọkunkundun.” Agbẹnusọ Uber sọ fun BBC.

“Ko si nkan ti o jẹ wa logun ju alaafia awọn to wọ Uber lọ, idi ti a fi ṣe awọn akanse ọfin niyi sugbọn a ko lẹ so nkankan nipa ẹsun naa bayi, a tun gbọdọ mu abo awọn onibara wa ni ọkunkundun.”

Awọn olupẹjọ ti awọn agbejoro lati Slater Slater Schulman ṣoju fun ninu iwe ti wọn gbe wa si ile ẹjọ sọ pe awọn iṣẹlẹ yii waye ni ọpọlọpọ ipinlẹ lorilẹde naa.

Iwe ọhun tun ni o to aadọjọ irufẹ iṣẹlẹ naa ti iwadi si n lọ lori wọn lọwọ.

Adam Slater, ọkan lara awọn oludasilẹ Slater Slater Schulman, ni lati ọdun 2014 ni ile isẹ Uber ti mọ pe awọ awako wọn ṣe awọn iwa ibajẹ ṣugbọn wọn ko lati ṣe ohun to tọ nitori owo ti wọn ri jọ wọn loju ju ẹmi awọn eeyan lọ.

“Ile isẹ Uber ni gbogbo wa ni igbagbo pe nkan ti o ba julọ ni abo awọn onibara wọn sugbọn o yawa lẹnu pe wọn ni awọn onibara wọn lọkan nitori owo ti wọn ri nibi isẹ naa.”