Ṣé lóòótọ́ ni Oriyomi Hamzat ń ṣàtìlẹ́yìn fún AMBO olùdíje APC sípò Gómìnà l'Osun? Ohun tí a mọ̀ rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Oriyomi Hamzat, ti sọ pe oun ko ṣatilẹyin fun oludije miran nipinlẹ Osun yatọ si Gomina Ademola Adeleke to n dije fun saa keji.

Oriyọmi Hamzat sọrọ yii lati yọ ara rẹ ninu awuyewuye to n lọ lori ayelujara wi pe o n ṣatilẹyin fun oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Munirudeen Bola Oyebamiji (Ambo), fun eto idibo gomina ipinlẹ Osun to n bọ.

Hamzat to jẹ gbajugbaja sọrọsọrọ fidi rẹ mulẹ pe fọnran ti wọn n gbe kaakiri nipa oun ati Ọgbẹni Oyebamiji tawọn eeyan n pe ni AMBO ti wa nita lati ọdun 2025.

Ilumọọka agbohunsafẹfẹ naa sọ loju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun wi pe kawọn eeyan kọ eti ikun si fidio ti awọn eeyan kan n gbe kiri nipa oun.

''Mo ti ṣe akiyesi fidio kan tawọn eeyan kan n gbe kiri lati ṣi awọn eeyan ipinlẹ Osun lọna.

O ṣeni laanu wi pe awọn eeyan kan lọ wu fidio to tipẹ jade, wọn si ṣe e bi ẹni wi pe nnkan to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ni.

Lasiko ti mo n ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ awọn ololufẹ Oriyomi niluu Ikire, Apomu ati Ikoyi ni awọn aṣoju Ambo wa si ibi eto naa, nibẹ si ni Ambo ti fun ẹgbẹ naa ni ẹbun owo.

Ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni eto naa waye, ati pe Oyebamiji ko tii di oludije sipo gomina fẹgbẹ APC nigba naa,'' Oriyomi ṣalaye.

Oriyomi fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan ti yi ọrọ toun sọ nibi eto naa pada.

O ni oun sọ pe ki Ambo lọ gba tikẹẹti oludije sipo gomina ẹgbẹ oṣelu APC nibi eto naa.

Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ naa sọ pe ọrọ yii toun sọ lawọn eeyan kan fẹ yi mọ oun lọwọ ti wọn fi n sọ pe oun n ṣatilẹyin fun Ambo.

Oriyomi ni awọn to n gbe fidio yii kiri mọ ọn mọ fẹ fi parọ ni tori tori oun gan an o tii darapọ mọ ẹgbẹ Accord nigba naa.

Oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo sọ pe awọn eeyan ipinlẹ Osun gbọn ju ki awọn ẹnikan maa fi fidio to tipẹ fun wọn lọ.

Ọgbẹni Hamzat wa sọ pe ''Gomina Adeleke to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu Accord ni mo n ṣatilẹyin fun, mo si gbagbọ ninu eto iṣejọba rẹ.

Ipolongo oṣelu da lori ibọwọ fun ara ẹni ati fun araalu, kii ṣe lilo fidio to ti pẹ lati ṣi awọn eeyan lọna.''

Oriyomi wa rọ awọn araalu wi pe ki wọn kọ eti ikun si fidio tawọn eeyan n gbe kaakiri naa tori irọ lo wa nibẹ.