Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn mú ọjọ́ tí yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ìbò gómìnà Kano

Published

Ileẹjọ kotẹmilọrun to n joko niluu Abuja ti mu ọjọ ti yoo gbe idajọ kalẹlori ibo gomina ipinlẹ Kano.

Saaju ni igbimọ ẹlẹni mẹta eyi Adajọ Akintan Osadebay lewaju wọgile ibo to gbe Gomina Abba Kabir Yusuf ni ileẹjọ to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina ni ogunjọ oṣu kẹsan an ọdun 2023.

Ileẹjọ Triunal ni ibo 165,663 ti Yusuf ni lo jẹ ayederu nitori osisẹ ajọ eleto idibo INEC ko buwọlu iwe ibo naa.

Nigba ton farahan ni ile ẹjọ kotẹmilọrun, Agbẹjọro Wole Olanipekun ni ki ileẹjọ wọgile idajọ ileẹjọ kotẹmilọrun.

O ni igba akọkọ re ti ileẹjọ yoo gbe idajọ kalẹ nitori wọn buwọlu iwe ibo.

Bakan naa ni Olanipekun ni igba akọkọ rẹ ti ẹgbẹ oṣelu yoo pe ẹjọ lia fọwọsowọpọ pẹ;pu oludije rẹ.

Ajọ eleto idibo INEC kede Yusuf to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu NNPP gẹgẹ ni oludije to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Kano loṣu Kẹta pẹlu ibo 1,019,602 nigba ti ajọ naa ni ibo 890,705 ni Gawuna ni ninu ibo ọhun.

Bakan naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tun gba iwe ẹri moyege ti ajọ INEC fun gomina Yusuf lẹyin to kede rẹ gẹgẹ bi oludije to wọle ibo gomina ipinlẹ Kano.

Lẹyin naa ti igbimọ olugbẹjọ ẹlẹni mẹta paṣẹ pe ki Gawuna gba ẹri moyege naa.

Ilẹ ẹjọ naa yọ ibo 165,663 kuro ninu gbogbo ibo ti Yusuf pẹlu alaye wi pe ko si ontẹ tabi ibuwọlu lori awọn ibo naa.

Gbogbo ẹsun mẹtẹẹta ti APC fi kan NNPP lori eto idibo ọjọ kọkanla oṣu Kẹta ni igbimọ igbẹjọ naa da APC lare lori wọn.