Oͅmoͅ Dora Akunyili di obìnrin dúdú àkóͅkóͅ tí yóò di adarí iléèwòsàn ní ilèͅ Ameͅrika

Aworan
Published

Arabinrin Ijeoma Akunyili ti fakoͅyoͅ lorileͅede Amerika leͅyin to di alawoͅdudu akoͅkoͅ lati dari ileewosan geͅgeͅ bi ‘Chief Medical Officer’ ni Ameͅrika.

Ijeoma Akunyili naa lo di adari ni ileewosan ‘Jersey City Medical Center.’

Ninu ateͅjade kan ti ileewosan naa fi lede ni woͅn ti ni idunnu ati ayoͅ lo jeͅ fun awoͅn lati jeͅ ki dokita Ijeoma jeͅ oͅkan lara awoͅn adari ni ileewosan naa.

Ninu oͅroͅ reͅ, igbakeji aareͅ ileesͅeͅ RWJBarnabas Health,Andy Anderson to ni Jersey City Medical center ni ipa ribiribi ni dokita naa yoo ko ni ipo adari nibeͅ.

Bakan naa ni aareͅ ati adari ileesͅeͅ naa, Michael Prilutsky ni lati igba to ti darapoͅ moͅ woͅn, ni atunsͅe ti ba ileesͅeͅ naa.

‘’Dokita Akunyili ni oͅgboͅn ati imoͅ nipa eto iwosan, eleyii ti yoo mu fakoͅyoͅ ati eto iwosan to peye fun gbogbo eͅni to ba wa si ileewosan naa.

Dokita Ijeoma oun ninu oͅroͅ reͅ, ni iwuri ati oriyin lo jeͅ fun oun, ti oun yoo si sa ipa oun lati ri pe ohun gbogbo loͅ leto leto bi o sͅe yeͅ ni ile iwosan naa.

Tani Ijeoma Akunyili?

Dokita  Ijeoma Akunyili ni oͅmoͅbinrin oͅjoͅgboͅn Dora Akunyili to jeͅ adari Ajoͅ Nafdac teͅleͅri to fi moͅ minisita fun eto iroyin ni Naijiria teͅleͅri.

Arabinrin naa koͅ eͅkoͅ gboye ni ileeͅkoͅ, to si fakoͅyoͅ peͅlu ami ‘distinction’ ni fasiti ilu Pennysylvania ati fasiti imoͅ eto iwosan, ‘Maryland school of medicine.’

Bakan naa lo gba eͅkoͅ imoͅ oye nipa idagbasoke ileͅ okeere (MPA) ni fasiti John F. Kennedy School of Harvard ati MBA ni ileeͅkoͅ Wharton School of Business.

Ki o to di asiko yii, o ti sͅisͅeͅ geͅgeͅ bi adari eto iwosan pajawiri fun ileewosan Waterbury Hospital.

Bakan naa lo gba ami eͅyeͅ 2019 Medical Director of the Year Award, nitori bi ileewosan naa sͅe yipada.

Bakan naa lo ti sͅisͅeͅ fun oͅpoͅloͅpoͅ oͅdun ni ileewosan ni ilu Texas, Connecticut ati beͅeͅ beͅeͅ loͅ.

Iroyin lati ileewosan Jersey City Medical center ni Dokita Ijeoma ati oͅkoͅ reͅ ti bi oͅmoͅ meji ti woͅn si ti di oͅdoͅmoͅde.

 

Tani awoͅn obi Ijeoma, Dr Chike ati Oͅjoͅgboͅn Dora Akunyili

Aworan

Oͅjoͅgboͅn Dora Akunyili to jeͅ adari Ajoͅ Nafdac teͅleͅri to fi moͅ minisita fun eto iroyin ni Naijiria teͅleͅri.

Lasiko to wa ni ipo Nafdac yii lo kopa ribiribi lati jeͅ ki opin de ba awoͅn oogun ayederu to poͅ ni Naijiria.

Oͅjoͅgboͅn Dora Akunyili lo dagbere fun aye ni ileewosan ‘Specialist Cancer Hospital’ ni orileͅede India, leͅyin aisan jeͅjeͅreͅ fun bi oͅdun meji.

Dr Chike Akunyili

Dokita Chike Akunyili ni oͅkoͅ oͅjoͅgboͅn Dora Akunyili to jeͅ adari Ajoͅ Nafdac teͅleͅri to fi moͅ minisita fun eto iroyin ni Naijiria teͅleͅri.

Oͅdun meͅrindinlogoji ni woͅn fi jeͅ oͅkoͅ ati iyawo, ki iyawo reͅ to papoda ni oͅdun 2014.

Dokita Dr Akunyili lo sͅetan peͅlu ‘First Class’ to si fi imoͅ reͅ geͅgeͅ bi dokita sͅe eto iwosan oͅfeͅ fun awoͅn eniyan kaakiri orileͅede Naijiria loͅfeͅ.

Osͅu Keͅsan, oͅdun 2021 lo ku leͅyin ti awoͅn agbeboͅn sͅe ikoͅlu sii nigba to n pada boͅ lati ilu Enugu, nibi to ti loͅ sͅe ipade kan lati sͅeranti iyawo reͅ, ni ilu Onitsha.