Eͅgbéͅ òsͅèlú méͅrin darapòͅ moͅ APC ní ilèͅ Yoruba láti ṣàtìlẹ́yìn fún Tinubu

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Published

Sͅaaju idibo sipo aareͅ ti yoo waye ni Oͅjoͅ Satide, awoͅn eͅgbeͅ osͅelu meͅrin lo ti gba lati sͅisͅeͅ poͅ peͅlu eͅgbeͅ oselu APC.

Awoͅn eͅgbeͅ oselu naa ni Allied Peoples Movement (APM), Young Progressives Party (YPP), Peoples Redemption Party (PRP), ati Action Democratic Party (ADP).

Awoͅn eͅgbeͅ osͅelu naa to wa labeͅ asia Registered Political Parties ni awoͅn gbe igbeseͅ naa lati ri pe eͅgbeͅ oselu APC jawe olubori ninu idibo Oͅjoͅ Satide.

Alaga igbimoͅ Inter-Party Advisory Council (IPAC) ti ipinleͅͅ Eko, Mobolaji Oluwaseun lo kede reͅ.

Bakan naa ni awoͅn asͅoju eͅgbeͅ oselu naa to darapoͅ naa wa nibeͅ

Woͅn ni awoͅn gbe igbeseͅ naa nitori awoͅn gbagboͅ pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo le mu Naijiria de ileͅ ileri.

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni oͅgboͅn lati mu Naijiria teͅ siwaju – Sanwo-Olu

Ni idahun si igbese awoͅn eͅgbeͅ oselu yii, gomina ipinleͅ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti igbakeji reͅ Hamzat Obafemi n sͅoju fun ni orileͅede Naijiria nilo akinkanju eniyan bii Tinubu lati tukoͅ orileͅede Naijiria.

‘’Lati se atunse ti Naijiria nilo, a nilo eniyan to jeͅ akinkanju to si le ja fun eͅtoͅ awoͅn araalu.

Bakan naa ni a nilo awoͅn adari to see mu yangan, ti woͅn si ni akoͅsileͅ rere.

Eͅni to lee gbe igbeseͅ ti yoo si duro ti igbeseͅ reͅ lai wo eͅyin’’

Sanwo-Olu ni Asiwaju leke ninu gbogbo awoͅn to n dije du ipo, nitori naa woͅn roͅ awoͅn alatileͅyin woͅn lati dibo yan woͅn.