Olubadan sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó ní ó ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Rasidi Adewolu Ladoja ti fi aidunnu rẹ lede lori lori awọn iroyin kan to n lọ ni igboro pe oun ti n ṣe oṣelu.
Ladoja tun kilọ fun awọn akọroyin to n gbe irufẹ iroyin bẹẹ kiri ki wọn jawọ ninu rẹ, bi bẹẹ kọ, wọn le foju wina ofin.
Agbẹnusọ Kabiesi, Oloye Adesola Oloko lo fi ikilọ naa lede lorukọ Olubadan lẹyin abẹwo alaga gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu APC, Nentawe Yilwatda, si aafin rẹ.
Abẹwo Yilwatda si aafin Olubadan ko ṣẹyin bo ṣe lọ si Ibadan lati lọ gba ami ẹyẹ ti fasiti kan fun nibẹ.
Amọ lẹyin abẹwo naa ni awọn iroyin kan bẹrẹ si n lọ kaakiri ni igboro pe Oludadan ti to sẹyin ẹgbẹ oṣelu APC.
Nigba to n da si ọrọ ọhun, Oloko sọ pe irọ ni iroyni naa ati pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
O ni "Ni gbogbo igba ti aaye ba ti gba Olubadan, o le gba ẹnikẹni lalejo, yala ẹni naa wa lati inu ilu Ibadan ni tabi ipinlẹ Oyo tabi bẹẹ kọ.
"Ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin, alaga gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu APC, Ọjọgbọn Nentawe Yilwatda wa siluu Ibadan. O wa gba ami ẹyẹ ni ọkan lara awọn fasiti to wa niluu Ibadan, o si woye pe o yẹ ki oun ṣabẹwo si Olubadan.
"Bo ṣe maa n ṣe ni gbogbo ibi to ba lọ niyẹn. Kabiesi si gba a laaye lati de oun lalejo pẹlu awọn igbimọ rẹ.
"O sọ fun Olubadan pe ọkan lara awọn fasiti to wa ni Ibadan lo fun oun ni ami ẹyẹ ti oun si woye pe o yẹ ki oun ṣabẹwo si Olubadan.
"Awọn akọroyin kekeke kan wa n kọ iroyin pe o ti darapọ ẹgbẹ oṣelu, wọn si bẹ rẹ si n tabuku rẹ.
"Ọpọ awọn ọdọ lo kun ori ayelujara bayii ti wọn ko kawe tabi kọ iṣẹ akọroyin, irufẹ awọn bẹẹ lo n kọ iranu ninu awọn iwe iroyin."
Oloko wa kilọ fun awọn akọroyin bẹẹ ki wọn jawọ ninu kikọ iroyin kobakungbe nipa Olubadan, bi bẹẹ kọ, wọn yoo jẹ iyan wọn niṣu.
Lẹyin naa lo gba awọn akọroyin niyanju lati dẹkun a ti maa gbe iroyin jade lai kọkọ ṣe iwadii wọn daadaa lati mọ ootọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.



























