El-Rufai, Bello Matawalle gbé Buhari lọ síléẹjọ́ torí owó tuntun, ilé ẹjọ́ gíga l'Abuja ní Buhari kò gbọdọ̀ yí gbèdéke padà

Oríṣun àwòrán, other
Pẹlu bi ọrọ ayipada owo lorilẹede Naijiria ti ṣe di eyi ti gbogbo awọn olugbe Naijiria n pariwo le lori bayii, ile ẹjọ ti gbalejo igun oselu meji lori ọrọ naa.
Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja ti fọwọ si ẹbẹ awọn igun oṣelu kan to n beere fun iwe aṣẹ lati so aarẹ lọwọ kọ pe ko gbọdọ yi ipinnu pada lori gbedeke ayipada owo tuntun lorilẹede Naijiria.
Awọn wo lo gba idajọ to so aarẹ lọwọ kọ pe ko gbọdọ yin ohun pada lori gbedeke ayipada owo?
Awọn oludije fun ipo aarẹ, ipo gomina ati aga ile aṣofin apapọ pẹlu awọn alaga ẹgbẹ oṣelu marun un kan lorilẹede Naijiria ni wọn gba ile ẹjọ giga apapọ lọ nilu Abuja nibi ti wọn ti rọ ile ẹjọ naa pe ko paṣẹ fun aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari, banki apapọ Naijiria, CBN ati gomina banki apapọ naa pe wọn ko gbọdọ fọwọ kan gbedeke ọjọ ti wọn fi lelẹ fun ayipada owo Naira lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, other
Lọjọ Aje ni ile ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ eyi to fi pa aṣẹ fun aarẹ, banki apapọ Nijiria, gomina banki apapọ Naijiria atawọn banki mẹta dinlọgbọn kan pe onyẹ kan ko gbọdọ yẹ gbedeke ọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2023.
Bakan naa ni ile ẹjọ naa paṣẹ fun awọn adari agba banki lorilẹede Naijiria pe ki wọn sọ idi ti wọn ko fi ni foju ba ile ẹjọ fun ẹsun lilodi si ofin iṣuna nipa kiko awọn owo tuntun pamọ.
Gomina ipinlẹ Mẹta labẹ ẹgbẹ oṣelu APC naa gbe Buhari lọ si ile ẹjọ lati sun gbedeke siwaju
Gomina Nasir El-Rufai ti Kaduna, Gomina Yahaya Bello ti Kogi pẹlu Gomina Bello Matawalle ti ipinlẹ Zamfara gba ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lọ lati kan an nipa fun Aarẹ Buhari ati Gomina Banki apapọ Naijiria lati dawọ duro lori gbedeke ayipada naira si tuntun.
Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ko ti da ọjọ si igbẹjọ naa.
Awọn agbẹjọro agba lawọn ipinlẹ mẹtẹẹta lo pe ẹjọ naa nigbati Abubakar Malami to jẹ agbẹjọro agba fun ijọba apapọ yoo jẹ olujẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dr.bello matawalle/alhaji yahaya bello/ governor kaduna
Awọn gomina mẹtẹtẹta naa n jiyan pe afikun ọjọ mẹwaa ti ijọba fi lelẹ ko lee tan inira ti eto ayipada owo naa n mu ba araalu.
Awọn gomina mẹtẹta n fẹ ki ijọba apapọ jawọ lori fifi gbedeke le ayipada owo naa.
Wọn ni labẹ ofin to de idasilẹ banki apapọ Naijiria, CBN Act, abala ogun ẹsẹ kẹta rẹ fihan pe Banki apapọ ko ni agbara tabi aṣẹ kankan lati fi gbedeke ọjọ si ori ayipada owo si tuntun.
Kí ló fà tí ẹgbẹ́ òṣèlú 13 fí ń dúnkokò láti má kópa nínú ètò ìdìbò?

Oríṣun àwòrán, INEC
Ẹgbẹ oṣelu mẹtala ninu ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to fẹ kopa ninu eto ìdibo lorilẹede Naijiria ti leri pe awọn ko ni kopa ninu eto ìdibo lọjọ Kẹdogun, oṣu kejì ati ọjọ kẹtala, oṣu kẹta ti banki apapọ Orilẹede Naijiria ba fikun ọjọ ti wọn yoo ko owo naira tẹlẹ nilẹ, ìyẹn ọjọ kẹwaa oṣu kejì ọdun yii.
Apapọ awọn alaga ẹgbẹ oselu naa kan sara sì Aarẹ Muhammadu Buhari lori atunṣe owo Orilẹede Naijiria, ti wọn lodi si ki mimi kankan mi asẹ naa.
Bakan naa ni awọn ẹgbẹ oselu naa bu ẹnu atẹlu bi ìjọba ìpinlẹ Kaduna,Kogi ati Zamfara ṣe wọ ìjọba apapọ lọ ileẹjọ lori afikun gbedeke ọjọ ti wọn yoo ko owo naira tẹlẹ nilẹ.
Alaga ẹgbẹ oṣelu Acton Alliance, Kenneth Udeze, ẹni to ba awọn akọroyin sọrọ ni, "A ṣe ikede pe ẹgbẹ oṣelu mẹtala ninu ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to fẹ kopa ninu eto ìdibo gbogbo gbo ninu oṣu yii ko ni kopa mọ ninu eto ìdibo ti ijọba apapọ ba yín ìpinnu wọn lori owo naira pada."
Ọsẹ to kọja ni Gomina Banki Naijiria, Godwin Emefiele kede pe ijoba ti fi kun gbendeke asiko ti won yoo ko owo atijo kuro nile.
Emefiele ṣalaye pe lẹyin ọpọlọpọ ipade pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn pinnu lati fi kun iye ọjọ ti wọn yoo ko owo naa kuro nilẹ.
Saaju ni wọn ti kede ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 gẹgẹ bi ọjọ to gbẹyin ṣugbọn bayii, wọn ti sun un siwaju di ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023.


























