Iléẹjọ́ ráńṣẹ́ pe Naira Marley, Sam Larry àti Primeboy lórí ikú Mohbad

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ileẹjọ to n ṣe iwadii iku to pa akọrin takasufee, Ilerioluwa Aloba tawọn eeyan mọ si Mohbad ti ranṣẹ pe Abdulazeez Fashola, ti awọn eeyan mọ si Naira Marley, Owodunni Eletu ti inagijẹ rẹ n jẹ Sam Larry, ati Owodunni Ibrahim, ọrẹ Mohbad ti wọn n pe ni Primeboy.
Ninu iwadii to n lọ lọwọ ni adajọ majisireeti to wa ni Ikorodu, , Adedayo Shotobi ti paṣẹ pe ki awọn mẹtẹẹta wa sọ ti ẹnu wọn lori iku Mohbad.
Adajọ Shotobi paṣẹ pe wọn gbọdọ foju han nile ẹjọ lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹwaa ti a wa yii.
Ohun ti ile ẹjọ n beere lọwọ awọn mẹtẹẹta ni lati sọ ohun ti wọn mọ nipa iku Mohbad ati awọn ti ba lero pe wọn le sẹkupa Mohbad.
Ile ẹjọ gbe igbesẹ yii lẹyin ti wọn ti gbọrọ lati ẹnu awọn eeyan kan lori iku ọdọmọde olorin naa.
Ile ẹjọ to n ṣewadi iku to pa Mohbad ti sọ fun ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti pe ki wọn gbe awọn mẹtẹẹta yii wa si ileẹjọ lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹwaa.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ fun ileẹjọ naa pe ayẹwọ oku Mohbad ko tii pari lati fi le mọ ohun to ṣe okunfa iku rẹ gan an.
Ileẹjọ to n ṣe iwadii yii ni iṣẹ lati ṣawari ohun to ṣekupa Mohbad eleyii ti ọpọ eeyan gbagbọ pe awọn eeyan kan lo wa nidi iṣẹlẹ ọhun.
Ileẹjọ naa ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹwaa yii.


























