Kí ló fa ikú pásítọ̀ ìjọ Celestial kan àti ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jà tán? Àlàyé rèé

Abidemi Odukoya ati iyawo rẹ, Adenike Odukoya wọ asọ olusọ fun ijọ Cele

Oríṣun àwòrán, CCCNews24/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

L'Ọjọru, ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fidi rẹ mulẹ pe pasitọ ijọ Sẹlẹ kan, Abidemi Odukoya ati iyawo rẹ, Adenike Odukoya ti ku sinu ile, lẹyin ti wọn jọ ni faakaja tan laaarin ara wọn.

Igbakeji agbẹnusọ ọlọpaa, Opeyemi Oluborode lo fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin, to si lawọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa iku tọkọ-taya ọhun.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ, lati mọ kulẹkulẹ bi ọrọ naa ati iku wọn ṣe jẹ," Oluborode sọ bẹẹ.

Abidemi Odukoya ni olori ijọ Sẹlẹ ti CCC, ẹka ti Iri Orun to wa lagbegbe Akinode-Ibogun, ijọba ibilẹ Ifo nipinlẹ Ogun, nigba ti iyawo rẹ jẹ Iya Yaadi.

Nnkan bi agogo mẹta oru ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, osu Kẹjọ, ọdun 2026 ni wọn sọ pe wahala bẹ silẹ laaarin Odukoya ati iyawo rẹ, Adenike ninu ile ti wọn n gbe.

Nibi ti wọn ti n fa wahala naa la gbọ pe awọn mejeeji ti bẹrẹ sii lu ara wọn, to fi di pe Adenike ṣubu lulẹ, to si daku, lẹyin to ti fi ori farapa.

Nigba ti Odukoya rii pe iyawo rẹ ti daku, ko si dahun ni gbogbo bo ṣe n gbiyanju lati gbe e dide, lo mu ko ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ki ọwọ ma ba a tẹ ẹ.

Gẹgẹ bi iroyin Punch se se iwadii rẹ, ọkan lara awọn ọmọkunrin ti awọn mejeeji bi ni wọn lo sare lọ pe awọn ara adugbo lati wa wo ohun to ṣẹlẹ, ti wọn si loju ẹsẹ ni awọn eeyan ti debẹ.

Gbogbo igbiyanju awọn ara adugbo naa lati ra ẹmi Adenike pada saye lo ja si pabo, leyi to jẹ ki wọn mọ pe ẹpa ko boro mọ.

Nibi ti wọn ti n kẹdun iku Adenike lọwọ, ni wọn lawọn kan tun tis are wọle pe awọn ri oku ọkunrin kan lẹgbẹ opopona ni adugbo Iyana-Coker to wa loju ọna Ekoo si Abẹokuta.

Igba ti awọn eeyan yoo fi sare debẹ lati mọ iru ẹni ti oku naa jẹ, lo jẹ kayeefi pe Ajihinrere Odukoya to sa kuro nile ni.

"Odukọya mọ̀-ọ́n-mọ̀ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ ni"

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe Odukoya mọ-ọn-mọ gba ẹmi ara rẹ ni, pẹlu bo ṣe sare lọ ko sẹnu ọkan lara awọn ọkọ to n kọja lọ.

Pupọ ninu awọn to wa nibẹ lasiko naa sọ pe kani awọn mọ pe ọkunrin naa fẹẹ gbẹmi ara rẹ ni, wọn ko ba ti da a duro.

Wọn ni ojiji ni Odukoya sare ko sẹnu ọkọ to n bọ naa, tiyẹn si gba a danu.

Wọn lawọn ọlọpaa lo pada gbe oku Odukoya kuro lọna ni nnkan bi agogo meji ọsan ọjọ naa.

Awọn alakoso ijọ ti Odukoya n dari rẹ naa, la gbọ pe wọn sinku Adenike si ẹgbẹ ile wọn ni nnkan bi agogo meji ọsan ọjọ naa.

To si jẹ pe irọlẹ ọjọ naa ni wọn lọ gba oku Odukoya kuro ni mọṣuari ile iwosan ijọba to wa ni Ifo, ko to di pe wọn sinku rẹ.

"A rí òku Adenike nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaga agbegbe naa tẹlẹ, Ọgbẹni Adejimi Olawunmi, nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, sọ pe ariwo ole loun n gbọ ni nnkan bi agogo kan oru ọjọ naa, ko to di pe ouns are jade lati lọ pe awọn eeyan.

Olawunmi sọ pe nigba tawọn yoo fi jade, lo di pe ọkan lara awọn ọmọ oloogbe ni awọn ri, to si sọ pe awọn obi oun lo n ja ninu ile.

O nigba tawọn yoo fi debẹ, awọn tib a Adenike ninu agbara ẹjẹ lori bẹẹdi, to si jẹ iyalẹnu fun wọn.

"Ko tii ku tan nigba yẹn, o ṣi n pokaka iku lọwọ ni. A gbiyanju lati wa ọkọ tabi ọkada, ka le sare gbe e lọ sile iwosan, ṣugbọn gbogbo awọn ti a lọ ba ni wọn ko gbe ọkọ walẹ," Olawunmi ṣalaye.

O tẹsiwaju pe, "Ọmọ wọn sọ pe inu yara miran loun sun, toun fi n gbọ ariwo lojiji. Idi ree ti a fi sare lọ si agọ ọlọpaa lati fi to awọn agbofinro leti. Igba ti a maa fi pada sile naa, a rii pe Iya Yaadi ti dakẹ."

Bakan naa lo sọ pe lẹyin naa lawọn bẹrẹ sii wa oluṣọ aguntan wọn kaakiri inu igbo ati awọn agbegbe lati wa, ṣugbọn to ni oloogbe naa jana mọ ọkọ lẹnu.

"Ibi ti a ti n wa a kaakiri, lawọn kan tis are w ani nnkan bi agogo meje aarọ wi pe Odukoya ti jana mọ ọkọ lẹnu, o si tik u. Igba ti a maa fi debẹ, wọn ti gbe e lọ si mọṣuari, ibẹ la si ti rii daju pe oun ni," Olawunmi fidi rẹ mulẹ.

"A jọ ṣe ìkórè ìjọ ni"

Ọkan lara awọn ajihinrere ijọ naa, Ogido sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun wọn pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, nitori pe awọn ṣẹṣẹ pari ikore ninu ijọ naa ni.

"O ya wa lẹnu pupọ, a jọ wa ninu ikore titi di nnkan bi agogo mẹjọ alẹ ana tii ṣe Sande ni. Ohun ti a gbọ tẹlẹ ni pe Odukoya ṣa iyawo rẹ lada, ṣugbọn ayẹwo ti a ṣe la fidi rẹ mulẹ pe ko si apa ṣiṣa, ifarapa ibi ijakadi lasan la ri," Ogido sọ bẹẹ.

"Awọn to ri ọkọ nigba to de agbegbe Iyana Coker sọ pe ẹgbẹ obinrin kan to n ta ọti lo jokoo si, to si n da sọrọ. Wọn ni lojiji to ri tirela to n bọ, lo sare lọ ko sii labẹ.

"Tirela naa lo tẹ ẹ mọlẹ, to si ku loju ẹsẹ. Ọgbẹ ọkan lo jẹ fun wa. Ọkọ ṣi wa ni mọṣuari, ṣugbọn loni naa la maa sin wọn," alagba naa sọ bẹẹ.

"Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọn yoó maa jà rèé"

Aburo Odukota, Arabinrin Abiola Fawole ninu ọrọ rẹ sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn mejeeji yoo maa ja, to si loun maa n ba wọn sọrọ lati ni suuru.

Fawole sọ pe awọn mejeeji ṣi ja ninu oṣu Kẹrin, ọdun yii, to di pe wọn n ko ara wọn lọ si agọ ọlọpaa lati yanju rẹ.

"Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn mejeeji yoo maa ja. Ninu oṣu Kẹrin, ọdun yii ni ẹgbọn mi wa ba mi, to sọ pe awọn ja, ti awọn si ko ara wọn lọ si teṣan ọlọpaa," Fawole ṣalaye.

Obinrin naa jẹ ko di mimọ pe, "mo ba wọn sọrọ lati maa ṣe suuru fun ara wọn. Oriṣiriṣi la ti gbọ lonii pe gbogbo igba ni wọn maa n ba ara wọn ja.

"Awọn ẹbi iyawo ti gbe igbesẹ lati sin eeyan wọn, awa ṣi wa lẹnu bi a ṣe fẹẹ sin ẹgbọn mi ni. Awọn ẹbi iyawo ti sọ pe awọn yoo maa ko awọn ọmọ lọ lati tọju wọn, ko si nnkan to buru nibẹ."