'Ọgbẹ ọkàn lò jẹ́ Fúnmi nígbàtí mori òkú Bàbá mí lójú ẹ̀rọ ayélujára Facebook'

Aworan Moti

Oríṣun àwòrán, FISEHAADUGNAWMINTESNOT

Published

Moti Dereje ti sọrọ lori ibanujẹ ọkan rẹ papjulọ nigba ti o ri oku Baba rẹ lori ẹrọ ayelujara Facebook ninu oṣu kọkanla ọdun 2018.

Moti akẹkọ ni fasiti to wa ni ilu Addis-Ababa olu ilu orilẹede Ethopia ni oun fẹwo ohun to n sẹlẹ lagbaye lori ẹrọ ayelujara Facebook,ṣugbon ohun ti oun ri ba inu oun jẹ gidigidi.

Nigba ti oun ba ile iṣẹ BBC sọrọ Moti ni Oku Baba oun to wa ni ilẹlẹ ni oun ri lori ẹrọ ayelujara Facebook.

Orilẹede Ethopia lo ti n koju ipenija igbesumomi fun ọpọlọpọ ọdun ti gbogbo oju opo itakun ayelujara wọn kun fun awọran awọn to padanu ẹmi wọn ninu awọn iṣẹlẹ igbesumomi ,ti ọpọlọpọ iroyin jẹ iroyin ofegee to mu rogbodiyan pọsi.

Awọn ajafẹtọ ọmọniyan Ethopia ti n pefun ofin ti yo de awọn ohun ti wọn gbe si oju opo ayelujara.

Moti ni iyalẹnu lo jẹ fun oun pe lẹyin aworan iku Baba oun ọpọlọpọ awọran ti ko ṣe wo lo pọju loju opo ẹrọ ayelujara.

Baba Moti je ọkan ninu awọn asoju ile igbimo asofin ni Ethopia to tun jẹ oṣisẹ fasiti,o wa lara awọn oloselu ti wọn fẹ pa ni agbegbe Oromia.

Agbegbe Oromia lo ti n dojukọ iṣẹlẹ isekupani papajilọ ti awọn oloṣelu,Moti ni odabi wi pe inu awọn to pa Baba oun dun si iku rẹ.

Moti ni oun ti kọwe si ile iṣẹ Facebook lati yo aworan baba oun kuro lori itakun ayelujara rẹ sugbon titi di asiko yii wọn o ti yo kuro.

ọpọlọpọ lo ti n sọrọ lori bi awọn aworan ti ko boju mu ṣe kun oju opo ayelujara,Lọdun 2021 ajọ Facebook sẹleri lati gbe iwadii lori bi awọn aworan to le mu rogbodiyan pọsi ni Ethopia ṣugbon titi di akoko yii wọn ko ṣe iwadi kankan.

Ile iṣẹ BBC bere lọwọ ile iṣẹ Meta idi ti ko fi ṣe iwadii na,ti wọn si ṣeleri lati ṣe iwadii nitori o tapa si ẹto ọmọniyan ni Ethopia.

Ile iṣẹ Meta ni awọn ti na ọpọlọpọ owo lati gbogunti lilo awọn aworan ti ko da loju opo rẹ,sugbon Rehobot Ayalew ogbon ta rigi onimo ẹrọ ni Ethopia ni ile iṣẹ Meta ko ṣe ohun to ye ni Ethopia.

Moti rọ ile iṣẹ Meta to ni Facebook lati se ohun to yẹ nipa fifayegba awọn aworan ti ko dara foju lori ẹrọ ayelujara rẹ.

O ni igbakugba ti oun ba ri awọran oku Baba oun to un tan lori ẹro ayelujara o ma n jẹ ki oun ṣi iwa wu.