Ọba Ghandi Soun Ogbomoso, ẹ má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí mo bá ṣẹ̀ yín - Ìmáàmù Àgbà bẹ̀bẹ̀

Oríṣun àwòrán, Imaamu Agba Ogbomoso/Facebook, Oba Ghandi Afolabi Olaoye/faceook
Lẹyin ifanya to ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumọgẹgẹ Kẹta ati Imaamu agba ilu naa, Sheikh Teliat Yunus Ayilara, imaamu naa ti n bẹbẹ bayii wi pe ki kabiyesi fiye denu darijin oun.
Nigba to n sọrọ ninu fọnran kan to fi lede loju opo Facebook rẹ, Imaamu Ayilara ni ''a bẹ baba pe ki wọn ma binu gbogbo ohun ti a ba ṣe si wọn gẹgẹ bi ọmọ.
Ọrọ ẹnu ni, irin ẹsẹ ni, ihuwasi ni, ki wọn ma binu tori ti Ọlọrun, ki Eledumare maa tubọ tọ wọn sọna.
Baba kabiyesi Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, ẹ ma binu tori Ọlọrun, ẹyin agbalagba lo sọ pe bi ẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi, ko ni pẹ lori ikunlẹ.
Awọn agbalagba naa lo tun sọ pe ti a ba fi ọwọ ọtun bọmọ wi, a si fi ti osi fa a mọra, ẹ fa wa mọra kabiyesi.''
- Oriyomi padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tí iléẹjọ́ gba béèlì rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ohun tó sọ rèé
- Soun Ogbomosho: Ka nípa Sòún Ogbomosho to kọ owó #100 mílíọ̀nù tí ìjọba Makinde ní kó fí tún ààfin ṣé
- Ẹgbẹ́ àwọn Ìmáàmù Ogbomoso dá sí ìfaǹfà àárín Ìmáàmù àgbà àti Soun, ọ̀rọ̀ bá ibòmíràn yọ
- Lórí ọ̀rọ̀ Ìmáàmù Ogbomosho, àwọn kan ń yarí pé àwọn alágbara ló gbé e sípò, kìí ṣe ọmọ ìdílé t'óyè tọ́ sí
Baba kabiyesi, ẹ yọnu si wa - Sheikh Ayilara
Imaamu Ayilara rọ kabiyesi lati fa oun mọra tori oun nifẹ Soun Ogbomoso.
O wa rọ kabiyesi lati lati ba oun wi ti oun ba ṣẹ ori ade naa lọna kọna, '' ẹ bu wa, ẹ ki ipọri iya wa fun wa, ẹ darijin wa ẹ ni ki a ma ṣe bẹẹ mọ.
Baba kabiyesi, ẹ yọnu si wa, ti ẹ ba yọnu si wa, awọn eeyan yoo dẹkun ariwo wa ti wọn n pa kaakiri ori itakun ayelujara lojoojumọ.''
Sheikh Teliat ni ohunkohun ti musulumi kankan ba le ṣe fun kabiyesi wi pe ki Ọba Ghandi darijin wọn.
Imaamu agba Ogbomoso gbadura ninu fidio to fi lede loju opo Facebook rẹ pe Eledua yoo fun gbogbo eeyan niluu Ogbomoso ni isinmi wi pe ki kabiyesi fiye denu.
Sheikh Ayilara sọ ni bi oun atawọn eeyan oun ṣe n pẹ lori ikunlẹ jẹ ẹdun ọkan foun.
O tun sọ ninu fọnran naa pe lati igba ti kabiyesi ti rinrin ajo lọ si oke okun loun ti n bẹbẹ eyi ti oun si tun tẹsiwaju pẹlu rẹ nigba ti kabiyesi tajo de.
Imaamu agba ni o da oun loju pe kabiyesi yoo maa gbọ ninu aafin bi oun sẹ n bẹbẹ lati inu mọṣalaaṣi Oja-igbo bi oun ṣe n bẹbẹ.
Shiekh Ayilara fidi rẹ mulẹ ninu fidio tl fi soju opo Facebook rẹ pe o ti di Jimọh meje toun ti n bẹ kabiyesi bayii.
O wa sọ pe o da oun loju wi pe Ọba Ghandi ti gbọ ẹbẹ oun, wọn si gba bakan naa.
Imaamu agba Ogbomoso sọ pe oun atawọn musulumi mii yoo lọ si aafin laipẹ lati bẹ kabiyesi daadaa.
Sheikh Ayilara ni Ọba Ghandi fẹran oun gan an tẹlẹ ko to di wi pe aawọ bẹ silẹ laarin awọn, amọ, o gbagbọ pe ko ni pẹ mọ ti aawọ naa yoo fi pari pẹlu bi oun ti n bẹ kabiyesi.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Aawọ laarin Soun Ogbomoso ati Imaamu Agba Ayilara

Oríṣun àwòrán, Soun palace
Wahala aarin Ṣọun Ogbomọṣọ ati Immamu agba Sheikh Ayilara bẹrẹ nigba ti imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun Ogbomọṣọ lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.
Soun ana lo fi Ayilara jẹ oye Imaamu agba lọdun 2021 ko to waja, eyi ti Imaamu agba naa si n sọ wi pe iyansipo oun ba ilakalẹ gbogbo ilana mu ni ibamu pẹlu ẹsin Islam, ti igbimọ onimimọ nipa ẹsin ni ilu Ogbomọṣọ si fọwọ si i.
Amọṣa ọrọ mii suyọ nigba ti Ọba Afọlabi Ghandi Ọlaoye jẹ gẹgẹ bii Ṣọun tuntun ni ilu Ogbomọṣọ lọdun 2023, to si fariga pẹlu bi Ayilara ṣi ṣe n di ipo mu gẹgẹ bii Imaamu agba ilu naa.
Ẹgbẹ awọn Imaamu Ogbomoso da si ifanfa aarin Imaamu agba ati Soun, ọrọ ba ibomiran yọ
Awuyewuye to n waye laaarin Soun ilu Ogbomoso ati Imaamu agba ilu naa tun ti gba ọna miiran yọ bi igbimọ awọn Alfa ilu naa se ti da si bayii.
Igbimo ẹgbẹ awọn Imaamu ati Alfa ti ilu Ogbomoso ti bu ẹnu atẹ lu ifanfa to n waye laaarin Imam agba ilu ọhun Alhaji Toliat Yusuf Ayilara ati Oba ilu naa, Oba Ghandi Olaoye.
Ẹgbẹ awọn Alfa ati Imaamu Ilu Ogbomoso labẹ isakoso Aarẹ musulumi ilẹ Ogbomoso, AbdulGaniyu Owodunni ninu ifọrọwerọ tí ẹgbẹ naa ṣe pẹlu awọn oniroyin ni gbagede Reacreation Club, lo ti ni, iwa ti Imaamu agba ilu Ogbomoso n hu mu ki aisọkan wa laarin awọn Musulumi ilu Ogbomoso.
Ninu ọrọ apilẹkọ ti Aarẹ musulumi ilu Ogbomoso ka lo ti ran Imam Toliat Yusuf leti wí pe ṣaaju ko to gba lawani gẹgẹ bi Imam agba ilu Ogbomosho ni awọn ẹbi Ayilara ti ń fapa janu wi pe kii ṣe ọmọ ile awọn, nitori naa ipo naa ko tọ si.
Ọba Ghandi Soun Ogbomoso yan Imaamu Agba tuntun fun Aafin

Oríṣun àwòrán, Soun palace
Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumogege 111, Soun ilẹ Ogbomoso yan Habib Ahmed Adekunle Ayilara gẹgẹ bi Imaamu tuntun fun aafin Soun Ogbomoso.
Ọba Olaoye sọrọ yii ninu atẹjade kan ti o fi sita ni ọjọ Ẹti.
Sheikh Habib Ayilara yii ni ẹbi Ayilara fọwọ si tẹlẹ wi pe ki o jẹ Imaamu Agba ilu Ogbomoso.
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi naa ṣalaye pe aafin nilo Imaamu ti ko ni maa dari irun laafin nikan.
Ọpọ musulumi lo wa ni aafin Soun nibi ti wọn ti we lawani fun Imaamu Ayilara ọhun to fi mọ Parakoyi Ogbomoso, Alhaji Sirajudeen Aleem, Sẹnẹtọ Fatai Buhari ti Alhaji Yekinni Woleola ṣoju rẹ atawọn olori ẹsin mii l'Ogbomoso.
Parakoyi ilu Ogbomoso ko ṣai fidi rẹ pe aafin Soun ni Imaamu yii wa fun, o ni Imaamu Agba ilu Ogbomoso, Sheikh Teliat Yunus Olusina Ayilara ṣi wa ni ipo rẹ.
O ni ẹjọ to wa lori ipo rẹ si wa nile ẹjọ lọwọ yii.
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi naa ṣalaye pe aafin nilo Imaamu ti ko ni maa dari irun laafin nikan.
Ọba Ghandi ni aafin Soun nilo Imaamu ti yoo maa ṣoju oun ninu gbogbo eto tawọn musulumi ba n ṣe yala niluu Ogbomoso tabi nibi miran.
''Mo gbagbọ ibagbepọ oniruusu ẹsin lo le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilu Ogbomoso.
Mi o si ni kaarẹ nipa gbigbaruku ti iṣọkan ilu Ogbomoso fun anfani gbogbo araalu,'' Ọba Olaoye lo sọ bẹẹ.
Idi ti Soun fi yan Imaamu tuntun fun aafin Ogbomoso
Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Oloye Orumogege III ti yan Habib Ahmed Adekunle gẹgẹ bii Imaamu tuntun fun aafin Soun ti ilẹ Ogbomoso.
Eto yii lo waye lẹyin ti awọn Musulumi ilu naa pejọ lati ṣe akanse eto adura fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹtalelọgọta Ọba ohun.
Nibi ayẹyẹ naa ni Soun ti kede pe Imaamu aafin tuntun naa ni yoo maa ṣoju aafin oun ninu gbogbo ipade to nii ṣe pẹlu awọn Musulumi ilu Ogbomoso ati aafin.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni wahala kan ti kọkọ waye laarin Ṣọun ati Imaamu agba Sheikh Toliat Ayilara.
Asiko naa ni imaamu agba naa pe Ṣọun ati igbimọ Ṣọun lẹjọ lori igbesẹ to ni pe wọn n gbe lati yọ oun nipo.
Ninu oṣu keje ọdun yii ni kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ayodele Sonubi pe ipade alafia laarin, kabiyesi ati Sheikh Taliat Ayilara, ẹni ti o jẹ imaamu ilu naa.
Ninu ifọrọwerọ BBC Yoruba pẹlu aṣoju aafin lori igbese yii, oloye agba Samuel Otolorin, to jẹ Aarẹ Ago ti ilẹ Ogbomoso ni Soun ko se aṣiṣe pẹlu yiyan imaamu aafin tuntun.
Aarẹ Ago fun ilu Ogbomoso ni lati igba ti Sheikh Toliat Ayilara ti gbe Ọba Ghandi Afolabi Oloye lọ si ile ẹjọ, ni o ti tẹti ninu awọn ojuṣe rẹ si aafin.
Paapaa julọ, o ni Imaamu agba naa ko wa si aafin mọ lati maa lewaju adura fun Soun ni gbogbo ọjọ Jimoh ṣaaju ki wọn to kirun Jimoh ni mọṣalaṣi apapọ Ogbomoso.
Oloye Aarẹ ago ni "ireti ni pe nigba ti Sheikh Toliat Yusuf ti lọ si ile ẹjọ ati wi pe boya yoo ronu piwada funra ara rẹ yoo mu awọn ẹsun ile ẹjọ kuro.
Lẹyin oṣu mẹfa ni kabiyesi wa wo wi pe o yẹ ki awọn ni imaamu ti yoo maa ṣoju aafin, nitori idi eyi ni wọn fi yan imaamu aafin, ipo naa si yatọ si oye Imamu agba.


























