You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí tí Iran ṣe n sa gbogbo ipá rẹ̀ lórí òpó Strait of Hormuz
- Author, Amir Azimi
- Role, BBC Persian
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Lẹyin ọjọ mẹwaa ikojuaraẹni pẹlu ilẹ America lori ẹni ti yoo dari opo pataki to jẹ oju ọna epo, iyẹn Strait of Hormuz, o ṣee ṣe ko jẹ pe ọna mẹta lo la kalẹ fun awọn olori Iran lati gba. Amọ ko si eyi to jọ pe yoo mu aṣeyọri jade ninu wọn.
Akọkọ ni ki wọn gba pupọ ninu ohun ti Washington n fẹ : ki wọn ri i daju pe ọna oju opo Strait of Hormuz ṣee lo lai si idiwọ tabi ewu, nipa fifi opin si ikọlu ti wọn n ṣe si awọn ọkọ to n gbe epo tita kọja.
Ki wọn jawọ patapata tabi ki wọn la Uranium wọn to mu ṣinṣin, ki wọn si gba ki awọn to n ṣe ayẹwo lagbaaye wa lati yẹ ẹ wo.
Ipadabọ rẹ ni pe Tehran yoo wa ọna lati fopin si bi America ṣe di awọn ebute Iran pa, wọn yoo wa ọna irọrun fun wọn, wọn yoo si dena ikọlu to ba tun fẹ waye.
Eyi nikan lo fẹ jọ pe o dẹrun diẹ ninu awọn ọna to la kalẹ naa, amọ oun naa lo tun ṣoro ju bi a ba foju oṣelu wo o.
Ṣiṣi Hormuz lai jẹ pe Iran kọkọ ni ipa kan toun naa yoo maa ko lori oju ọna naa yoo tumọ si ohun tawọn kan ni Tehran ri bii ki wọn fi eeyan jofin, eyi to le lagbara ju ado oloro Iran lọ.
Fun igba akọkọ, ilẹ Islam naa ti fi agbara rẹ han lati mu ki gbogbo agbaye jiya ikọlu ti awọn ọta rẹ n ṣe si i.
Bakan naa si ni nnkan ogun ti Iran gbe kalẹ ni wọn ti fi han lọjọ pipẹ pe awọn ko le gbagbe rẹ.
Bi wọn ba gba lati ṣiwọ awọn nnkan naa lẹyin ọpọ oṣu ti wọn fi yari mọ America lọwọ, yoo tumọ si pe ipa America ti mu wọn niyẹn gẹgẹ bawọn alakatakiti inu wọn yoo ṣe ro o.
O tun le mu ki wọn tun maa beere awọn nnkan ija Iran si i ati ajọṣepọ rẹ pẹlu Hezbollah ni Lebanon, ẹgbẹ Shia ni Iraqi atawọn Houthis ni Yemen.
Ọna keji to wa fun wọn ni ki wọn fẹ ọrọ yii loju. Iran le fi kun ikọlu to n ṣe si awọn ibudo America to wa lọdọ wọn nipa irinajo ọkọ oju omi ati kikọlu awọn nnkan amayedẹrun pataki to wa ni ilẹ Arab to jẹ ti America.
Wọn le maa ṣe eyi pẹlu ero pe bi owo nnkan amuṣagbara ba n wọn si i, ti ikọlu si n pọ si i, yoo mu ki Washington atawọn eeyan rẹ gba ohun tawọn n fẹ.
Eyi lo si ni ewu to ga ju lẹka awọn ologun.
Ọna kẹta ni ki wọn fi i silẹ bo ṣe wa: bi nnkan ko ṣe fararọ fawọn to n gba ọna yii, amọ ko ma tun le debi ti yoo pada di ogun pẹlu America.
Eyi lo jọ pe o ba irori Iran mu. Iran ko nilo lati ṣẹgun ọta to lagbara ju u lọ to ba ti le maa wa bẹẹ lọ ti yoo fi su awọn to n ba wọn ja.
Bi wọn ṣe n le tẹsiwaju lai ba ogun naa lọ paapaa to ohun ti wọm ri bii iṣẹgun.
Amọ òté to n de wọn ati bi nnkan ṣe n bajẹ si i pẹlu ọwọngogo gbogbo nnkan nile n mu wọn lomi gidi.
Bo si ṣe n lọ yii, nnkan mi-in le ṣẹlẹ: Bi Iran ba ṣe n lo Strait of Hormuz bii paṣan ati nnkan ija, o ṣee ṣe ki wọn padanu agbara wọn bi awọn orilẹede ba ja ọgbọ́n mi-in ti wọn yoo maa fi gbe epo atawọn nnkan agbara.
Agbẹnusọ ilẹ igbimọ, Mohammad Bagher Ghalibaf, ti sọ pe ko le ri bẹẹ.
O ni Hormuz yoo wulẹ maa lagbara si i ni dipo ki ohun ti wọn n gbe kọja nibẹ dinku. Oju ọna mi-in ti ko si aabo nibẹ ko ṣee gba bo ṣe wi, to je ki gbogbo aye maa fi ti Iran ṣe.
Ta lo n ṣe awọn ipinnu naa?
Ohun kan to tun n mu ọrọ yii ṣoro ni ti ilana ipinnu ṣiṣe Iran.
Labẹ iṣakoso Ayatollah Ali Khamenei, ẹni ti wọn pa ninu ikọlu to bẹrẹ ogun America,Israeli pẹlu Iran loṣu Keji, olori wọn naa lo maa n pari ede aiyede to ba waye laarin awọn oloṣelu, awujọ ẹsin atawọn ẹṣọ.
Lẹyin ọpọ oṣu ti ogun fi n waye labẹ idari ọmọ Khamenei torukọ rẹ n jẹ Mojtaba, atunto yii ti mẹhẹ.
Aarẹ Masoud Pezeshkian atawọn isọmọgbe rẹ le torii pe ki ọrọ aje ma bajẹ, ki wọn yanju ọrọ.
Amọ awọn aṣofin atawọn alakatakiti ti ko gba ọna tiwọn le ro pe bi ọpọ eeyan ba fẹnuko le ṣe akoba fun ẹ̀sìn, ko si tun mu kawọn alatilẹyin awọn di alailẹnikan.
Ọna mẹtẹẹta to wa nilẹ fun Tehran ko ba nnkankan naa de, ọtọọtọ ni ipa ti yoo ni lori aye wọn.
Awọn to n tun ọrọ yẹ wo ninu wọn le gba ki afẹnuko waye, awọn alakatakiti le ni awọn yoo maa ba a lọ bo ṣe wa ni, bẹẹ ni awọn olori ogun kan le sọ pe ki ọrọ naa fẹju si i ni yoo fun Iran lagbara ati sọ ohun ti wọn fẹ.
Ibeere to kan bayii wa ni pe ọna wo gan-an ni Iran yoo gba, ta a ni yoo sọ eyi ti wọn yoo ṣe.
Ohun ti awọn ọmọ Iran n sọ
Ohun tawọn aṣiwaju pe ni aforiti fawọn araalu ko jọ bẹẹ loju awọn ti wọn fẹ ko ṣe aforiti naa.
Iran ati US kọwọ bọwe adehun loṣu Kẹfa lati dawọ iṣẹ ologun duro ki wọn si ṣi Strait of Hormuz, bẹẹ ni wọn tun fẹnuko pe awọn yoo da ogun duro fun ọgọta ọjọ to tẹle e.
Amọ ọsẹ kẹta lẹyin ti wọn tọwọ bọwe adehun naa, Aarẹ America; Donald Trump, kede pe awọn ko dawọ ogun duro mọ lẹyin ti Iran ṣe ikọlu si awọn ọkọ oju omi ni Hormuz, ti America naa si da a pada..
Obinrin kan nilẹ Iran sọ fun BBC Persian, pe inu oun bajẹ gidi nigba ti ija tun bẹrẹ pada.
Ero obinrin naa ni pe adehun ti igun mejeeji ṣe yoo fun wọn laye lati yanju aawọ to ku nilẹ, ti alaafia yoo si jọba.
Amọ kaka bẹẹ, o ni ẹru lo n ba oun bayii pẹlu bi wọn ṣe n ba nnkan amayedẹrun jẹ, ti wọn si tun n pa araalu atawọn ologun.
O di ẹbi ọrọ naa ru awọn alakatakiti to wa ni Iran fun bi wọn ṣe n ṣe ipinnu to n da nnkan ru, bẹẹ lo bu ẹnu atẹ lu awọn alatako nilẹ okeere, to ni awọn ni wọn n kona mọ ogun naa lati maa ran lọ.
Obinrin miran ni Tehran sọ pe ileeṣẹ ilẹ okeere toun ti n ṣiṣẹ ti wa ni titipa, oun ko niṣẹ lọwọ fun oṣu mẹrin pẹlu boun ṣe gba oye Ọmọwe to, toun si tun ni ẹkọ ati iriri iṣẹ ọdun mẹtadinlogun.
"Ko sẹni to n gba eeyan siṣẹ mọ bayii, nitori ko sẹni to mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ"
Bẹẹ ni obinrin naa wi.
O ni gbogbo nnkan lo n wọn gogo bii oju, ko sina, ko somi, ole jija n pọ si i, bẹẹ ni ija oru ko yee waye. O ni oun ti din boun ṣe n jade kiri ilu ku bayii.
Ohun toju wọn n ri yii ko tumọ si pe wọn ti gba lati fẹnuko sibi kan.
Ikọlu ilẹ okeere le mu inu bi awọn mi-in si America ati Israel, koda laarin awọn even alatako Iran.
Amọ o tun n fi han pe o ṣee ṣe ko su awọn ọmọ Iran lati maa fi ara da inira lọ.
Trump naa ni tiẹ to n koju: ki ogun fẹju si i, ki awọn ṣọja maa ja lọ ati ki ọrọ aje ma sinmi, tabi ko gba ki wọn yanju wahala yii, ki Iran maa tọju nnkan agbara rẹ labẹ amojuto to le. Amọ ko si eyi to pe e ninu mejeeji.
Ikoju ara ẹni yii le maa lọ bẹẹ fun ọpọ oṣu, ki wọn maa jọ jokoo sọrọ ki wọn si maa jẹ ki ogun sinmi fawọn asiko perete.
Ohun to ṣe koko lati beere ni pe titi digba wo ni awọn olori Iran le tọju Hormuz da lai tun pe ogun to le koko, tabi ṣiṣe ọna mi-in to ṣee gba, ti yoo mu ti strait yii dinku jọjọ.