‘Container’ míì tún ṣubú lórí afárá Ojuelegba

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ìjàmbá ọkọ̀ kan tún wáyé lálẹ́ àná lẹ́yìn tí ọkọ̀ ńlá ‘container’ kan tún ṣubú lórí bírìjì Ojuelegba ní agbègbè Surulere, ìpínlẹ̀ Eko.
Níṣe ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà dá súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ sílẹ̀ lásìkò tí àwọn ènìyàn ń wọlé lọ.
Ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ àná ni ìjàmbá ọkọ̀ náà wáyé lẹ́yìn tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti fòfin de kí àwọn ọkọ̀ ńlá máa gba orí afárá Dorman Long àti ti Ojuelegba.
Lẹ́yìn tí ọkọ̀ container kan ṣubú lórí afárá Ojuelegba tó sì ṣekúpa ènìyàn mẹ́sàn-án tó fi mọ́ àwọn ọmọdé ni ìjọba ìpínlẹ̀ fòfin de àwọn ọkọ̀ náà láti yé gba orí afárá ọ̀hún.
Níbi ìjàmbá tó wáyé lálẹ́ àná yìí, container ọ̀hún ṣubú sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà afárá náà tó sì fa súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀.
Ní àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, kò sí ẹnikẹ́ni tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Akọ̀wé àgbà Iléeṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA, Femi Oke-Osanyintolu fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn.
Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn wà níbi ìjàmbá náà láti ṣàmójútó ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.























