Wo bí ọwọ́ Amotekun ṣe tẹ àwọn afurasí àjínigbé àti àwọn mìí tó tó ogójì nípìnlẹ̀ Ondo

Published

Ileeṣẹ eleto aabo nilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ondo ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi mẹtalelogoji lori ẹsun ọdaran, papaa ijinigbe.

Ọga agba fun ajọ Amọtẹkun nipinlẹ naa, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ lo sọ eyi di mimọ lasiko to n foju awọn afurasi naa han fawọn akọroyin niluu Akurẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii.

Adelẹyẹ sọ pe kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo lọwọ ti tẹ gbogbo wọn, ati pe awọn to to idaji ninu awọn tọwọ tẹ yii lo jẹ pe wọn mọ nipa oriṣiriṣi ijinigbe to ti n ṣẹlẹ.

O ni bi awọn ṣe da ọmọ ogun sita lati dẹkun iwa ọdaran lo jẹ ki wọn rọwọ to awọn afurasi ọhun, to si ni pupọ wọn ti n jẹwọ fun wọn.

“Loni, a ni afurasi ọdaran mẹtalelogoji ti ọwọ tẹ kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo.

“Ohun to ya ni lẹnu pupọ nibi ti a ti n foju wọn han yii ni pe pupọ ninu wọn lo jẹ pe nitori ẹsun ijinigbe la fi mu wọn.

“Bii idaji ninu awọn mẹtalelogoji yii ni wọn jẹ afurasi ajinigbe, ti a si ni awọn idi pataki ti a fi gbọdọ fọrọ wa wọn lẹnu wo.

“A ni awọn afurasi to le ni aadọta, ṣugbọn ti a ni idi pataki lati fọrọ wa wọn lẹnu wo lati mọ idi ti wọn ṣe wa nibi ti a ti mu wọn, ati awọn nnkan ti a ri gba lọwọ wọn.

O ni o ṣe e ṣe ko jẹ nitori pe awọn ẹṣọ aabo rẹpẹtẹ ti wa nipinlẹ Ekiti bayii, ni wọn ṣe sa wa si ipinlẹ Ondo lati farapamọ.

“Ṣugbọn mo fẹẹ fi da yin loju pe ipinlẹ Ondo nibi kii ṣe ibi ti ọdaran kankan le farapamọ si.

Ọgbẹni Adeleye sọ pe ọwọ awọn oṣiṣẹ Amotekun tẹ awọn kan nibi ti iwa ijinigbe ti waye, lasiko ijinigbe ati asiko ti wọn n palẹmọ ijinigbe, pẹlu awọn ẹlẹri ti wọn fẹẹ jigbe, ti wọn si le tọka si wọn.”