Farooq Oreagba ṣàlàyé bó ṣe di olówó l'ọ́gbọ̀n ọdún

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oniṣowo nni, Farooq Oreagba ti ṣalaye bo ṣe di olowo tabua nigba to wa lẹni ọgbọn ọdun, to si n ṣe daadaa.

Yatọ si eyi Oreagba tọpọ awọn ololufẹ rẹ tun n pe ni 'Mr Steeze' tun sọ bo ṣe padanu iṣẹ to sọ ọ di olowo naa, to si dẹni to n ṣiṣẹ agbaṣe loke-okun.

Oreagba lo tu awọn aṣiri yii lasiko to n dahun ibeere lori eto ori ayelujara laipẹ yii, to si tun jẹ ko di mimọ pe oun mu ọrọ igbe aye ju owo lọ.

Gbajugbaja naa sọ pe ko ju bi ọdun marun-un lọ toun di olowo ọpọlọpọ miliọnu dọla nidi iṣẹ ile ifowopamọ, toun tun padanu iṣẹ to sọ oun di olowo tabua naa.

O ni kaka koun bẹrẹ sii ronu, niṣe loun tẹkọ leti, toun si gba ilu oyinbo lọ, nibi toun ti lọ ṣiṣẹ agbaṣe niluu England.

Ifọrọwerọ ọhun lo waye lori eto ti wọn pe ni 'MENtality Show', eyi ti awọn gbajugbaja amuludun bii Ebuka Obi Uchendu ati Banky W gbe kalẹ lori ayelujara.

Oreagba sọrọ lori ọrọ, ohun afẹ ati pataki igbe aye to kọja owo.

Nigba to n dahun ibeere nipa eyi to ṣe pataki, o ni, "Ebuka, maa beere ibeere kan. Eelo ni owo si ẹ. Ṣe biliọnu owo dọla le to ẹ?

Oreagba continued, "Maa tun beere ibeere miran nipa kiko dukia ati ohun afẹ jọ, ati awọn to n le owo. Bi mo ba fun ọ ni miliọnu mẹwaa owo dọla, ki lo maa sọ?.

"Bi mo ba sọ pe mo fun ẹ ni owo yii, ṣugbọn o ko ni ju wakati mẹrinlelogun lọ nile aye lati lo owo naa, ki lo maa ṣe?"

Nibẹ lo ti ṣalaye nipa bo ṣe di olowo, to si tun sọ bo se padanu rẹ laaarin ọdun marun-un.

"O dara, lojiji, gbigbe igbe aye bayii ni anfaani gidi. Ọgbọn ọun ni mo wa, ti mo ti di olowo miliọnu dọla, nigba ti mo pe ọdun marunlelọgbọn, mo ti bẹrẹ sii ṣiṣẹ agbaṣe niluu England.

"Mo ni afojusun temi, ati pe gbogbo rẹ ni mo padanu, to fi mọ iṣẹ mi gẹgẹ bi oṣiṣẹ banki. Lati tẹsiwaju igbe aye mi gẹgẹ bi ẹni to n tẹpa mọ iṣẹ, mo bẹrẹ sii ṣe oriṣiriṣi iṣẹ.

"Mo ṣe awọn ipinnu to lodi, lọpọ igba, a maa n gbe ohun to n jẹ wa logun lọkan ju igbe aye irọrun lọ," Oreagba sọ bẹẹ.

O wa jẹ ko di mimọ pe awọn iriri toun ti ni sẹyin, ti kọ oun pe ọpọ awọn eeyan lo n le owo, nigba ti wọn kuna lati gbajumọ ohun to ṣẹ pataki.

Bẹẹ lo kadi ọrọ rẹ nilẹ pe owo ati ọrọ nikan ko ṣapejuwe pataki igbe aye eeyan.