You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Egbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀honúhàn àti Ìyanṣẹ́lódì lónìí
Lonii, ẹgbẹ oṣisẹ lorilẹede Naijiria, NLC yoo bẹrẹ ifẹhonuhan ati iyansẹlodi lati fi tako igbesẹ ijọba apapọ lori yiyọ owo iranwọ epe bẹntiro ati awọn igbesẹ miiran.
Lọjọ Ajẹ, Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ, to si kede igbesẹ ijọba lati mu aye dẹrun fun araalu.
Sugbọn ẹgbẹ osisẹ ni ọrọ Aarẹ kọ lati salaye ọna to fẹ fi mu adikun ba bi nnkan se le lasiko yii fun awọn ọmọ Naijiria.
Ni pataki aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Comrade Ajaero ni ọrọ awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria to dẹnukọlẹ ati atunṣe wọn lawọn lero pe aarẹ yoo sọ nipa rẹ.
''Ibẹrẹ gbogbo wahala yiyọ ẹkunwo taa n ri yi ko ṣẹhin aiṣẹ awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria.O ṣeni laanu pe lati oke de ilẹ ọrọ aarẹ Tinubu ko mẹnu ba atunṣe awọn ileeṣẹ ifọpo yi rara ati rara''
Ki ni nnkan ti NLC n bere fun
O to nnkan mẹfa ti ajọ ẹgbẹ n bere lọwọ ijọba apapọ orilẹede Naijiria
- Mimu adehun to wa laarin ijọba apapo ati osisẹ wa si mumu sẹ
- Dida owo iranwọ bentiro pada, ati mimu adikun ba ọwọn gogo owo epo bentiro
- Sise atunse si awọn ileeṣẹ to n se epo bentiro ni Warri, Kaduna ati Fatakwal
- Sisan owo oṣu mẹjọ fun awọn olukọ fasiti